Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 22:1-30

22  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé ọba Júdà, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀.  Kí o sì wí pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ ọba Júdà tí o jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì,+ ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ, àwọn tí ń gba ẹnubodè wọ̀nyí wọlé.+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo, ẹ sì dá ẹni tí a ń jà lólè nídè kúrò lọ́wọ́ oníjìbìtì; má sì ṣe àtìpó èyíkéyìí, ọmọdékùnrin aláìníbaba tàbí opó níkà.+ Má ṣe ohun àìtọ́ kankan sí wọn.+ Má sì ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ èyíkéyìí sílẹ̀ ní ibí yìí.+  Nítorí bí ẹ bá mú ọ̀rọ̀ yìí ṣe láìkùnà, dájúdájú, àwọn ọba tí ń jókòó nípò Dáfídì lórí ìtẹ́ rẹ̀ yóò gba àwọn ẹnubodè ilé yìí wọlé,+ tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin, òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.”’+  “‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mo fi ara mi búra,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘pé ilé yìí yóò di ibi ìparundahoro lásán-làsàn.’+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa ilé ọba Júdà, ‘Ìwọ dà bí Gílíádì sí mi, orí Lẹ́bánónì.+ Dájúdájú, èmi yóò sọ ọ́ di aginjù;+ ní ti àwọn ìlú ńlá, kò sí ọ̀kan tí a óò máa gbé inú rẹ̀.+  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ àwọn tí ń mú ìparun wá di mímọ́ lòdì sí ọ,+ olúkúlùkù àti àwọn ohun ìjà rẹ̀;+ wọn yóò sì gé ààyò jù lọ nínú kédárì rẹ lulẹ̀,+ wọn yóò sì mú kí wọ́n ṣubú sínú iná.+  Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò sì kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú ńlá yìí, ẹnì kìíní yóò sì wí fún ẹnì kejì pé: “Ní tìtorí kí ni Jèhófà fi ṣe báyìí sí ìlú ńlá títóbi yìí?”+  Dájúdájú, wọn yóò wí pé: “Ní tìtorí òtítọ́ náà pé wọ́n ti fi májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún àwọn ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì ń sìn wọ́n.”’+ 10  “Ẹ má sunkún fún ẹni tí ó ti kú,+ ẹ má sì ṣe bá a kẹ́dùn. Ẹ sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ fún ẹni tí ń lọ, nítorí kì yóò padà mọ́, kì yóò sì rí ilẹ̀ àwọn ìbátan rẹ̀ mọ́ ní tòótọ́. 11  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa Ṣálúmù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà tí ń jọba nípò Jòsáyà baba rẹ̀,+ ẹni tí ó jáde lọ kúrò ní ibí yìí, ‘òun kì yóò padà sí ibẹ̀ mọ́. 12  Nítorí ibi tí wọ́n mú un lọ ní ìgbèkùn ni yóò kú sí, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.’+ 13  “Ègbé ni fún ẹni tí ń kọ́ ilé rẹ̀,+ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe pẹ̀lú òdodo, àti àwọn ìyẹ̀wù òkè rẹ̀, ṣùgbọ́n tí kí í ṣe pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo, nípa ìlò ọmọnìkejì rẹ̀ tí ń sìn lásán, tí kò sì fún un ní owó ọ̀yà rẹ̀;+ 14  ẹni tí ń wí pé, ‘Èmi yóò kọ́ ilé aláyè gbígbòòrò àti àwọn ìyẹ̀wù òkè aláyè gbàràmùgbaramu fún ara mi;+ fèrèsé mi ni a ó sì mú gbòòrò sí i nítorí rẹ̀, ọ̀ṣọ́ igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ yóò sì jẹ́ kédárì+ tí a fi àwọ̀ pupa fòò kùn.’+ 15  Ìwọ yóò ha máa jọba nìṣó nítorí pé o ń díje nípasẹ̀ ìlò kédárì? Ní ti baba rẹ, òun kò ha jẹ, kò ha mu, kò ha sì mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo ṣẹ ní kíkún?+ Nítorí ìyẹn, nǹkan lọ dáadáa fún un.+ 16  Ó gba ìbéèrè ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin ti àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn òtòṣì rò.+ Nítorí ìyẹn, nǹkan lọ dáadáa. ‘Ìyẹn kì í ha ṣe ọ̀ràn mímọ̀ mí bí?’ ni àsọjáde Jèhófà. 17  ‘Dájúdájú, ojú rẹ àti ọkàn-àyà rẹ kò sí lórí nǹkan mìíràn bí kò ṣe lórí èrè rẹ aláìbá ìdájọ́ òdodo mu,+ lórí ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ láti ta á sílẹ̀,+ àti lórí lílu jìbìtì àti lórí ìlọ́nilọ́wọ́gbà láti máa bá a lọ ní ṣíṣe wọ́n.’ 18  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, ‘Wọn kì yóò pohùn réré ẹkún fún un pé: “Págà, arákùnrin mi! Págà, arábìnrin mi!” Wọn kì yóò pohùn réré ẹkún fún un pé: “Págà, ọ̀gá! Àti págà, iyì rẹ̀!”+ 19  Bí a ṣe ń sin akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a ó sin ín,+ pẹ̀lú ìwọ́káàkiri àti ìgbésọnù, ré kọjá àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.’+ 20  “Gòkè lọ sí Lẹ́bánónì+ kí o sì ké jáde, kí o sì gbé ohùn rẹ sókè ní Báṣánì.+ Sì ké jáde láti Ábárímù,+ nítorí pé a ti ṣẹ́ gbogbo àwọn tí ń fi ìgbónájanjan nífẹ̀ẹ́ rẹ.+ 21  Mo bá ọ sọ̀rọ̀ lákòókò òmìnira rẹ kúrò lọ́wọ́ àníyàn.+ O wí pé, ‘Èmi kì yóò ṣègbọràn.’+ Èyí ti jẹ́ ọ̀nà rẹ láti ìgbà èwe rẹ, nítorí ìwọ kò ṣègbọràn sí ohùn mi.+ 22  Ẹ̀fúùfù yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn gbogbo olùṣọ́ àgùntàn rẹ;+ àti ní ti àwọn tí ń fi ìgbónájanjan nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọn yóò lọ sí oko òǹdè.+ Nítorí ní àkókò yẹn, ojú yóò tì ọ́, dájúdajú, a ó sì tẹ́ ọ lógo nítorí gbogbo ìyọnu àjálù rẹ.+ 23  Ẹ̀yin tí ń gbé Lẹ́bánónì,+ tí ẹ tẹ́ ìtẹ́ sínú kédárì,+ ẹ wo bí ẹ ó ti mí ìmí ẹ̀dùn dájúdájú nígbà tí ìroragógó ìbímọ bá dé bá yín,+ ìrora ìrọbí bí ti obìnrin tí ó fẹ́ bímọ!”+ 24  “‘Bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní bí Konáyà+ ọmọkùnrin Jèhóákímù,+ ọba Júdà, bá jẹ́ òrùka èdìdì+ ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ibẹ̀ ni èmi yóò ti yọ ọ́ kúrò!+ 25  Dájúdájú, èmi yóò sì fi ọ́ lé àwọn tí ń wá ọkàn rẹ+ àti lé àwọn tí o ń fòyà wọn àti lé Nebukadirésárì ọba Bábílónì àti lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́.+ 26  Èmi yóò sì fi ìwọ àti ìyá rẹ+ tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn tí a kò bí yín sí, ibẹ̀ sì ni ẹ óò kú sí.+ 27  Ilẹ̀ tí wọn yóò sì máa gbé ọkàn wọn sókè láti padà sí, wọn kì yóò padà sí ibẹ̀.+ 28  Ọkùnrin yìí, Konáyà,+ ha jẹ́ ohun kan lásán tí a tẹ́ńbẹ́lú, tí a fọ́ túútúú,+ tàbí ohun èlò kan tí a kò ní inú dídùn kankan sí?+ Èé ṣe tí a ó fi fi òun fúnra rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀, tí a ó sì sọ wọ́n sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀?’+ 29  “Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ 30  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ẹ kọ ọ́ sílẹ̀ pé ọkùnrin yìí jẹ́ aláìbímọ,+ bí abarapá ọkùnrin tí kì yóò ní àṣeyọrí sí rere kankan ní ọjọ́ ayé rẹ̀; nítorí nínú àwọn ọmọ rẹ̀, ọ̀kankan kì yóò ní àṣeyọrí sí rere kankan,+ ní jíjókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti ní ṣíṣàkóso ní Júdà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé