Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 21:1-14

21  Ọ̀rọ̀+ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, nígbà tí Sedekáyà+ Ọba rán Páṣúrì+ ọmọkùnrin Málíkíjà àti Sefanáyà+ ọmọkùnrin Maaseáyà, àlùfáà sí i, pé:  “Jọ̀wọ́ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà+ nítorí wa, nítorí pé Nebukadirésárì ọba Bábílónì ń bá wa jagun.+ Bóyá Jèhófà yóò ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀, kí ó lè fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wa.”+  Jeremáyà sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí ẹ ó sọ fún Sedekáyà,  ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Kíyè sí i, èmi yóò yí ohun ìjà ogun tí ó wà ní ọwọ́ yín padà, èyí tí ẹ fi ń bá ọba Bábílónì jà,+ àti àwọn ará Kálídíà+ tí wọ́n ń sàga tì yín lẹ́yìn ògiri, ṣe ni èmi yóò kó wọn jọpọ̀ sí àárín ìlú ńlá yìí.+  Dájúdájú, èmi fúnra mi yóò sì bá yín jà+ pẹ̀lú ọwọ́ nínà jáde àti pẹ̀lú apá lílágbára àti pẹ̀lú ìbínú àti pẹ̀lú ìhónú àti pẹ̀lú ìkannú ńláǹlà.+  Dájúdájú, èmi yóò kọlu àwọn olùgbé ìlú ńlá yìí, àti ènìyàn àti ẹranko. Nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ńláǹlà ni wọn yóò kú.”’+  “‘“Àti lẹ́yìn ìyẹn,” ni àsọjáde Jèhófà, “èmi yóò fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn náà àti àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ àjàkálẹ̀ àrùn, láti ọwọ́ idà àti láti ọwọ́ ìyàn, lé Nebukadirésárì ọba Bábílónì lọ́wọ́, àní lé àwọn ọ̀tá wọn àti lé àwọn tí ń wá ọkàn wọn lọ́wọ́, dájúdájú, òun yóò fi ojú idà kọlù wọ́n.+ Kì yóò káàánú wọn, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìyọ́nú hàn tàbí kí ó ṣàánú.”’+  “Kí o sì sọ fún àwọn ènìyàn yìí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, mo ń fi ọ̀nà ìyè àti ọ̀nà ikú síwájú yín.+  Ẹni tí ó jókòó jẹ́ẹ́ sínú ìlú ńlá yìí yóò tipa idà àti ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn kú;+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jáde kúrò tí ó sì ṣubú ní tòótọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n ń sàga tì yín ni yóò máa wà láàyè nìṣó, dájúdájú, ọkàn rẹ̀ yóò sì jẹ́ tirẹ̀ bí ohun ìfiṣèjẹ.”’+ 10  “‘“Nítorí mo ti dojú mi kọ ìlú ńlá yìí fún ìyọnu àjálù, kì í sì í ṣe fún rere,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Èmi yóò fi í lé ọba Bábílónì lọ́wọ́,+ dájúdájú, òun yóò sì fi iná sun ún.”+ 11  “‘Àti ní ti agbo ilé ọba Júdà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ 12  Ilé Dáfídì,+ èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ní òròòwúrọ̀,+ máa fi ìdájọ́ òdodo dájọ́,+ sì dá ẹni tí a ń jà lólè nídè kúrò lọ́wọ́ oníjìbìtì,+ kí ìhónú mi má bàa jáde lọ gẹ́gẹ́ bí iná,+ kí ó sì jó ní ti gidi, tí kò ní sí ẹni tí yóò pa á nítorí ìwà búburú ìbálò yín.”’+ 13  “‘Kíyè sí i, mo dojú kọ ọ́, ìwọ obìnrin olùgbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀, ìwọ àpáta ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ,’+ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Ní ti ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé: “Ta ni yóò sọ̀ kalẹ̀ láti gbéjà kò wá? Ta ni yóò sì wá sínú ibùgbé wa?”+ 14  Dájúdájú, èmi yóò béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ yín+ pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí èso ìbálò yín,’+ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Èmi yóò sì ti iná bọ inú igbó rẹ̀,+ yóò sì jẹ gbogbo ohun tí ó yí i ká run.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé