Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 20:1-18

20  Wàyí o, Páṣúrì, ọmọkùnrin Ímérì,+ àlùfáà, tí ó tún jẹ́ kọmíṣọ́nnà tí ó ń mú ipò iwájú nínú ilé Jèhófà,+ ń fetí sí Jeremáyà nígbà tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí.  Nígbà náà ni Páṣúrì lu Jeremáyà wòlíì,+ ó sì fi í sínú àbà+ tí ó wà ní Ẹnubodè Òkè ti Bẹ́ńjámínì, èyí tí ó wà ní ilé Jèhófà.  Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e pé Páṣúrì ń bá a lọ láti tú Jeremáyà sílẹ̀ kúrò nínú àbà,+ Jeremáyà sì wá wí fún un pé: “Jèhófà kò pe orúkọ+ rẹ ní Páṣúrì, bí kò ṣe Jìnnìjìnnì ní gbogbo àyíká.+  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò sọ ọ́ di jìnnìjìnnì sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ, dájúdájú, wọn yóò sì tipa idà àwọn ọ̀tá wọn ṣubú+ ní ìṣojú rẹ;+ gbogbo Júdà ni èmi yóò sì fi lé ọba Bábílónì lọ́wọ́, ní ti gidi, òun yóò sì kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì, yóò sì fi idà ṣá wọn balẹ̀.+  Dájúdájú, èmi yóò sì fi gbogbo nǹkan tí ìlú ńlá yìí tò jọ pa mọ́ àti gbogbo àmújáde rẹ̀ àti gbogbo ohun ṣíṣeyebíye rẹ̀ fúnni; àti gbogbo ìṣúra àwọn ọba Júdà ni èmi yóò sì fi lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.+ Dájúdájú, wọn yóò sì piyẹ́ wọn, wọn yóò sì kó wọn, wọn yóò sì mú wọn wá sí Bábílónì.+  Ní tìrẹ, ìwọ Páṣúrì, àti gbogbo àwọn olùgbé ilé rẹ, ẹ ó lọ sí oko òǹdè;+ ìwọ yóò sì wá sí Bábílónì, ibẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, ibẹ̀ sì ni a ó sin ìwọ tìkára rẹ sí pẹ̀lú gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ,+ nítorí o ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún wọn.’”+  O ti tàn mí, Jèhófà, tí mo fi di ẹni tí a tàn. O lo okun rẹ lórí mi, o sì borí.+ Mo di ohun ìfirẹ́rìn-ín láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀; olúkúlùkù ènìyàn ń fi mí ṣẹ̀sín.+  Nítorí nígbàkúùgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ṣe ni mo ń ké jáde. Ìwà ipá àti ìfiṣèjẹ ni mo ń ké jáde.+ Nítorí pé fún mi, ọ̀rọ̀ Jèhófà di okùnfa ẹ̀gàn àti ìfiṣeyẹ̀yẹ́ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+  Mo sì wí pé: “Èmi kì yóò mẹ́nu kàn án, èmi kì yóò sì sọ̀rọ̀ mọ́ ní orúkọ rẹ̀.”+ Nínú ọkàn-àyà mi, ó sì wá dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun mi; pípa á mọ́ra sú mi, èmi kò sì lè fara dà á.+ 10  Nítorí mo gbọ́ ìròyìn búburú ọ̀pọ̀lọpọ̀.+ Jìnnìjìnnì wà ní gbogbo àyíká. “Ẹ sọ ọ́ jáde, kí a lè sọ nípa rẹ̀.”+ Olúkúlùkù ẹni kíkú tí ń sọ fún mi pé “Àlàáfíà!”—wọ́n ń wọ̀nà fún ìtagẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́ mi:+ “Bóyá yóò di ẹni tí a tàn,+ kí a bàa lè borí rẹ̀, kí a sì lè gbẹ̀san lára rẹ̀.” 11  Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú mi+ bí alágbára ńlá tí ń jáni láyà.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi yóò fi kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí.+ Dájúdájú, ìtìjú púpọ̀ yóò bá wọn, nítorí pé wọn kì yóò láásìkí. Ìtẹ́lógo wọn tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin yóò jẹ́ ọ̀kan tí a kì yóò gbàgbé.+ 12  Ṣùgbọ́n ìwọ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ń wádìí olódodo wò;+ o ń rí kíndìnrín àti ọkàn-àyà.+ Jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lára wọn,+ nítorí ìwọ ni mo ṣí ẹjọ́ mi lábẹ́ òfin payá fún.+ 13  Ẹ kọrin sí Jèhófà! Ẹ yin Jèhófà! Nítorí ó ti dá ọkàn àwọn òtòṣì nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn aṣebi.+ 14  Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má di èyí tí a bù kún!+ 15  Ègún ni fún ọkùnrin tí ó mú ìhìn rere wá fún baba mi, pé: “A ti bí ọmọkùnrin kan fún ọ, akọ!” Dájúdájú, òun mú un láyọ̀.+ 16  Kí ọkùnrin yẹn gan-an dà bí àwọn ìlú ńlá tí Jèhófà bì ṣubú láìjẹ́ pé Òun kẹ́dùn.+ Òun yóò sì gbọ́ igbe ẹkún ní òwúrọ̀ àti àmì àfiyèsí oníròó ìdágìrì ní àkókò ọjọ́kanrí.+ 17  Èé ṣe tí kò kúkú fi ikú pa mí ní ilé ọlẹ̀, kí ìyá mi di ibi ìsìnkú fún mi, kí ilé ọlẹ̀ rẹ̀ sì lóyún fún àkókò tí ó lọ kánrin?+ 18  Èé ti ṣe tí mo fi jáde wá láti inú ilé ọlẹ̀ náà+ láti rí iṣẹ́ àṣekára àti ẹ̀dùn-ọkàn,+ kí àwọn ọjọ́ mi sì wá sí òpin wọn nínú ìtìjú lásán-làsàn?+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé