Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 2:1-37

2  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá,+ pé:  “Lọ, kí o sì ké jáde ní etí Jerúsálẹ́mù, pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí:+ “Mo rántí dáadáa, níhà ọ̀dọ̀ rẹ, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ìgbà èwe rẹ,+ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí a ń fẹ́ ọ sọ́nà láti gbé ọ níyàwó,+ bí o ti ń tọ̀ mí lẹ́yìn ní aginjù, ní ilẹ̀ tí a kò fún irúgbìn sí.+  Ohun mímọ́ ni Ísírẹ́lì jẹ́ lójú Jèhófà,+ èso àkọ́so fún Un.”’+ ‘Àwọn tí ó bá jẹ ẹ́ run yóò sọ ara wọn di ẹlẹ́bi.+ Àní ìyọnu àjálù yóò já lù wọ́n,’ ni àsọjáde Jèhófà.”+  Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ ilé Jékọ́bù,+ àti gbogbo ẹ̀yin ìdílé ti ilé Ísírẹ́lì.+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kí ni àwọn baba yín rí nínú mi tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu,+ tí wọ́n fi jìnnà réré sí mi,+ tí wọ́n sì ń tọ òrìṣà asán lẹ́yìn,+ tí àwọn fúnra wọn sì di asán?+  Wọn kò sì sọ pé, ‘Jèhófà dà, Ẹni tí ó mú wa gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ Ẹni tí ó mú wa rìn la aginjù kọjá, la ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀+ àti kòtò kọjá, la ilẹ̀ aláìlómi+ àti ibú òjìji kọjá,+ la ilẹ̀ tí ènìyàn kankan kò gbà kọjá, tí ará ayé kankan kò sì gbé?’  “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọgbà igi eléso, láti máa jẹ èso rẹ̀ àti àwọn ohun rere rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n ẹ wọlé wá, ẹ sì sọ ilẹ̀ mi di ẹlẹ́gbin; ẹ sì sọ ogún tèmi di ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.+  Àwọn àlùfáà pàápàá kò sọ pé, ‘Jèhófà dà?’+ Àwọn ẹni náà tí ń mú òfin lò kò sì mọ̀ mí;+ àwọn olùṣọ́ àgùntàn pàápàá sì ré ìlànà mi kọjá,+ àní àwọn wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ Báálì,+ àwọn tí kò sì lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan ni wọ́n tọ̀ lẹ́yìn.+  “‘Nítorí náà, èmi yóò bá yín fà á síwájú sí i,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘èmi yóò sì bá àwọn ọmọ ọmọ yín fà á.’+ 10  “‘Ṣùgbọ́n ẹ kọjá lọ sí ilẹ̀ etí òkun àwọn ará Kítímù+ kí ẹ sì wò ó. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ránṣẹ́ lọ sí Kídárì pàápàá,+ kí ẹ sì fún un ní àkànṣe àfiyèsí, kí ẹ sì rí i bóyá ohunkóhun bí èyí ti ṣẹlẹ̀ rí.+ 11  Orílẹ̀-èdè kan ha ti ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ọlọ́run,+ àní fún àwọn tí kì í ṣe ọlọ́run bí?+ Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tèmi ti ṣe pàṣípààrọ̀ ògo mi fún ohun tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan.+ 12  Ẹ wo èyí sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì, ẹ̀yin ọ̀run; ẹ sì dìde gàn-ùn gàn-ùn bí irun ti ń dìde nínú ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ńláǹlà,’ ni àsọjáde Jèhófà,+ 13  ‘nítorí ohun búburú méjì ni àwọn ènìyàn mi ṣe: Wọ́n ti fi èmi pàápàá,+ orísun omi ààyè sílẹ̀,+ láti gbẹ́ àwọn ìkùdu fún ara wọn, àwọn ìkùdu fífọ́, tí kò lè gba omi dúró.’ 14  “‘Ìránṣẹ́ ha ni Ísírẹ́lì,+ tàbí ẹrú tí a bí nínú agbo ilé? Èé ṣe tí ó fi wá jẹ́ ohun tí a piyẹ́? 15  Àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ké ramúramù mọ́ ọn;+ wọ́n ti na ohùn wọn jáde.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ohun ìyàlẹ́nu. A ti sọ iná sí àwọn ìlú ńlá rẹ̀, tí kò fi ní àwọn olùgbé kankan.+ 16  Àní àwọn ọmọ Nófì+ àti àwọn Tápánésì+ pàápàá ń fi ọ ṣe oúnjẹ jẹ ní àtàrí rẹ.+ 17  Èyí ha kọ́ ni ohun tí o bẹ̀rẹ̀ sí ṣe sí ara rẹ nípa fífi Jèhófà Ọlọ́run rẹ sílẹ̀+ ní àkókò tí ó ń mú ọ rìn lójú ọ̀nà?+ 18  Wàyí o, ìdàníyàn wo ni ó yẹ kí o ní fún ọ̀nà Íjíbítì,+ láti mu omi Ṣíhórì?+ Ìdàníyàn wo sì ni ó yẹ kí o ní fún ọ̀nà Ásíríà,+ láti mu omi Odò? 19  Ó yẹ kí ìwà búburú rẹ tọ́ ọ sọ́nà,+ kí ìwà àìṣòótọ́ rẹ sì fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà.+ Mọ̀, nígbà náà, kí o sì rí i pé fífi tí o fi Jèhófà Ọlọ́run rẹ sílẹ̀ jẹ́ ohun búburú tí ó sì korò,+ ìwọ kò sì ní ìbẹ̀rùbojo fún mi,’+ ni àsọjáde Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 20  “‘Nítorí pé ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni mo ti ṣẹ́ àjàgà rẹ sí wẹ́wẹ́;+ mo fa ọ̀já rẹ já. Ṣùgbọ́n, ìwọ wí pé: “Èmi kì yóò sìn,” nítorí pé orí gbogbo òkè kékeré gíga àti abẹ́ olúkúlùkù igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+ ni ìwọ dùbúlẹ̀ gbalaja sí,+ tí o ń fi ara rẹ ṣe iṣẹ́ kárùwà.+ 21  Ní tèmi, mo ti gbìn ọ́ bí ààyò àjàrà pupa,+ gbogbo rẹ̀ irúgbìn tòótọ́. Báwo ni a ṣe yí ọ padà di ọ̀mùnú àjàrà ilẹ̀ òkèèrè tí ó jẹrà bàjẹ́ sí mi?’+ 22  “‘Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá tilẹ̀ fi ákáláì wẹ̀, tí o sì mú ìwọ̀n ọṣẹ ìfọṣọ púpọ̀ fún ara rẹ,+ dájúdájú, ìṣìnà rẹ yóò jẹ́ àbààwọ́n níwájú mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 23  Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Èmi kò sọ ara mi di ẹlẹ́gbin.+ Èmi kò tọ Báálì lẹ́yìn’?+ Wo ọ̀nà rẹ ní àfonífojì.+ Fiyè sí ohun tí o ti ṣe. Ẹgbọrọ abo ràkúnmí yíyára tí ń sálọ-sábọ̀ jàbàjàbà ní ọ̀nà rẹ̀; 24  kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà+ tí aginjù ti mọ́ lára, nínú ìfàsí ọkàn rẹ̀, tí ń fa ẹ̀fúùfù símú;+ nígbà tí ó bá tó àkókò fún un láti gùn, ta ni ó lè dá a padà? Gbogbo àwọn tí ń wá a kì yóò kó àárẹ̀ bá ara wọn. Wọn yóò wá a rí ní oṣù rẹ̀. 25  Fa ẹsẹ̀ rẹ sẹ́yìn kúrò nínú àìwọ bàtà, àti ọ̀fun rẹ kúrò nínú òùngbẹ.+ Ṣùgbọ́n o bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Ìrètí kò sí!+ Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n mo ti kó sínú ìfẹ́ pẹ̀lú àwọn àjèjì,+ àwọn ni èmi yóò sì máa tọ̀ lẹ́yìn.’+ 26  “Bí ojú ṣe máa ń ti olè nígbà tí a bá mú un, bẹ́ẹ̀ ni ojú ti àwọn ti ilé Ísírẹ́lì,+ àwọn, àwọn ọba wọn, àwọn ọmọ aládé wọn àti àwọn àlùfáà wọn àti àwọn wòlíì wọn.+ 27  Wọ́n ń sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’+ àti fún òkúta pé, ‘Ìwọ fúnra rẹ ni o bí mi.’ Ṣùgbọ́n wọ́n yí ẹ̀yìn ọrùn sí mi, kì í sì í ṣe ojú wọn.+ Ní àkókò ìyọnu àjálù wọn, wọn yóò sì wí pé, ‘Dìde, kí o sì gbà wá là!’+ 28  “Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́run rẹ tí o ti ṣe fún ara rẹ dà?+ Kí wọ́n dìde bí wọ́n bá lè gbà ọ́ là ní àkókò ìyọnu àjálù rẹ.+ Nítorí pé bí iye ìlú ńlá rẹ ti pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ọlọ́run rẹ ti pọ̀ tó, ìwọ Júdà.+ 29  “‘Èé ṣe tí ẹ fi ń bá mi fà á?+ Èé ṣe tí ẹ̀yin, àní gbogbo yín, fi ré ìlànà mi kọjá?’+ ni àsọjáde Jèhófà. 30  Lásán ni mo kọlu àwọn ọmọ yín.+ Wọn kò tẹ́wọ́ gba ìbáwí rárá.+ Idà yín ti jẹ àwọn wòlíì yín run, bí kìnnìún tí ń fa ìparun.+ 31  Ìran yìí, ẹ fúnra yín wo ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ “Mo ha ti di aginjù lásán lójú Ísírẹ́lì+ tàbí ilẹ̀ òkùnkùn biribiri? Èé ṣe tí àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ènìyàn mi fi wí pé, ‘A ti rìn kiri. A kì yóò wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́’?+ 32  Wúńdíá ha lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ bí, kí ìyàwó sì gbàgbé ọ̀já ìgbàyà rẹ̀? Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi—wọ́n ti gbàgbé mi fún àwọn ọjọ́ tí kò níye.+ 33  “Èé ṣe tí ìwọ, obìnrin, fi mú ọ̀nà rẹ sunwọ̀n sí i láti wá ìfẹ́? Nítorí náà, ẹ̀kọ́ àwọn ohun búburú ni o tún fi kọ́ àwọn ọ̀nà rẹ.+ 34  Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ti rí àmì ẹ̀jẹ̀ ọkàn+ àwọn òtòṣì aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nínú ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ.+ Kì í ṣe lẹ́nu fífọ́lé ni mo ti rí i, bí kò ṣe lára gbogbo ìwọ̀nyí.+ 35  “Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Mo ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. Dájúdájú, ìbínú rẹ̀ ti yí padà kúrò lórí mi.’+ “Kíyè sí i, èmi yóò wọnú ìjà pẹ̀lú rẹ ní tìtorí ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’+ 36  Èé ṣe tí o fi ka yíyí ọ̀nà rẹ padà sí aláìjámọ́ nǹkan kan rárá?+ Ojú yóò tì ọ́ nítorí Íjíbítì pẹ̀lú,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ojú ti tì ọ́ nítorí Ásíríà.+ 37  Fún ìdí yìí pẹ̀lú, ìwọ yóò káwọ́ lérí jáde lọ,+ nítorí pé Jèhófà ti kọ àwọn ohun àgbọ́kànlé rẹ, ìwọ kì yóò sì ní àṣeyọrí sí rere kankan pẹ̀lú wọn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé