Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 19:1-15

19  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Lọ, kí o sì wá ṣágo amọ̀ ti amọ̀kòkò,+ kí o sì wá lára àwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà àti lára àwọn àgbà ọkùnrin àlùfáà.  Kí o sì jáde lọ sí àfonífojì ọmọ Hínómù,+ èyí tí ó wà ní ibi àtiwọ Ẹnubodè Èéfọ́ Ìkòkò. Ibẹ̀ sì ni kí o ti pòkìkí àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi yóò sọ fún ọ.+  Kí o sì wí pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin ọba Júdà àti ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù.+ Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “‘“Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù kan wá sórí ibí yìí, èyí tí ó jẹ́ pé nígbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́, etí rẹ̀ yóò hó yee;+  nítorí ìdí náà pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ti tẹ̀ síwájú láti sọ ibí yìí di aláìṣeédámọ̀,+ wọ́n sì ti rú èéfín ẹbọ nínú rẹ̀ sí àwọn ọlọ́run mìíràn tí wọn kò mọ̀,+ àwọn àti àwọn baba ńlá wọn àti àwọn ọba Júdà; wọ́n sì ti fi ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ kún ibí yìí.+  Wọ́n sì kọ́ àwọn ibi gíga Báálì láti sun àwọn ọmọ wọn nínú iná bí odindi ọrẹ ẹbọ sísun sí Báálì,+ ohun kan tí èmi kò pa láṣẹ tàbí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀,+ tí kò sì wá sínú ọkàn-àyà mi.”’+  “‘“Nítorí náà, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “nígbà tí a kì yóò pe ibí yìí ní Tófétì+ mọ́ àti àfonífojì ọmọ Hínómù,+ bí kò ṣe àfonífojì ìpànìyàn.  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ ìmọ̀ràn Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù di aláìjámọ́ nǹkan kan ní ibí yìí,+ èmi yóò sì mú kí wọ́n tipa idà ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá wọn àti láti ọwọ́ àwọn tí ń wá ọkàn wọn.+ Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko orí ilẹ̀.+  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ ìlú ńlá yìí di ohun ìyàlẹ́nu àti ohun ìsúfèé sí.+ Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gbẹ̀yìn yóò wò sùn-ùn tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu, yóò sì súfèé nítorí gbogbo ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.+  Dájúdájú, èmi yóò sì mú wọn jẹ ẹran ara àwọn ọmọkùnrin wọn àti ẹran ara àwọn ọmọbìnrin wọn; olúkúlùkù wọn yóò sì jẹ ẹran ara ọmọnìkejì rẹ̀, nítorí lílepinpin àti nítorí másùnmáwo tí àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tí ń wá ọkàn wọn yóò fi há wọn mọ́.”’+ 10  “Kí o sì fọ́ ṣágo náà lójú àwọn ọkùnrin tí ìwọ àti àwọn jọ ń lọ. 11  Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Bákan náà ni èmi yóò fọ́ àwọn ènìyàn yìí àti ìlú ńlá yìí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò tí kò fi lè ṣeé tún ṣe mọ́;+ wọn yóò sì sìnkú ní Tófétì+ títí kò fi ní sí àyè mọ́ láti sìnkú.”’+ 12  “‘Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe sí ibí yìí,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àti sí àwọn olùgbé rẹ̀, àní láti ṣe ìlú ńlá yìí bí Tófétì.+ 13  Àwọn ilé Jerúsálẹ́mù àti ilé àwọn ọba Júdà yóò sì dà bí ibi Tófétì,+ àwọn aláìmọ́, èyíinì ni, gbogbo ilé tí wọ́n ń rú èéfín ẹbọ ní òrùlé rẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run,+ tí wọ́n sì ti ń da ọrẹ ẹbọ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run mìíràn.’”+ 14  Jeremáyà sì dé láti Tófétì,+ ibi tí Jèhófà ti rán an lọ láti sọ tẹ́lẹ̀, ó sì dúró ní àgbàlá ilé Jèhófà, ó sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé:+ 15  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú gbogbo ìyọnu àjálù tí mo sọ lòdì sí ìlú ńlá yìí wá sórí rẹ̀ àti sórí gbogbo ìlú ńlá rẹ̀, nítorí wọ́n ti mú ọrùn wọn le láti ṣàìgbọràn sí ọ̀rọ̀ mi.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé