Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 18:1-23

18  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé:  “Dìde, kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò,+ ibẹ̀ sì ni èmi yóò ti mú kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.”  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀, ó sì ń ṣe iṣẹ́ lórí àgbá kẹ̀kẹ́ amọ̀kòkò.  Ọwọ́ amọ̀kòkò sì ba ohun èlò tí ó ń fi amọ̀ ṣe jẹ́, ó sì yí padà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe ohun èlò mìíràn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ̀nà ní ojú amọ̀kòkò láti ṣe.+  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá pé:  “‘Èmi kò ha lè ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí sí yín, ilé Ísírẹ́lì?’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Wò ó! Bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí ni ọwọ́ mi, ilé Ísírẹ́lì.+  Ní ìṣẹ́jú èyíkéyìí tí mo bá sọ̀rọ̀ lòdì sí orílẹ̀-èdè kan àti lòdì sí ìjọba kan láti fà a tu àti láti bì í wó àti láti pa á run,+  tí orílẹ̀-èdè yẹn bá sì yí padà ní ti gidi kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀ èyí tí mo sọ̀rọ̀ lòdì sí,+ èmi pẹ̀lú yóò pèrò dà dájúdájú ní ti ìyọnu àjálù tí mo ti rò láti mú ṣẹ ní kíkún sórí rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú èyíkéyìí tí mo bá sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè kan àti nípa ìjọba kan láti gbé e ró àti láti gbìn ín,+ 10  tí ó bá sì ṣe ohun tí ó burú ní ojú mi ní ti gidi nípa ṣíṣàìgbọràn sí ohùn mi,+ ṣe ni èmi yóò pèrò dà pẹ̀lú ní ti ohun rere tí mo sọ fún ara mi pé èmi yóò ṣe fún ire rẹ̀.’ 11  “Nísinsìnyí, jọ̀wọ́, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, mo ń pilẹ̀ ìyọnu àjálù kan lòdì sí yín, mo sì ń ro èrò kan lòdì sí yín.+ Kí olúkúlùkù jọ̀wọ́ yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, kí ẹ sì ṣe ọ̀nà yín àti ìbálò yín ní rere.”’”+ 12  Wọ́n sì wí pé: “Ìrètí kò sí!+ Nítorí ìrònú tiwa ni àwa yóò tẹ̀ lé, olúkúlùkù wa yóò sì mú agídí ọkàn-àyà búburú rẹ̀ ṣẹ.”+ 13  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ béèrè fún ara yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ta ni ó ti gbọ́ àwọn nǹkan bí èyí rí? Ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan wà tí wúńdíá Ísírẹ́lì ti ṣe dé ìwọ̀n tí ó pọ̀ lápọ̀jù.+ 14  Ìrì dídì Lẹ́bánónì yóò ha lọ kúrò lórí àpáta tí ó wà ní pápá gbalasa bí? Tàbí àjèjì omi, tí ó tutù, tí ń sun yóò ha gbẹ bí? 15  Nítorí àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi+ ní ti pé wọ́n ń rú èéfín ẹbọ sí ohun tí kò ní láárí,+ àti ní ti pé wọ́n ń mú àwọn ènìyàn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,+ ipa ọ̀nà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ láti rìn ní òpópónà, ọ̀nà tí a kò kọ bèbè rẹ̀, 16  láti sọ ilẹ̀ wọn di ohun ìyàlẹ́nu,+ fún sísúfèé sí fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gbẹ̀yìn yóò wò sùn-ùn tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu, yóò sì mi orí rẹ̀.+ 17  Bí ẹ̀fúùfù láti ìlà-oòrùn ni èmi yóò tú wọn ká níwájú ọ̀tá.+ Ẹ̀yìn ni èmi yóò kọ sí wọn, kì í ṣe ojú,+ ní ọjọ́ àjálù wọn.” 18  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a ro àwọn èrò kan lòdì sí Jeremáyà,+ nítorí òfin kì yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àlùfáà+ tàbí ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ wòlíì.+ Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a fi ahọ́n lù ú,+ ẹ má sì ṣe jẹ́ kí a fiyè sí èyíkéyìí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.” 19  Fiyè sí mi, Jèhófà, kí o sì fetí sí ohùn àwọn akọjú-ìjà sí mi.+ 20  Ó ha yẹ kí a fi búburú san rere bí?+ Nítorí wọ́n ti wa kòtò fún ọkàn mi.+ Rántí ìdúró mi níwájú rẹ láti sọ ohun rere àní nípa wọn, láti yí ìhónú rẹ padà kúrò lórí wọn.+ 21  Nítorí náà, fi àwọn ọmọ wọn fún ìyàn,+ sì fà wọ́n lé agbára idà lọ́wọ́;+ kí àwọn aya wọn sì di àwọn obìnrin tí ó ṣòfò ọmọ, àti opó.+ Kí àwọn ọkùnrin wọn pàápàá sì di àwọn tí a pa nípasẹ̀ ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani, kí a fi idà ṣá àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn balẹ̀ nínú ìjà ogun.+ 22  Jẹ́ kí a gbọ́ igbe láti inú ilé wọn, nígbà tí o bá mú ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí wá sórí wọn lójijì.+ Nítorí wọ́n ti wa kòtò láti fi mú mi, wọ́n sì ti fi pańpẹ́ pa mọ́ de ẹsẹ̀ mi.+ 23  Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà, mọ gbogbo ìmọ̀ràn wọn lòdì sí mi fún ikú ní àmọ̀dunjú.+ Má bo ìṣìnà wọn, má sì nu ẹ̀ṣẹ̀ wọn yẹn kúrò níwájú rẹ; ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọ́n di àwọn tí a mú kọsẹ̀ níwájú rẹ.+ Ní àkókò ìbínú rẹ, gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé