Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 16:1-21

16  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá pé:  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fẹ́ aya fún ara rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ní ibí yìí.+  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa àwọn ọmọkùnrin àti nípa àwọn ọmọbìnrin tí a bí ní ibí yìí, àti nípa àwọn ìyá wọn tí ó bí wọn àti nípa àwọn baba wọn tí ó mú kí a bí wọn ní ilẹ̀ yìí,+  ‘Ikú láti ọwọ́ àrùn ni wọn yóò kú.+ A kì yóò pohùn réré ẹkún nítorí wọn,+ bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sin wọ́n.+ Bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ ni wọn yóò dà;+ àti nípasẹ̀ idà àti nípasẹ̀ ìyàn ni wọn yóò wá sí òpin,+ ní ti gidi, òkú wọn yóò jẹ́ oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko ilẹ̀.’+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Má wọnú ilé àsè àwọn aṣọ̀fọ̀, má sì lọ láti pohùn réré ẹkún, má sì bá wọn kẹ́dùn.’+ “‘Nítorí mo ti mú àlàáfíà mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn yìí,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú.+  Dájúdájú, wọn yóò sì kú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, ní ilẹ̀ yìí. A kì yóò sin wọ́n,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kì yóò lu ara wọn nítorí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò kọ ara rẹ̀ lábẹ+ tàbí kí ó mú orí ara rẹ̀ pá nítorí wọn.+  Wọn kì yóò sì pín oúnjẹ èyíkéyìí fún wọn ní tìtorí ọ̀fọ̀ láti tu ẹnì kan nínú nítorí òkú;+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fún wọn ní ife ìtùnú mu ní tìtorí baba ẹni àti ní tìtorí ìyá ẹni.+  Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ wọ ilé àkànṣe àsè kankan láti jókòó pẹ̀lú wọn láti jẹ àti láti mu.’+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú kí ohùn ayọ̀ ńláǹlà àti ohùn ayọ̀ yíyọ̀, ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó kásẹ̀ nílẹ̀ kúrò ní ibí yìí lójú yín àti ní ọjọ́ yín.’+ 10  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí o bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n sì sọ ní ti gidi fún ọ pé, ‘Ní tìtorí kí ni Jèhófà ṣe sọ gbogbo ìyọnu àjálù ńláǹlà yìí lòdì sí wa, kí sì ni ìṣìnà wa, kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run wa?’+ 11  kí o wí fún wọn pẹ̀lú pé, ‘“Ní tìtorí òtítọ́ náà pé àwọn baba yín fi mí sílẹ̀,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “wọ́n sì ń tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, wọ́n sì ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń tẹrí ba fún wọn.+ Ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n fi sílẹ̀, òfin mi ni wọn kò sì pa mọ́.+ 12  Ẹ̀yin alára sì ti ṣe búburú nínú ìṣe yín ju àwọn baba yín lọ,+ sì kíyè sí i olúkúlùkù yín ń tọ agídí ọkàn-àyà+ búburú rẹ̀ lẹ́yìn ní ṣíṣàìgbọràn sí mi.+ 13  Dájúdájú, èmi yóò fi yín sọ̀kò kúrò ní ilẹ̀ yìí+ sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ̀,+ tàbí àwọn baba yín, níbẹ̀, ẹ ó sì sin àwọn ọlọ́run+ mìíràn ní ọ̀sán àti ní òru, nítorí èmi kì yóò fún yín ní ojú rere kankan.”’ 14  “‘Nítorí náà, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘nígbà tí a kì yóò tún wí pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè, ẹni tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì!”+ 15  bí kò ṣe: “Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè, ẹni tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti gbogbo ilẹ̀ tí ó ti fọ́n wọn ká sí!” dájúdájú, èmi yóò sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ wọn, èyí tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn.’+ 16  “‘Kíyè sí i, èmi yóò ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ apẹja,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘dájúdájú, wọn yóò sì dẹ wọ́n; àti lẹ́yìn ìgbà náà, èmi yóò ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ ọdẹ,+ dájúdájú, wọn yóò sì ṣọdẹ wọn láti orí gbogbo òkè ńlá àti láti orí gbogbo òkè kékeré, àti láti àwọn pàlàpálá àpáta gàǹgà.+ 17  Nítorí ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn. Wọn kò pa mọ́ kúrò níwájú mi, bẹ́ẹ̀ ni ìṣìnà wọn kò fara sin ní iwájú mi.+ 18  Àti pé, lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó dájú pé èmi yóò san ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye ìṣìnà wọn+ àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn padà, ní tìtorí sísọ tí wọ́n ń sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́.+ Wọ́n ti fi òkú àwọn ohun ìríra wọn àti àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn kún ogún mi.’”+ 19  Ìwọ Jèhófà okun mi àti ibi odi agbára mi, àti ibi ìsásí mi ní ọjọ́ wàhálà,+ ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn orílẹ̀-èdè fúnra wọn yóò wá láti òpin ilẹ̀ ayé,+ wọn yóò sì wí pé: “Ní tòótọ́, kìkìdá èké+ ni àwọn baba ńlá wa ní, asán àti àwọn nǹkan tí kò ní àǹfààní kankan nínú.”+ 20  Ará ayé kan ha lè ṣe àwọn ọlọ́run fún ara rẹ̀ nígbà tí wọn kì í ṣe ọlọ́run?+ 21  “Nítorí náà, kíyè sí i, èmi yóò jẹ́ kí wọ́n mọ̀; lẹ́ẹ̀kan yìí, èmi yóò jẹ́ kí wọ́n mọ ọwọ́ mi àti agbára ńlá mi,+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé orúkọ mi ni Jèhófà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé