Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 15:1-21

15  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti wí fún mi pé: “Bí Mósè+ àti Sámúẹ́lì+ bá dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò sí níhà ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn yìí.+ A óò rán wọn lọ kúrò níwájú mi, kí wọ́n lè jáde lọ.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí wọ́n bá sọ fún ọ pé, ‘Ibo ni àwa yóò jáde lọ?’ kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹnì yòówù tí ó bá wà fún ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani, sí ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani! Ẹnì yòówù tí ó bá sì wà fún idà, sí idà! Ẹnì yòówù tí ó bá sì wà fún ìyàn, sí ìyàn!+ Ẹnì yòówù tí ó bá sì wà fún oko òǹdè, sí oko òǹdè!”’+  “‘Dájúdájú, èmi yóò fàṣẹ yan ìdílé mẹ́rin lé wọn lórí,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘idà láti pa, àti àwọn ajá láti wọ́ lọ, àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run+ àti àwọn ẹranko ilẹ̀ láti jẹ àti láti run.  Dájúdájú, èmi yóò fi wọ́n fún ìmìtìtì lójú gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé+ ní tìtorí Mánásè ọmọkùnrin Hesekáyà, ọba Júdà, nítorí ohun tí ó ṣe ní Jerúsálẹ́mù.+  Nítorí ta ni yóò fi ìyọ́nú hàn sí ìwọ,+ Jerúsálẹ́mù, ta ni yóò sì bá ọ kẹ́dùn, ta ni yóò sì yà láti béèrè nípa àlàáfíà rẹ?’  “‘Ìwọ fúnra rẹ ti kọ̀ mí tì,’+ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Ẹ̀yìn ni ìwọ ń rìn lọ.+ Èmi yóò sì na ọwọ́ mi lòdì sí ọ láti run ọ́.+ Kíkẹ́dùn ti sú mi.+  Èmi yóò sì fi àmúga fẹ́ wọn bí ọkà+ ní àwọn ẹnubodè ilẹ̀ náà. Dájúdájú, èmi yóò mú kí wọ́n ṣòfò ọmọ.+ Ṣe ni èmi yóò pa àwọn ènìyàn mi run, níwọ̀n bí wọn kò ti yí padà kúrò ní ọ̀nà tiwọn.+  Sí mi, àwọn opó wọn ti di púpọ̀ níye ju àwọn egunrín iyanrìn òkun. Dájúdájú, èmi yóò mú afiniṣèjẹ ní ọjọ́kanrí wá fún wọn, wá bá ìyá àti ọ̀dọ́kùnrin.+ Èmi yóò mú kí ìrusókè àti ìyọlẹ́nu ṣubú tẹ̀ wọ́n lójijì.+  Okun ti tán nínú obìnrin tí ó bí ọmọ méje; ọkàn rẹ̀ ń mí gúlégúlé.+ Oòrùn rẹ̀ ti wọ̀ nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀sán;+ ìtìjú ti bá a, ó sì ti tẹ́.’ ‘Idà sì ni èmi yóò fi àṣẹ́kù wọn lásán fún níwájú àwọn ọ̀tá wọn,’+ ni àsọjáde Jèhófà.” 10  Ègbé ni fún mi,+ ìwọ ìyá mi, nítorí pé o bí mi, ọkùnrin tí ó dojú kọ aáwọ̀ àti ọkùnrin tí ó dojú kọ gbọ́nmi-sí omi-ò-to pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ ayé.+ Èmi kò fúnni ní ẹ̀yáwó, wọn kò sì fún mi ní ẹ̀yáwó. Gbogbo wọn ń pe ibi wá sórí mi.+ 11  Jèhófà wí pé: “Dájúdájú, èmi yóò ṣe ìránṣẹ́ fún ọ fún rere.+ Dájúdájú, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún ọ ní àkókò ìyọnu àjálù+ àti ní àkókò wàhálà, lòdì sí àwọn ọ̀tá.+ 12  Ènìyàn ha lè fọ́ irin sí wẹ́wẹ́, irin láti àríwá, àti bàbà? 13  Ohun àmúṣọrọ̀ rẹ àti ìṣúra rẹ ni èmi yóò fi fúnni fún ìpiyẹ́ lásán,+ kì í ṣe fún iye owó, ṣùgbọ́n fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, àní ní gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ.+ 14  Dájúdájú, èmi yóò mú kí wọ́n ré kọjá pẹ̀lú àwọn ọ̀tá rẹ sí ilẹ̀ tí o kò mọ̀.+ Nítorí a ti mú iná kan ràn nínú ìbínú mi.+ A ti mú un ràn lára yín.” 15  Ìwọ fúnra rẹ ti mọ̀.+ Jèhófà, rántí mi+ kí o sì yí àfiyèsí rẹ sí mi, kí o sì gbẹ̀san mi lára àwọn onínúnibíni mi.+ Nínú ìlọ́ra rẹ láti bínú, má ṣe mú mi kúrò.+ Fiyè sí rírù tí mo ń ru ẹ̀gàn ní tìtorí rẹ.+ 16  A rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́;+ ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà+ àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi;+ nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí,+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+ 17  Èmi kò jókòó ní àwùjọ tímọ́tímọ́ àwọn tí ń ṣe àwàdà,+ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ ayọ̀ ńláǹlà.+ Nítorí ọwọ́ rẹ, ṣe ni mo dá jókòó ní èmi nìkan,+ nítorí o ti fi ìdálẹ́bi kún inú mi.+ 18  Èé ṣe tí ìrora mi fi di bárakú,+ tí ọgbẹ́ mi sì di aláìṣeéwòsàn?+ Ó ti kọ̀ láti sàn. Ó dájú hán-ún pé, ìwọ dà bí ohun ẹ̀tàn sí mi,+ bí omi tí ó jẹ́ aláìṣeégbẹ́kẹ̀lé.+ 19  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Bí ẹ óò bá padà, nígbà náà, èmi yóò mú yín padà wá.+ Ẹ óò dúró níwájú mi.+ Bí ẹ óò bá sì mú ohun ṣíṣeyebíye jáde wá láti inú àwọn ohun tí kò ní láárí, ẹ ó dà bí ẹnu tèmi. Àwọn fúnra wọn yóò padà wá bá ọ, ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ kì yóò padà wá bá wọn.” 20  “Mo sì ti ṣe ọ́ ní ògiri olódi bàbà fún àwọn ènìyàn yìí;+ ó sì dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ.+ Nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ, láti gbà ọ́ là àti láti dá ọ nídè,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 21  “Dájúdájú, èmi dá ọ nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn ẹni búburú,+ èmi yóò sì tún ọ rà padà kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé