Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 14:1-22

14  Èyí ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó tọ Jeremáyà wá nípa ọ̀ràn ọ̀gbẹlẹ̀:+  Júdà ti wọnú ìṣọ̀fọ̀,+ àwọn ẹnubodè rẹ̀ gan-an ti dá páro.+ Wọ́n ti dorí kodò kan ilẹ̀,+ kódà igbe ẹkún Jerúsálẹ́mù ti gòkè lọ.+  Àwọn ènìyàn wọn tí ó jẹ́ ọlọ́lá ọba sì ti rán àwọn ènìyàn wọn tí kò jámọ́ nǹkan kan lọ bu omi.+ Wọ́n ti wá sí àwọn kòtò. Wọn kò rí omi kankan.+ Wọ́n ti gbé òfìfo ládugbó wọn padà. Ìtìjú ti bá wọn,+ wọ́n sì ti já kulẹ̀, wọ́n sì ti bo orí wọn.+  Ní tìtorí ilẹ̀ tí a ti fọ́ túútúú, nítorí pé eji wọwọ kò rọ̀ sórí ilẹ̀ náà,+ ojú ti ti àwọn àgbẹ̀; wọ́n ti bo orí wọn.+  Nítorí, àní egbin inú pápá ti bímọ, ṣùgbọ́n ó fi í sílẹ̀, nítorí kò sí koríko tútù yọ̀yọ̀.  Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà+ pàápàá dúró jẹ́ẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké dídán borokoto; wọ́n ti fa ẹ̀fúùfù símú bí akátá; ojú wọn ti kọṣẹ́ nítorí pé kò sí ewéko.+  Kódà bí ìṣìnà tiwa bá jẹ́rìí lòdì sí wa, Jèhófà, gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ rẹ;+ nítorí ìwà àìṣòótọ́ wa ti di púpọ̀;+ ìwọ ni a ti dẹ́ṣẹ̀ sí.+  Ìwọ, ìrètí Ísírẹ́lì,+ Olùgbàlà rẹ̀+ ní àkókò wàhálà,+ èé ṣe tí o fi dà bí àtìpó ní ilẹ̀ náà, àti bí arìnrìn-àjò tí ó yà láti sùn mọ́jú?+  Èé ṣe tí o fi dà bí ọkùnrin tí háà ṣe, bí ọkùnrin alágbára ńlá tí kò lè gbani là rárá?+ Síbẹ̀, ìwọ fúnra rẹ wà ní àárín wa,+ Jèhófà, a sì ń pe orúkọ rẹ mọ́ wa.+ Má ṣe já wa kulẹ̀. 10  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa àwọn ènìyàn yìí: “Báyìí ni wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ láti máa rìn gbéregbère;+ wọn kò ṣàkóso ẹsẹ̀ wọn.+ Nítorí náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ kò ní ìdùnnú kankan sí wọn.+ Nísinsìnyí, òun yóò rántí ìṣìnà wọn, yóò sì fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní àfiyèsí.”+ 11  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti wí fún mi pé: “Má gbàdúrà nítorí àwọn ènìyàn yìí fún ire èyíkéyìí.+ 12  Nígbà tí wọ́n bá gbààwẹ̀, èmi kì yóò fetí sí igbe ìpàrọwà wọn;+ nígbà tí wọ́n bá sì fi odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ọkà rúbọ, èmi kì yóò ní ìdùnnú sí wọn;+ nítorí pé idà àti ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn ni èmi yóò fi mú wọn wá sí òpin wọn.”+ 13  Látàrí èyí, mo wí pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kì yóò rí idà, ìyàn kì yóò sì dé bá yín, ṣùgbọ́n àlàáfíà tòótọ́ ni èmi yóò fún yín ní ibí yìí.’”+ 14  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi.+ Èmi kò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò pàṣẹ fún wọn tàbí bá wọn sọ̀rọ̀.+ Ìran èké àti ìwoṣẹ́ àti ohun tí kò ní láárí+ àti àgálámàṣà ọkàn-àyà wọn ni wọ́n ń sọ ní àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.+ 15  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa àwọn wòlíì tí ń sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi, àwọn tí èmi fúnra mi kò rán, tí wọ́n ń wí pé idà tàbí ìyàn kankan kì yóò dé bá ilẹ̀ yìí, ‘Nípa idà àti ìyàn ni àwọn wòlíì wọnnì yóò wá sí òpin wọn.+ 16  Àwọn ènìyàn tí wọ́n sì ń sọ tẹ́lẹ̀ fún gan-an yóò di àwọn ènìyàn tí a lé jáde sí àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù nítorí ìyàn àti idà náà, láìsí ẹni tí yóò sin wọ́n—àwọn, àwọn aya wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn.+ Èmi yóò sì da ìyọnu àjálù wọn sórí wọn dájúdájú.’+ 17  “Kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ‘Jẹ́ kí omijé ṣàn wálẹ̀ ní ojú mi ní ọ̀sán àti ní òru, má sì jẹ́ kí wọ́n dá,+ nítorí ìfọ́yángá ńláǹlà ni a fi ṣẹ́ wúńdíá ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi,+ pẹ̀lú ọgbẹ́ amúniya-aláìsàn dé góńgó.+ 18  Ní ti gidi, bí mo bá jáde lọ sínú pápá, wò ó, nísinsìnyí, àwọn tí a fi idà pa!+ Ní ti gidi, bí mo bá sì wá sínú ìlú ńlá, wò ó, pẹ̀lú, àwọn àrùn nítorí ìyàn!+ Nítorí àti wòlíì àti àlùfáà ti lọ káàkiri sí ilẹ̀ kan tí wọn kò mọ̀.’”+ 19  O ha ti kọ Júdà pátápátá ni bí,+ tàbí ọkàn rẹ ha ti kórìíra Síónì tẹ̀gàntẹ̀gàn?+ Èé ṣe tí o fi kọlù wá, tí kò fi sí ìmúláradá kankan fún wa?+ Ìrètí fún àlàáfíà wà, ṣùgbọ́n ohun rere kankan kò sí; àti fún àkókò ìmúláradá, sì wò ó! ìpayà!+ 20  Jèhófà, a jẹ́wọ́ ìwà burúkú wa, ìṣìnà àwọn baba ńlá wa,+ nítorí a ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.+ 21  Má ṣàìbọlá fún wa nítorí orúkọ rẹ;+ má ṣe tẹ́ńbẹ́lú ìtẹ́ ògo rẹ.+ Rántí; má ba májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú wa jẹ́.+ 22  Èyíkéyìí ha wà nínú àwọn òrìṣà asán+ ti àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó lè rọ òjò, tàbí ọ̀run pàápàá ha lè rọ ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò?+ Kì í ha ṣe ìwọ ni Ẹni náà, Jèhófà Ọlọ́run wa?+ A sì ní ìrètí nínú rẹ, nítorí ìwọ fúnra rẹ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé