Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 13:1-27

13  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi: “Lọ, kí o sì wá ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ̀ fún ara rẹ, kí o sì fi sí ìgbáròkó rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú un wọnú omi èyíkéyìí.”  Nítorí náà, mo wá ìgbànú náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà, mo sì fi sí ìgbáròkó mi.  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá ní ìgbà kejì pé:  “Mú ìgbànú tí o rí yẹn, tí ó wà ní ìgbáròkó rẹ, sì dìde, lọ sí Yúfírétì,+ sì fi pa mọ́ síbẹ̀, nínú pàlàpálá àpáta gàǹgà.”  Nítorí náà, mo lọ, mo sì fi pa mọ́ sẹ́bàá Yúfírétì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún mi.  Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ ní òpin ọjọ́ púpọ̀ pé Jèhófà tẹ̀ síwájú láti wí fún mi pé: “Dìde, lọ sí Yúfírétì, kí o sì mú ìgbànú tí mo pàṣẹ pé kí o fi pa mọ́ sí ibẹ̀ kúrò níbẹ̀.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, mo lọ sí Yúfírétì, mo walẹ̀, mo sì mú ìgbànú náà ní ibi tí mo fi pa mọ́ sí, sì wò ó! ìgbànú náà ti bàjẹ́; kò yẹ fún ohunkóhun.  Nígbà náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní ọ̀nà kan náà ni èmi yóò run ìyangàn Júdà+ àti ọ̀pọ̀ yanturu ìyangàn Jerúsálẹ́mù. 10  Àwọn ènìyàn búburú yìí tí wọ́n ń kọ̀ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi,+ tí wọ́n ń rìn nínú agídí ọkàn-àyà wọn,+ tí wọ́n sì ń tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn ṣáá láti sìn wọ́n àti láti tẹrí ba fún wọn,+ àwọn pẹ̀lú yóò dà bí ìgbànú yìí tí kò yẹ fún nǹkan kan.’ 11  ‘Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbànú ti ń lẹ̀ mọ́ ìgbáròkó ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́ kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì àti gbogbo ilé Júdà lẹ̀ mọ́ mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti di ènìyàn kan+ àti orúkọ+ kan àti ìyìn kan àti ohun ẹlẹ́wà fún mi; ṣùgbọ́n wọn kò ṣègbọràn.’+ 12  “Kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ‘Èyí ní ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Olúkúlùkù ìṣà títóbi jẹ́ ohun kan tí ń kún fún wáìnì.”’+ Dájúdájú, wọn yóò sì wí fún ọ pé, ‘A kò ha mọ̀ dájú pé olúkúlùkù ìṣà títóbi jẹ́ ohun kan tí ń kún fún wáìnì?’ 13  Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò fi ìmutípara+ kún gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí àti àwọn ọba tí wọ́n jókòó nípò Dáfídì+ lórí ìtẹ́ rẹ̀ àti àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù. 14  Dájúdájú, èmi yóò sì fi wọ́n kọlura, àwọn baba àti àwọn ọmọ, ní àkókò kan náà,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Èmi kì yóò fi ìyọ́nú hàn, tàbí kí n káàánú, èmi kì yóò sì ní àánú tí kì yóò jẹ́ kí n run wọ́n.”’+ 15  “Ẹ gbọ́, ẹ sì fi etí sílẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ onírera,+ nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ̀rọ̀.+ 16  Ẹ fi ògo fún Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ó tó fa òkùnkùn,+ kí ẹsẹ̀ yín sì tó gbá ara wọn lórí àwọn òkè ńlá ní àṣálẹ́.+ Dájúdájú, ẹ óò sì retí ìmọ́lẹ̀,+ òun yóò sì ṣe é ní ibú òjìji ní ti gidi;+ òun yóò sọ ọ́ di ìṣúdùdù tí ó nípọn.+ 17  Bí ẹ kò bá sì gbọ́,+ ní àwọn ibi ìlùmọ́, ọkàn mi yóò sunkún nítorí ìgbéraga, dájúdájú, yóò sì da omijé; omijé yóò ṣàn wálẹ̀ ní ojú mi,+ nítorí agbo+ Jèhófà ni a ó ti kó lọ ní òǹdè. 18  “Sọ fún ọba àti fún ìyáàfin+ pé, ‘Ẹ jókòó sí ibi rírẹlẹ̀,+ nítorí adé ẹwà yín yóò ṣí kúrò ní orí yín dájúdájú.’+ 19  Àwọn ìlú ńlá gúúsù pàápàá ni a ti tì pa, tí kò fi sí ẹni tí ó ń ṣí wọn. Júdà látòkè délẹ̀ ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn. A ti kó o lọ sí ìgbèkùn pátápátá.+ 20  “Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tí ń bọ̀ láti àríwá.+ Agbo ẹran ọ̀sìn tí a fi fún ọ dà, agbo ẹran rẹ ẹlẹ́wà?+ 21  Kí ni ìwọ yóò sọ nígbà tí ẹnì kan bá yí àfiyèsí rẹ̀ sí ọ,+ nígbà tí ìwọ fúnra rẹ ti kọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àfinúhàn rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ gan-an láti ìbẹ̀rẹ̀?+ Ìroragógó ìbímọ pàápàá kì yóò ha gbá ọ mú bí, bí ti aya kan tí ó fẹ́ bímọ?+ 22  Nígbà tí o bá sì wí ní ọkàn-àyà+ rẹ pé, ‘Èé ṣe tí nǹkan wọ̀nyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?’+ nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ìṣìnà rẹ, apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ ni a ti ká kúrò gẹ́gẹ́ bí ìbora;+ gìgísẹ̀ rẹ ni a ti ṣe léṣe. 23  “Ọmọ Kúṣì+ ha lè yí awọ ara rẹ̀ padà? tàbí àmọ̀tẹ́kùn ha lè yí àmì ara rẹ̀ padà bí?+ Ẹ̀yin pẹ̀lú yóò lè ṣe rere, ẹ̀yin ẹni tí a kọ́ láti ṣe búburú.+ 24  Nítorí náà, èmi yóò tú wọn ká+ bí àgékù pòròpórò tí ó ń kọjá lọ nínú ẹ̀fúùfù láti aginjù.+ 25  Èyí ni ìpín rẹ, ìpín rẹ tí a díwọ̀n láti ọ̀dọ̀ mi,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “nítorí o ti gbàgbé mi,+ o sì ń fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sínú èké.+ 26  Èmi fúnra mi pẹ̀lú yóò sì ká ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ sókè bo ojú rẹ, dájúdájú, a ó sì rí àbùkù rẹ,+ 27  ìwà panṣágà rẹ+ àti yíyán rẹ,+ ìwà àìníjàánu rẹ nínú iṣẹ́ kárùwà. Lórí àwọn òkè kéékèèké, ní pápá, mo ti rí àwọn ohun ìríra rẹ.+ Ègbé ni fún ọ, ìwọ Jerúsálẹ́mù! O kò lè mọ́+—yóò ti pẹ́ sí i tó?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé