Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 12:1-17

12  Olódodo ni ìwọ,+ Jèhófà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ mi wá sọ́dọ̀ rẹ, nítòótọ́, nígbà tí mo bá ọ sọ̀rọ̀, àní nípa ọ̀ràn ìdájọ́. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé ọ̀nà àwọn ẹni burúkú ni ó kẹ́sẹ járí,+ pé gbogbo àwọn tí ó ń ṣe àdàkàdekè ni ó jẹ́ aláìní ìdààmú-ọkàn?  O ti gbìn wọ́n; wọ́n ti ta gbòǹgbò pẹ̀lú. Wọ́n ń tẹ̀ síwájú ṣáá; wọ́n sì so èso pẹ̀lú. Ìwọ wà nítòsí ẹnu wọn, ṣùgbọ́n o jìnnà réré sí kíndìnrín wọn.+  Ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà, sì mọ̀ mí dáadáa;+ ìwọ rí mi, o sì ti ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà mi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ara rẹ.+ Ṣà wọ́n jáde bí àgùntàn fún pípa,+ sì yà wọ́n sọ́tọ̀ gedegbe fún ọjọ́ pípa.  Yóò ti pẹ́ tó tí ilẹ̀ náà yóò máa bá a nìṣó ní ṣíṣá,+ àní tí ewéko gbogbo pápá yóò sì gbẹ dànù?+ Nítorí ìwà búburú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀, àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ni a ti gbá lọ.+ Nítorí wọ́n wí pé: “Kò rí ọjọ́ ọ̀la wa.”  Nítorí pé ìwọ ti bá àwọn ẹlẹ́sẹ̀ sáré, wọ́n sì kó àárẹ̀ bá ọ, báwo wá ni ìwọ ṣe lè bá àwọn ẹṣin sá eré ìje?+ O ha sì ní ìgbọ́kànlé nínú ilẹ̀ àlàáfíà bí?+ Nítorí náà, báwo ni ìwọ yóò ṣe gbé ìgbésẹ̀ láàárín àwọn agbéraga ìgbòrò lẹ́bàá Jọ́dánì?+  Nítorí àní àwọn arákùnrin rẹ àti agbo ilé baba rẹ pàápàá, àní àwọn fúnra wọn ti ṣe àdàkàdekè sí ọ.+ Àní lẹ́yìn rẹ ni àwọn fúnra wọn ti ké kíkankíkan. Má ṣe ní ìgbàgbọ́ kankan nínú wọn, kìkì nítorí pé wọn sọ àwọn ohun rere fún ọ.+  “Mo ti fi ilé mi sílẹ̀;+ mo ti kọ ogún mi tì;+ mo ti fi olùfẹ́ ọ̀wọ́n ọkàn mi lé àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọ̀tá mi.+  Sí mi, ogún mi ti dà bí kìnnìún nínú igbó. Ó ti gbé ohùn rẹ̀ sókè lòdì sí mi. Ìdí nìyẹn tí mo fi kórìíra rẹ̀.+  Sí mi, ogún mi+ ti dà bí ẹyẹ aṣọdẹ tí ó jẹ́ kàlákìnní; àwọn ẹyẹ aṣọdẹ wà lórí rẹ̀ yí ká.+ Ẹ wá, ẹ kóra jọpọ̀, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá; ẹ kó wọn wá jẹun.+ 10  Àní ọ̀pọ̀ olùṣọ́ àgùntàn+ ti run ọgbà àjàrà mi;+ wọ́n ti fi ẹsẹ̀ tẹ ìpín mi mọ́lẹ̀.+ Wọ́n ti sọ ìpín mi fífanimọ́ra+ di aginjù tí ó jẹ́ ahoro. 11  Ẹnì kan ti sọ ọ́ di ahoro;+ ó ti rọ dànù; ahoro ni sí mi.+ Gbogbo ilẹ̀ náà ni a ti sọ di ahoro, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó fi í sí ọkàn-àyà.+ 12  Gbogbo ipa ọ̀nà àrìnkúnná tí ó gba aginjù kọjá ni àwọn afiniṣèjẹ ti gbà wá. Nítorí idà tí ó jẹ́ ti Jèhófà ń jẹ run láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ náà, àní dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ náà.+ Kò sí àlàáfíà kankan fún ẹran ara èyíkéyìí. 13  Wọ́n ti fúnrúgbìn àlìkámà, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọ́n kárúgbìn rẹ̀.+ Wọ́n ti ṣiṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àìsàn fi kọlù wọ́n; wọn kì yóò jàǹfààní kankan.+ Dájúdájú, ojú yóò sì tì wọ́n nítorí àmújáde yín, nítorí ìbínú jíjófòfò Jèhófà.” 14  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí lòdì sí gbogbo aládùúgbò mi búburú,+ tí wọ́n ń fọwọ́ kan ohun ìní àjogúnbá tí mo mú kí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, ní:+ “Kíyè sí i, èmi yóò fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn;+ ilé Júdà sì ni èmi yóò fà tu kúrò ní àárín wọn.+ 15  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, lẹ́yìn tí mo bá fà wọ́n tu, èmi yóò tún ṣàánú wọn,+ èmi yóò sì mú wọn padà wá, olúkúlùkù sí ohun ìní àjogúnbá rẹ̀ àti olúkúlùkù sí ilẹ̀ rẹ̀.”+ 16  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n bá kọ́ ọ̀nà àwọn ènìyàn mi láìkùnà, ní fífi orúkọ mi búra,+ ‘Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè!’ gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Báálì búra,+ a óò gbé wọn ró pẹ̀lú ní àárín àwọn ènìyàn mi.+ 17  Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá ṣègbọràn, ṣe ni èmi yóò fa orílẹ̀-èdè yẹn tu pẹ̀lú, ní fífà á tu àti pípa á run,”+ ni àsọjáde Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé