Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 11:1-23

11  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé:  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí! “Kí o sì sọ+ ọ́ fún àwọn ènìyàn Júdà àti fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù,  kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ègún ni fún ènìyàn tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí,+  èyí tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò nínú ìléru irin,+ pé, ‘Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi, kí ẹ sì ṣe àwọn nǹkan ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín;+ dájúdájú, ẹ ó sì di ènìyàn mi, èmi alára yóò sì di Ọlọ́run yín,+  láti lè mú ìbúra tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ,+ láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,+ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní òní yìí.’”’” Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn pé: “Àmín, Jèhófà.”  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: “Pòkìkí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù,+ pé, ‘Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì pa wọ́n mọ́.+  Nítorí mo ṣí àwọn baba ńlá yín létí lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ ní ọjọ́ tí mo ń mú wọn gòkè bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì+ àti títí di ọjọ́ òní yìí, mo ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń ṣí wọn létí, pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi.”+  Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dẹ etí wọn sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n wọ́n ń rìn ṣáá, olúkúlùkù nínú agídí ọkàn-àyà búburú wọn;+ nítorí náà, mo mú gbogbo ọ̀rọ̀ inú májẹ̀mú yìí wá sórí wọn, èyí tí mo pa láṣẹ fún wọn láti pa mọ́, ṣùgbọ́n tí wọn kò pa mọ́.’”  Síwájú sí i, Jèhófà sọ fún mi pé: “A ti rí tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun láàárín àwọn ènìyàn Júdà àti láàárín àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù.+ 10  Wọ́n ti padà sínú àwọn ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn,+ àwọn ti àkọ́kọ́, tí ó kọ̀ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi, ṣùgbọ́n tí àwọn fúnra wọn ti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n.+ Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti da májẹ̀mú mi, èyí tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá.+ 11  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù+ wá sórí wọn, tí wọn kò ní lè bọ́ nínú rẹ̀;+ dájúdájú, wọn yóò sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n èmi kì yóò fetí sí wọn.+ 12  Àwọn ìlú ńlá Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù yóò sì ní láti lọ ké pe àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń rú èéfín ẹbọ sí,+ fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n tí kì yóò mú ìgbàlà wá fún wọn rárá ní àkókò ìyọnu àjálù wọn.+ 13  Nítorí àwọn ọlọ́run rẹ ti pọ̀ bí àwọn ìlú ńlá rẹ ti pọ̀ tó, ìwọ Júdà;+ àwọn pẹpẹ tí ó sì pọ̀ bí àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù ti pọ̀ tó ni ẹ̀yin ti mọ fún ohun ìtìjú,+ àwọn pẹpẹ láti máa fi rú èéfín ẹbọ sí Báálì.’+ 14  “Àti ní ti ìwọ, má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn ènìyàn yìí, má sì ṣe gbé ohùn igbe ìpàrọwà tàbí àdúrà sókè nítorí wọn,+ nítorí èmi kò ní fetí sílẹ̀ ní àkókò tí wọ́n bá ń ké pè mí nípa ìyọnu àjálù wọn.+ 15  “Iṣẹ́ wo ni olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n ń ṣe nínú ilé mi,+ tí púpọ̀ nínú wọn fi ní láti ṣe ohun yìí,+ ète ibi?+ Wọn yóò ha sì fi ẹran mímọ́ mú kí ó ré ọ kọjá bí,+ nígbà tí ìyọnu àjálù rẹ bá dé? Ní àkókò yẹn, ìwọ yóò ha yọ ayọ̀ ńláǹlà bí?+ 16  ‘Igi ólífì gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, tí ó rẹwà nínú èso àti ní ìrísí,’ ni Jèhófà ti pe orúkọ rẹ.+ Pẹ̀lú ìró ìkéramúramù tí ó pọ̀, ó ti fi iná jó o, wọ́n sì ti ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀.+ 17  “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀, Ẹni tí ó gbìn ọ́,+ sì ti sọ̀rọ̀ ìyọnu àjálù lòdì sí ọ ní tìtorí ìwà búburú ilé Ísírẹ́lì+ àti ilé Júdà tí wọ́n ti hù níhà ọ̀dọ̀ wọn láti mú mi bínú ní rírú èéfín ẹbọ sí Báálì.”+ 18  Jèhófà tìkára rẹ̀ sì ti sọ fún mi kí n lè mọ̀. Ní àkókò yẹn, o mú mi rí ìbálò wọn.+ 19  Mo sì dà bí akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, èyí tí ó ṣe tímọ́tímọ́, tí a mú wá fún pípa,+ èmi kò sì mọ̀ pé èmi ni wọ́n pète-pèrò lòdì sí pé:+ “Ẹ jẹ́ kí a run igi náà pẹ̀lú oúnjẹ rẹ̀, kí a sì ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè,+ kí a má bàa rántí orúkọ rẹ̀ gan-an mọ́.” 20  Ṣùgbọ́n Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ń fi òdodo ṣe ìdájọ́;+ ó ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín àti ọkàn-àyà.+ Jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn, nítorí ìwọ ni mo ṣí ẹjọ́ mi lábẹ́ òfin payá fún.+ 21  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí lòdì sí àwọn ènìyàn Ánátótì+ tí wọ́n ń wá ọkàn rẹ, pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà,+ kí o má bàa kú ní ọwọ́ wa”; 22  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Kíyè sí i, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí wọn. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá yóò tipa idà kú.+ Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn yóò tipa ìyàn kú.+ 23  Kì yóò sì sí àṣẹ́kù kankan fún wọn, nítorí èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí àwọn ènìyàn Ánátótì,+ ní ọdún ti a óò fún wọn ní àfiyèsí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé