Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 10:1-25

10  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ lòdì sí yín, ilé Ísírẹ́lì.  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ má ṣe kọ́ ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè rárá,+ ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ìpayà bá yín àní nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run, nítorí ìpayà ti bá àwọn orílẹ̀-èdè nítorí wọn.+  Nítorí àṣà àwọn ènìyàn+ jẹ́ èémí àmíjáde lásán, nítorí igi+ igbó lásán ni ẹnì kan gé lulẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú ohun èlò tí a fi ń gbẹ́ nǹkan.+  Fàdákà àti wúrà ni ènìyàn fi mú un lẹ́wà ní ìrísí.+ Ìṣó àti òòlù ni wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀, tí ọ̀kankan kò fi ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.+  Wọ́n dà bí aṣọ́ko-másùn nínú oko apálá, wọn kò sì lè sọ̀rọ̀.+ Gbígbé ni a ń gbé wọn, nítorí wọn kò lè gbé ìṣísẹ̀ kankan.+ Má fòyà nítorí wọn, nítorí wọn kò lè ṣe nǹkan kan tí ń mú ìyọnu àjálù wá àti pé, jù bẹ́ẹ̀ lọ, rere ṣíṣe kankan kò sì lọ́wọ́ wọn.”+  Lọ́nàkọnà, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí ìwọ, Jèhófà.+ O tóbi, orúkọ rẹ sì pọ̀ ní agbára ńlá.+  Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ,+ ìwọ Ọba àwọn orílẹ̀-èdè,+ nítorí ìwọ ni ó yẹ; nítorí láàárín gbogbo ọlọ́gbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè àti láàárín gbogbo ipò ọba wọn, lọ́nàkọnà, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí ìwọ.+  Ní àkókò kan náà, wọ́n jẹ́ aláìnírònú àti arìndìn.+ Ìgbani-níyànjú asán ni igi jẹ́.+  Fàdákà tí a ṣe pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ni a mú wá àní láti Táṣíṣì,+ àti wúrà láti Úfásì,+ iṣẹ́ ọnà oníṣẹ́ ọnà àti ti ọwọ́ oníṣẹ́ irin; aṣọ wọn jẹ́ fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti ìrun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró. Gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọnà àwọn ọ̀jáfáfá.+ 10  Ṣùgbọ́n ní òtítọ́, Jèhófà ni Ọlọ́run.+ Òun ni Ọlọ́run alààyè+ àti Ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Nítorí ìkannú rẹ̀, ilẹ̀ ayé yóò mì jìgìjìgì,+ orílẹ̀-èdè kankan kì yóò sì dúró lábẹ́ ìdálẹ́bi rẹ̀.+ 11  Èyí ni ohun tí ẹ ó sọ fún wọn: “Àwọn ọlọ́run+ tí kò ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ni yóò ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ ayé+ àti kúrò lábẹ́ ọ̀run yìí.” 12  Òun ni Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ agbára rẹ̀,+ Ẹni náà tí ó fìdí ilẹ̀ eléso múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ ọgbọ́n rẹ̀,+ àti Ẹni náà tí ó na ọ̀run nípasẹ̀ òye rẹ̀.+ 13  Nígbà tí ohùn rẹ̀ dún, òun a fúnni ní ìdàwìtìwìtì omi ní ojú ọ̀run,+ a sì mú kí oruku ròkè láti ìkángun ilẹ̀ ayé.+ Ó tilẹ̀ ti ṣe ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ fún òjò,+ ó sì ń mú ẹ̀fúùfù jáde wá láti inú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ̀.+ 14  Olúkúlùkù ènìyàn ti hùwà àìnírònú tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi mọ̀.+ Olúkúlùkù oníṣẹ́ irin ni ojú yóò tì dájúdájú nítorí ère gbígbẹ́;+ nítorí ère dídà rẹ̀ jẹ́ èké,+ kò sì sí ẹ̀mí kankan nínú wọn.+ 15  Asán ni wọ́n, iṣẹ́ àfiṣẹlẹ́yà.+ Wọn yóò ṣègbé ní àkókò tí a bá fún wọn ní àfiyèsí.+ 16  Ìpín Jékọ́bù+ kò rí bí nǹkan wọ̀nyí, nítorí òun ni Aṣẹ̀dá ohun gbogbo,+ Ísírẹ́lì sì ni ọ̀pá ogún rẹ̀.+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+ 17  Kó ẹrù tí o dìjọ kúrò ní ilẹ̀,+ ìwọ obìnrin tí ń gbé lábẹ́ másùnmáwo.+ 18  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò gbọn àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé nù ní àkókò yìí,+ dájúdájú, èmi yóò sì kó wàhálà bá wọn kí wọ́n lè rídìí rẹ̀.”+ 19  Ègbé ni fún mi ní tìtorí ìwópalẹ̀ mi!+ Ọgbẹ́ mi ti di amúniya-aláìsàn. Èmi fúnra mi sì wí pé: “Dájúdájú, èyí ni àìsàn mi, èmi yóò sì rù ú.+ 20  A ti fi àgọ́ tèmi ṣe ìjẹ, gbogbo okùn àgọ́ mi sì ni a ti fà já sí méjì.+ Àwọn ọmọ mi ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́.+ Kò sí ẹni tí ń na àgọ́ mi tàbí tí ń gbé àwọn aṣọ àgọ́ mi sókè mọ́. 21  Nítorí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti hùwà àìnírònú,+ wọn kò sì wá Jèhófà pàápàá.+ Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, gbogbo ẹran wọn tí ń jẹko sì ni a ti tú ká.”+ 22  Fetí sílẹ̀! Ìròyìn kan! Kíyè sí i, ó ti dé, bákan náà, ìbìlù ńlá láti ilẹ̀ àríwá,+ láti sọ àwọn ìlú ńlá Júdà di ahoro, ibùgbé àwọn akátá.+ 23  Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.+ 24  Tọ́ mi sọ́nà, Jèhófà, bí ó ti wù kí ó rí pẹ̀lú ìdájọ́;+ kì í ṣe nínú ìbínú rẹ,+ kí o má bàa sọ mí di asán.+ 25  Da ìhónú rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí ó ti fi ọ́ dá àgunlá,+ àti sórí àwọn ìdílé tí kò ké pe orúkọ rẹ.+ Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jékọ́bù run.+ Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti jẹ ẹ́ tán, wọ́n sì ń bá a lọ láti pa á run pátápátá;+ ibi gbígbé rẹ̀ ni wọ́n sì ti sọ di ahoro.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé