Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 1:1-19

1  Àwọn ọ̀rọ̀ Jeremáyà,+ ọmọ Hilikáyà, ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó wà ní Ánátótì,+ ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì;+  ẹni tí ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ wá ní ọjọ́ Jòsáyà+ ọmọkùnrin Ámọ́nì,+ ọba Júdà, ní ọdún kẹtàlá ìgbà ìjọba rẹ̀.+  Ó sì ń bá a nìṣó láti tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, títí di òpin ọdún kọkànlá Sedekáyà,+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, títí Jerúsálẹ́mù fi lọ sí ìgbèkùn ní oṣù karùn-ún.+  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá, pé:  “Kí n tó ṣẹ̀dá rẹ nínú ikùn,+ mo mọ̀ ọ́,+ kí o sì tó bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá láti inú ilé ọlẹ̀, mo sọ ọ́ di mímọ́.+ Wòlíì fún orílẹ̀-èdè ni mo fi ọ́ ṣe.”  Ṣùgbọ́n mo wí pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ,+ nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.”+  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: “Má ṣe wí pé, ‘ọmọdé lásán ni mí.’ Ṣùgbọ́n ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí èmi yóò rán ọ lọ ni kí o lọ; ohun gbogbo tí mo bá sì pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ.+  Má fòyà nítorí ojú wọn,+ nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè,’+ ni àsọjáde Jèhófà.”  Látàrí ìyẹn, Jèhófà na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú kí ó kan ẹnu mi.+ Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún mi pé: “Kíyè sí i, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ.+ 10  Wò ó, mo ti fàṣẹ yàn ọ́ lónìí lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti lórí àwọn ìjọba,+ láti fà tu àti láti bì wó àti láti pa run àti láti ya lulẹ̀,+ láti kọ́ àti láti gbìn.”+ 11  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: “Jeremáyà, kí ni ìwọ rí?” Nítorí náà, mo wí pé: “Èéhù igi álímọ́ńdì ni mo rí.” 12  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: “Ohun tí ó dára ni o rí, nítorí mo wà lójúfò nípa ọ̀rọ̀ mi láti mú un ṣẹ.”+ 13  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá ní ìgbà kejì, pé: “Kí ni ìwọ rí?” Nítorí náà, mo wí pé: “Ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀ tí a ń fẹ́ atẹ́gùn sí ni mo rí, ẹnu rẹ̀ sì wà níhà àríwá.” 14  Látàrí èyí, Jèhófà wí fún mi pé: “Láti àríwá ni a ó ti tú ìyọnu àjálù sára gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà.+ 15  Nítorí ‘kíyè sí i, mo ń ké sí gbogbo ìdílé àwọn ìjọba àríwá,’ ni àsọjáde Jèhófà;+ ‘wọn yóò sì wá dájúdájú, olúkúlùkù wọn yóò sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ sí ibi àtiwọ àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù,+ wọn yóò sì gbé e ti gbogbo ògiri rẹ̀ yí ká àti ti gbogbo ìlú ńlá Júdà.+ 16  Èmi yóò sì sọ̀rọ̀ àwọn ìdájọ́ mi sí wọn nítorí gbogbo ìwà búburú wọn,+ ní ti pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn,+ wọ́n sì ń tẹrí ba fún iṣẹ́ ọwọ́ wọn.’+ 17  “Ní ti ìwọ, kí o di ìgbáròkó rẹ lámùrè,+ kí o dìde, kí o sì bá wọn sọ ohun gbogbo tí èmi fúnra mi yóò pa láṣẹ fún ọ. Má ṣe jẹ́ kí ìpayà èyíkéyìí bá ọ nítorí wọn,+ kí èmi má bàa kó ìpayà bá ọ níwájú wọn. 18  Ṣùgbọ́n, ní tèmi, kíyè sí i, lónìí, mo ti sọ ìwọ di ìlú ńlá olódi àti ọwọ̀n irin àti ògiri bàbà+ lòdì sí gbogbo ilẹ̀ náà,+ sí àwọn ọba Júdà, sí àwọn ọmọ aládé rẹ̀, sí àwọn àlùfáà rẹ̀ àti sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.+ 19  Ó sì dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ,+ nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé