Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Júúdà 1:1-25

 Júúdà, ẹrú Jésù Kristi, ṣùgbọ́n arákùnrin Jákọ́bù,+ sí àwọn tí a pè,+ tí a nífẹ̀ẹ́ nínú ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run Baba,+ tí a sì pa mọ́+ fún Jésù Kristi:  Kí àánú+ àti àlàáfíà+ àti ìfẹ́+ pọ̀ sí i fún yín.+  Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n,+ bí mo tilẹ̀ ti ń ṣe ìsapá gbogbo láti kọ̀wé sí yín nípa ìgbàlà tí gbogbo wa jọ dì mú,+ mo rí i pé ó pọndandan láti kọ̀wé sí yín láti gbà yín níyànjú láti máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́+ tí a fi lé àwọn ẹni mímọ́+ lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.  Ìdí tí mo ní ni pé àwọn ènìyàn kan ti yọ́ wọlé,+ àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti yàn kalẹ̀+ láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn fún ìdájọ́+ yìí, àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run,+ tí wọ́n ń sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu,+ tí wọ́n sì já sí èké+ sí Ẹnì kan ṣoṣo tí ó ni wá,+ tí ó sì jẹ́ Olúwa,+ Jésù Kristi.  Láìka mímọ̀ tí ẹ mọ ohun gbogbo yanjú sí,+ mo fẹ́ láti rán yín létí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gba àwọn ènìyàn kan là kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ lẹ́yìn ìgbà náà, ó pa àwọn tí kò fi ìgbàgbọ́ hàn run.+  Àwọn áńgẹ́lì tí kò sì dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣá ibi gbígbé+ tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì ni òun ti fi pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá+ náà pẹ̀lú àwọn ìdè+ ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.  Bẹ́ẹ̀ náà ni Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ìlú ńlá tí ó yí wọn ká,+ lẹ́yìn tí àwọn, lọ́nà kan náà bí ti àwọn tí a mẹ́nu kàn ṣáájú, ti ṣe àgbèrè lọ́nà tí ó pọ̀ lápọ̀jù, tí wọ́n sì ti jáde tọ ẹran ara lẹ́yìn fún ìlò tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá,+ a gbé wọn ka iwájú wa gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ akini-nílọ̀+ nípa fífaragba ìyà ìdájọ́ iná àìnípẹ̀kun.+  Láìka èyíinì sí, lọ́nà kan náà, àwọn ènìyàn wọ̀nyí pẹ̀lú, ní fífi àwọn àlá+ kẹ́ra bàjẹ́, ń sọ ẹran ara di ẹlẹ́gbin, wọ́n sì ń ṣàìka ipò olúwa sí,+ wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo+ tèébútèébú.  Ṣùgbọ́n nígbà tí Máíkẹ́lì+ olú-áńgẹ́lì+ ní aáwọ̀ pẹ̀lú Èṣù, tí ó sì ń ṣe awuyewuye+ nípa òkú Mósè,+ kò gbójúgbóyà láti mú ìdájọ́ wá lòdì sí i ní àwọn ọ̀rọ̀ èébú,+ ṣùgbọ́n ó wí pé: “Kí Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná.”+ 10  Síbẹ̀, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ̀rọ̀ tèébútèébú nípa gbogbo ohun tí wọn kò mọ̀ ní ti gidi;+ ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí wọ́n lóye lọ́nà ti ẹ̀dá bí àwọn ẹran tí kì í ronú,+ nínú nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ń bá a lọ ní sísọ ara wọn di ìbàjẹ́.+ 11  Ó mà ṣe fún wọn o, nítorí wọ́n ti lọ ní ipa ọ̀nà Kéènì,+ wọ́n sì ti rọ́ wọnú ipa ọ̀nà ìṣìnà Báláámù+ fún èrè, wọ́n sì ti ṣègbé nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀+ Kórà!+ 12  Àwọn wọ̀nyí ni àpáta tí ó fara sin lábẹ́ omi nínú àwọn àsè ìfẹ́+ yín nígbà tí wọ́n ń jẹ àsè pẹ̀lú yín, àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń bọ́ ara wọn láìsí ìbẹ̀rù;+ àwọsánmà aláìlómi tí ẹ̀fúùfù ń gbá+ síhìn-ín sọ́hùn-ún;+ àwọn igi ní apá ìgbẹ̀yìn ìgbà ìkórè, ṣùgbọ́n tí kò ní èso, níwọ̀n bí wọ́n ti kú lẹ́ẹ̀mejì, níwọ̀n bí a ti hú wọn tegbòtegbò;+ 13  àwọn ìgbì òkun líle tí ń ru ìfóófòó àwọn okùnfà ìtìjú tiwọn sókè;+ àwọn ìràwọ̀ tí kò ní ipa ọ̀nà tí a là sílẹ̀, àwọn tí a fi ìdúdú òkùnkùn pa mọ́ dè títí láé.+ 14  Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnì keje nínú ìlà láti ọ̀dọ̀ Ádámù, Énọ́kù,+ sọ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú nípa wọn, nígbà tí ó wí pé: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́,+ 15  láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn,+ àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.”+ 16  Àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ oníkùnsínú,+ àwọn olùráhùn nípa ìpín wọn nínú ìgbésí ayé, wọ́n ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn,+ ẹnu wọ́n sì ń sọ ohun kàǹkà-kàǹkà,+ nígbà tí wọ́n ń kan sáárá sí àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn+ nítorí àǹfààní ti ara wọn. 17  Ní tiyín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ rántí àwọn àsọjáde tí àwọn àpọ́sítélì Olúwa wa Jésù Kristi+ ti sọ ní ìṣáájú, 18  bí wọ́n ti máa ń wí fún yín pé: “Ní àkókò ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wà, tí yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, fún àwọn ohun tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.”+ 19  Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀,+ àwọn ènìyàn oníwà-bí-ẹranko,+ aláìní ìfẹ́ ohun ti ẹ̀mí.+ 20  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, nípa gbígbé ara yín ró+ lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ,+ àti gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́,+ 21  ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run,+ bí ẹ ti ń dúró de àánú+ Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.+ 22  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ máa bá a lọ ní fífi àánú hàn+ fún àwọn kan tí wọ́n ní iyèméjì;+ 23  ẹ gbà wọ́n là+ nípa jíjá wọn gbà kúrò nínú iná.+ Ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní fífi àánú hàn fún àwọn ẹlòmíràn, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ní àkókò kan náà kí ẹ kórìíra ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí ara ti kó àbààwọ́n bá.+ 24  Wàyí o, ẹni tí ó lè ṣọ́+ yín kúrò nínú kíkọsẹ̀, tí ó sì lè mú yín dúró láìní àbààwọ́n+ níwájú ògo rẹ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà, 25  Ọlọ́run kan ṣoṣo tí ó jẹ́ Olùgbàlà+ wa nípasẹ̀ Jésù Kristi+ Olúwa wa, ni kí ògo,+ ọlá ọba, agbára ńlá+ àti ọlá àṣẹ+ jẹ́ tirẹ̀ fún gbogbo ayérayé+ tí ó ti kọjá àti nísinsìnyí àti títí lọ dé gbogbo ayérayé.+ Àmín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé