Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jónà 4:1-11

4  Bí ó ti wù kí ó rí, kò dùn mọ́ Jónà nínú+ rárá, inú rẹ̀ sì ru fún ìbínú.  Nítorí náà, ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì wí pé: “Áà, nísinsìnyí, Jèhófà, ohun tí mo ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ ha kọ́ ni èyí, nígbà tí mo wà lórí ilẹ̀ mi? Ìdí nìyẹn tí mo fi lọ ní ìṣáájú, tí mo sì fẹsẹ̀ fẹ lọ sí Táṣíṣì;+ nítorí mo mọ̀ pé ìwọ jẹ́ Ọlọ́run olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú,+ tí ó ń lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́,+ tí ń pèrò dà lórí ìyọnu àjálù.+  Wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́, gba ọkàn+ mi kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí, kí n kú sàn ju kí n wà láàyè.”+  Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà sọ pé: “Ǹjẹ́ ríru tí inú rẹ ru fún ìbínú ha jẹ́ lọ́nà ẹ̀tọ́ bí?”+  Nígbà náà ni Jónà jáde kúrò ní ìlú ńlá náà, ó sì jókòó ní ìlà-oòrùn ìlú ńlá náà; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ṣe àtíbàbà kan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, kí ó bàa lè jókòó sábẹ́ rẹ̀ nínú ibòji+ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú ńlá+ náà.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà Ọlọ́run ṣètò ewéko akèrègbè kan, pé kí ó gòkè wá bo Jónà, kí ó bàa lè di ibòji lórí rẹ̀, láti dá a nídè kúrò nínú ipò oníyọnu àjálù rẹ̀.+ Jónà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ gidigidi nítorí ewéko akèrègbè náà.  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tòótọ́ ṣètò kòkòrò mùkúlú+ kan nígbà tí ọ̀yẹ̀ là ní ọjọ́ kejì, pé kí ó kọlu ewéko akèrègbè náà; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó gbẹ.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí oòrùn ràn, Ọlọ́run tún ń bá a lọ láti ṣètò ẹ̀fúùfù+ ìlà-oòrùn amóhungbẹ hán-ún hán-ún, oòrùn sì ń pa Jónà lórí ṣáá, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ń dákú lọ;+ ó sì ń bá a nìṣó láti béèrè pé kí ọkàn òun kú, ó sì ń sọ léraléra pé: “Kí n kú dànù sàn ju kí n wà láàyè.”+  Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún Jónà pé: “Ǹjẹ́ ríru tí inú rẹ ru fún ìbínú nítorí ewéko akèrègbè náà ha jẹ́ lọ́nà ẹ̀tọ́ bí?”+ Látàrí ìyẹn, ó wí pé: “Ríru tí inú mi ru fún ìbínú jẹ́ lọ́nà ẹ̀tọ́, títí dé ojú ikú.” 10  Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ pé: “Ìwọ, ní tìrẹ, káàánú fún ewéko akèrègbè náà, èyí tí ìwọ kò ṣe làálàá lé lórí tàbí mú kí ó tóbi, èyí tí ó jẹ́ èéhù lásán tí ó hù ní òru kan, tí ó sì ṣègbé gẹ́gẹ́ bí èéhù lásán tí ó hù ní òru kan. 11  Ní tèmi, kò ha sì yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá+ títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà, tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn, yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹran agbéléjẹ̀?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé