Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jónà 3:1-10

3  Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jónà wá nígbà kejì, pé:+  “Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí fún un nípa ìpòkìkí+ tí èmi yóò sọ fún ọ.”  Látàrí ìyẹn, Jónà dìde, ó sì lọ sí Nínéfè ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ Wàyí o, Nínéfè jẹ́ ìlú ńlá tí ó tóbi lójú Ọlọ́run,+ tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹ́ta.  Níkẹyìn, Jónà bẹ̀rẹ̀ sí wọnú ìlú ńlá náà ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń pòkìkí, ó sì ń wí pé: “Kìkì ogójì ọjọ́ sí i, a ó sì bi Nínéfè ṣubú.”+  Àwọn ènìyàn Nínéfè sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,+ wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pòkìkí ààwẹ̀, wọ́n sì gbé aṣọ àpò ìdọ̀họ+ wọ̀, láti orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn àní dórí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn.  Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dé ọ̀dọ̀ ọba Nínéfè,+ nígbà náà ni ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ ẹ̀wù oyè rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bo ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.+  Síwájú sí i, ó mú kí a ṣe ìkéde náà, ó sì mú kí a sọ ọ́ ní Nínéfè, nípa àṣẹ àgbékalẹ̀ ọba àti àwọn ẹni ńlá rẹ̀, pé: “Kò sí ènìyàn, kò sì sí ẹran agbéléjẹ̀, kò sí ọ̀wọ́ ẹran, kò sì sí agbo ẹran kankan, tí ó gbọ́dọ̀ tọ́ ohunkóhun wò rárá. Kò sí ìkankan tí ó gbọ́dọ̀ jẹun. Wọn kò gbọ́dọ̀ mu+ omi pàápàá.  Kí wọ́n sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bo ara wọn, ènìyàn àti ẹran agbéléjẹ̀; kí wọ́n sì fi tokun-tokun ké pe Ọlọ́run, kí wọ́n sì padà, olúkúlùkù kúrò+ nínú ọ̀nà búburú rẹ̀ àti kúrò nínú ìwà ipá tí ó wà ní ọwọ́ wọn.  Ta ní mọ̀ bóyá Ọlọ́run tòótọ́ lè yí padà, kí ó sì pèrò dà+ ní ti tòótọ́, kí ó sì yí padà kúrò nínú ìbínú rẹ̀ jíjófòfò, kí a má bàa ṣègbé?”+ 10  Ọlọ́run tòótọ́ sì wá rí àwọn iṣẹ́+ wọn, pé wọ́n ti yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn;+ nítorí náà, Ọlọ́run tòótọ́ pèrò dà+ lórí ìyọnu àjálù tí ó ti sọ pé òun yóò mú bá wọn; kò sì mú un wá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé