Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jónà 2:1-10

2  Nígbà náà ni Jónà gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja+ náà,  ó sì wí pé: “Láti inú wàhálà mi ni mo ti ké pe Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn.+ Láti inú ikùn Ṣìọ́ọ̀lù ni mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́.+ Ìwọ gbọ́ ohùn mi.+  Nígbà tí ìwọ sọ mi sí ibú, sí àárín òkun gbalasa,+ Nígbà náà, àní odò kan yí mi ká. Gbogbo ìrugùdù omi rẹ tí ń fọ́n ká di ìfóófòó àti àwọn ìgbì rẹ—wọ́n kọjá lórí mi.+  Àti ní tèmi, mo sọ pé, ‘A ti lé mi kúrò níwájú rẹ!+ Báwo ni èmi yóò ṣe tún lè tẹjú mọ́ tẹ́ńpìlì+ mímọ́ rẹ?’  Omi ká mi mọ́ títí lọ dé ọkàn;+ ibú omi ń bá a nìṣó ní kíká mi mọ́ yí ká. A fi èpò wé mi ní orí.  Mo sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá. Ní ti ilẹ̀ ayé, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ wà lórí mi fún àkókò tí ó lọ kánrin. Ṣùgbọ́n o tẹ̀ síwájú láti mú ìwàláàyè mi gòkè wá láti inú kòtò, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi.+  Nígbà tí àárẹ̀ mú ọkàn mi nínú mi,+ Jèhófà ni Ẹni tí mo rántí.+ Nígbà náà ni àdúrà mi wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ, sínú tẹ́ńpìlì+ mímọ́ rẹ.  Ní ti àwọn tí ń ṣàkíyèsí àwọn òrìṣà àìjóòótọ́, wọ́n fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ ti ara wọn sílẹ̀.  Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò fi ohùn ìdúpẹ́ rúbọ sí ọ.+ Èmi yóò san+ ohun ti mo jẹ́jẹ̀ẹ́. Ti Jèhófà ni ìgbàlà.”+ 10  Nígbà tí ó ṣe, Jèhófà pàṣẹ fún ẹja náà, bẹ́ẹ̀ ni ó pọ Jónà sórí ilẹ̀ gbígbẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé