Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jónà 1:1-17

1  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ Jónà+ ọmọkùnrin Ámítáì wá, pé:  “Dìde, lọ sí Nínéfè+ ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí lòdì sí i pé ìwà búburú wọn ti gòkè wá síwájú mi.”+  Jónà sì dìde, ó sì fẹsẹ̀ fẹ lọ sí Táṣíṣì+ kúrò níwájú Jèhófà;+ níkẹyìn, ó sọ̀ kalẹ̀ wá sí Jópà,+ ó sì rí ọkọ̀ òkun kan tí ń lọ sí Táṣíṣì. Nítorí náà, ó san owó ọkọ̀, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú rẹ̀, kí ó bàa lè bá wọn lọ sí Táṣíṣì kúrò níwájú Jèhófà.  Jèhófà fúnra rẹ̀ sì rán ẹ̀fúùfù ńláǹlà jáde sí òkun,+ ìjì líle+ ńláǹlà sì wá wà lórí òkun; àti ní ti ọkọ̀ òkun náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́.  Àwọn atukọ̀ òkun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù, wọ́n sì ń ké fún ìrànlọ́wọ́, olúkúlùkù sí ọlọ́run rẹ̀.+ Wọ́n sì ń kó àwọn ohun èlò tí ó wà nínú ọkọ̀ òkun náà dà sínú òkun, kí wọ́n lè tipasẹ̀ ìwọ̀nyí mú un fúyẹ́.+ Ṣùgbọ́n Jónà alára ti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ìhà inú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún nínú ọkọ̀ òkun alájà òkè náà, ó sì dùbúlẹ̀, ó sì sùn lọ fọnfọn.+  Níkẹyìn, ọ̀gákọ̀ náà sún mọ́ ọn, ó sì wí fún un pé: “Kí ní ṣe ọ́, olóorun? Dìde, ké pe ọlọ́run+ rẹ! Bóyá Ọlọ́run tòótọ́ yóò fi ara rẹ̀ hàn pé òun bìkítà nípa wa, a kì yóò sì ṣègbé.”+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a ṣẹ́ kèké,+ kí a lè mọ ta ni ó fà á tí ìyọnu àjálù+ yìí fi dé bá wa.” Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣẹ́ kèké, níkẹyìn, kèké mú Jónà.+  Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún wa, ta ni ó fà á tí ìyọnu àjálù+ yìí fi dé bá wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ, ibo ni o sì ti wá? Ibo ni ilẹ̀ rẹ, ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wo ni ìwọ sì ti wá?”  Látàrí ìyẹn, ó wí fún wọn pé: “Hébérù+ ni mí, Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run+ sì ni mo ń bẹ̀rù,+ Ẹni tí ó dá òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ.”+ 10  Àwọn ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù gidigidi, wọ́n sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Kí ni ohun tí ìwọ ṣe yìí?”+ Nítorí àwọn ọkùnrin náà ti wá mọ̀ pé ṣe ni ó ń fẹsẹ̀ fẹ kúrò níwájú Jèhófà, nítorí ó ti sọ fún wọn. 11  Níkẹyìn, wọ́n wí fún un pé: “Kí ni kí a ṣe sí ọ,+ kí òkun bàa lè pa rọ́rọ́ fún wa?” Nítorí pé òkun náà túbọ̀ ń di oníjì líle. 12  Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì jù mí sínú òkun, òkun yóò sì pa rọ́rọ́ fún yín; nítorí mo mọ̀ pé èmi ni ó fà á tí ìjì líle ńláǹlà yìí fi dé bá yín.”+ 13  Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú láti wá ọ̀nà wọn kọjá, kí wọ́n bàa lè mú kí ọkọ̀ òkun náà padà wá sórí ilẹ̀ gbígbẹ; síbẹ̀, wọn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé òkun náà túbọ̀ ń di oníjì líle lòdì sí wọn.+ 14  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà, wọ́n sì wí pé:+ “Áà, nísinsìnyí, ìwọ Jèhófà, jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí a ṣègbé nítorí ọkàn ọkùnrin yìí! Má sì ka ẹ̀jẹ̀+ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sí wa lọ́rùn, níwọ̀n bí ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà, ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwọ ní inú dídùn sí!”+ 15  Nígbà náà ni wọ́n gbé Jónà, wọ́n sì jù ú sínú òkun; òkun sì bẹ̀rẹ̀ sí dáwọ́ ìhónú+ rẹ̀ dúró. 16  Látàrí ìyẹn, àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà gidigidi,+ nítorí náà, wọ́n rú ẹbọ sí Jèhófà,+ wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.+ 17  Wàyí o, Jèhófà ṣètò ẹja ńlá kan láti gbé Jónà+ mì, bẹ́ẹ̀ ni Jónà wá wà ní ìhà inú ẹja náà fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé