Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóṣúà 9:1-27

9  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí gbogbo àwọn ọba+ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá àti ní Ṣẹ́fẹ́là àti ní gbogbo etíkun Òkun Ńlá+ àti ní iwájú Lẹ́bánónì,+ àwọn ọmọ Hétì+ àti àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì+ àti àwọn Pérísì,+ àwọn Híf ì àti àwọn ará Jébúsì,+ gbọ́ nípa rẹ̀,  wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pe ara wọn jọpọ̀ láti bá Jóṣúà àti Ísírẹ́lì jagun ní ìf ìmọ̀ṣọ̀kan.+  Àwọn olùgbé Gíbéónì+ sì gbọ́ ohun tí Jóṣúà ṣe sí Jẹ́ríkò+ àti Áì.+  Nítorí náà, àwọn, àní láti inú ìdánúṣe wọn, gbé ìgbésẹ̀ ìfọgbọ́nhùwà,+ wọ́n lọ, wọ́n sì di àwọn ìpèsè oúnjẹ dání, wọ́n sì kó àwọn àpò ìdọ̀họ tí ó ti gbó sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, àti ògbólógbòó ìgò awọ wáìnì, tí ó sì ti bẹ́, tí a sì so,+  àti sálúbàtà tí ó ti gbó tí a sì ti lẹ̀ ní ẹsẹ̀ wọn, àti ẹ̀wù tí ó ti gbó lára wọn, gbogbo búrẹ́dì ìpèsè oúnjẹ wọn ti gbẹ, ó sì ti rún.  Nígbà náà ni wọ́n lọ sọ́dọ̀ Jóṣúà ní ibùdó ní Gílígálì,+ wọ́n sì wí fún òun àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì pé: “Láti ilẹ̀ jíj ì nnà ni àwa ti wá. Wàyí o, ẹ bá wa dá májẹ̀mú.”+  Látàrí èyí, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì wí fún àwọn Híf ì+ pé: “Bóyá tòsí wa ni o ń gbé. Nítorí náà, báwo ni a ṣe lè bá ọ dá májẹ̀mú?”+  Ẹ̀wẹ̀, wọ́n wí fún Jóṣúà pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́.”+ Nígbà náà ni Jóṣúà wí fún wọn pé: “Ta ni yín, ibo sì ni ẹ ti wá?”  Látàrí èyí, wọ́n wí fún un pé: “Láti ilẹ̀+ jíj ì nnàréré ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti wá ní tìtorí orúkọ+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ṣe ní Íjíbítì,+ 10  àti gbogbo ohun tí ó ṣe sí àwọn ọba méj ì ti àwọn Ámórì tí wọ́n wà ní ìhà kej ì Jọ́dánì, èyíinì ni, Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì àti Ógù+ ọba Báṣánì, tí ó wà ní Áṣítárótì.+ 11  Nítorí èyí, àwọn àgbà ọkùnrin àti gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ wa sọ báyìí fún wa pé,+ ‘Ẹ mú ìpèsè oúnjẹ ní ọwọ́ yín fún ìrìn àjò kí ẹ sì lọ pàdé wọn, kí ẹ sì wí fún wọn pé: “Ìránṣẹ́ yín ni àwa jẹ́.+ Wàyí o, ẹ bá wa dá májẹ̀mú.” ’+ 12  Búrẹ́dì wa yìí, gbígbóná ni nígbà tí a mú un jáde gẹ́gẹ́ bí ìpèsè oúnjẹ wa láti ilé wa ní ọjọ́ tí a jáde láti wá síhìn-⁠ín lọ́dọ̀ yín, wàyí o, sì wò ó! ó ti gbẹ, ó sì ti rún.+ 13  Ìwọ̀nyí sì ni ìgò awọ wáìnì tí a rọ kún ní tuntun, sì wò ó! wọ́n ti bẹ́,+ àti àwọn ẹ̀wù àti sálúbàtà wa wọ̀nyí, wọ́n ti gbó nítorí bí ìrìn àjò náà ti j ì nnà gan-⁠an tó.” 14  Látàrí ìyẹn, àwọn ènìyàn náà gbà lára ìpèsè oúnjẹ wọn, wọn kò sì wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà. 15  Jóṣúà sì wá àlàáfí à pẹ̀lú wọn,+ ó sì bá wọn dá májẹ̀mú láti jẹ́ kí wọ́n wà láàyè, àwọn ìjòyè+ àpéjọ náà sì búra fún wọn.+ 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ní òpin ọjọ́ mẹ́ta, lẹ́yìn tí wọ́n ti bá wọn dá májẹ̀mú, wọ́n wá gbọ́ pé wọ́n sún mọ́ wọn àti pé ní tòsí wọn ni wọ́n ń gbé. 17  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣí, wọ́n sì wá dé àwọn ìlú ńlá wọn ní ọjọ́ kẹta, àwọn ìlú ńlá wọn sì ni Gíbéónì+ àti Kéfírà+ àti Béérótì+ àti Kiriati-jéárímù.+ 18  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sì kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn ìjòyè àpéjọ ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ búra+ fún wọn. Gbogbo àpéjọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí àwọn ìjòyè náà.+ 19  Látàrí èyí, gbogbo àwọn ìjòyè náà wí fún gbogbo àpéjọ náà pé: “Ní tiwa, àwa ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún wọn, wàyí o, a kò yọ̀ǹda fún wa láti ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́.+ 20  Èyí ni ohun tí àwa yóò ṣe sí wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a óò dá ìwàláàyè wọn sí, kí ìkannú kankan má bàa wá sórí wa nítorí ìbúra tí a búra fún wọn.”+ 21  Nítorí náà, àwọn ìjòyè náà wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí wọ́n wà láàyè, kí ẹ sì jẹ́ kí wọ́n di aṣẹ́gi àti apọnmi fún gbogbo àpéjọ,+ gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí àwọn ìjòyè ti ṣèlérí fún wọn.”+ 22  Wàyí o, Jóṣúà pè wọ́n, ó sì sọ fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ṣe àgálámàṣà sí wa, pé, ‘A wà ní ibi jíj ì nnàréré gan-⁠an sí yín,’+ nígbà tí ó jẹ́ pé àárín wa gan-⁠an ni ẹ ń gbé?+ 23  Wàyí o, ẹni ègún ni yín,+ ipò+ ẹrú àti aṣẹ́gi àti apọnmi fún ilé Ọlọ́run mi ni a kì yóò ké kúrò lọ́dọ̀ yín láé.”+ 24  Nígbà náà ni wọ́n dá Jóṣúà lóhùn pé: “Nítorí pé àwa ìránṣẹ́ rẹ ni a sọ fún ní kedere pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fi gbogbo ilẹ̀ náà fún yín àti láti pa gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà rẹ́ ráúráú kúrò níwájú yín,+ àyà sì fò wá gidigidi fún ọkàn wa nítorí yín.+ Nítorí bẹ́ẹ̀ ni a fi ṣe nǹkan yìí.+ 25  Wàyí o, àwa rèé ní ọwọ́ rẹ. Bí ó bá ṣe dára ní ojú rẹ láti ṣe sí wa ni kí o ṣe.”+ 26  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn, ó sì dá wọn nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn kò sì pa wọ́n.+ 27  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ní ọjọ́ yẹn, Jóṣúà sọ wọ́n di+ aṣẹ́gi àti apọnmi fún àpéjọ+ náà àti fún pẹpẹ Jèhófà, títí di òní yìí, ní ibi tí ó bá yàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé