Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 8:1-35

8  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Jóṣúà pé: “Má fòyà tàbí kí o jáyà.+ Mú gbogbo ènìyàn ogun pẹ̀lú rẹ, kí o sì dìde, gòkè lọ sí Áì. Wò ó, èmi ti fi ọba Áì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ àti ìlú ńlá rẹ̀ àti ilẹ̀+ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.  Kí ìwọ sì ṣe sí Áì àti ọba rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Jẹ́ríkò àti ọba+ rẹ̀. K ì kì pé ohun ìfiṣèjẹ rẹ̀ àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀ ni ẹ lè piyẹ́ fún ara yín.+ Dẹ ibùba rẹ de ìlú ńlá náà ní ìhà ẹ̀yìn rẹ̀.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jóṣúà àti gbogbo ènìyàn ogun+ náà dìde láti gòkè lọ sí Áì, Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí yan ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ọkùnrin, àwọn akíkanjú alágbára ńlá,+ ó sì rán wọn lọ ní òru.  Ó sì ń bá a lọ láti pàṣẹ fún wọn pé: “Wò ó, ẹ ó ba ní ibùba+ de ìlú ńlá náà ní ìhà ẹ̀yìn ìlú ńlá náà. Ẹ má lọ j ì nnà réré jù sí ìlú ńlá náà, kí gbogbo yín sì wà ní ìmúratán.  Ní tèmi àti gbogbo ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú mi, àwa yóò sún mọ́ ìlú ńlá náà. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n bá jáde wá pàdé wa gan-an gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àkọ́kọ́,+ nígbà náà, kí a sá níwájú wọn.  Wọn yóò sì jáde tọ̀ wá lẹ́yìn títí àwa yóò fi fà wọ́n lọ kúrò ní ìlú ńlá náà, nítorí wọn yóò wí pé, ‘Wọ́n ń sá níwájú wa, gan-an gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àkọ́kọ́.’+ Àwa yóò sì sá níwájú wọn.  Lẹ́yìn náà ni ẹ̀yin—ẹ̀yin yóò dìde ní ibùba, ẹ ó sì gba ìlú ńlá náà; Jèhófà Ọlọ́run yín yóò sì fi í lé yín lọ́wọ́.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú ńlá náà, kí ẹ dáná ran+ ìlú ńlá náà. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà ni kí ẹ ṣe. Wò ó, èmi ti pàṣẹ fún yín.”+  Lẹ́yìn ìyẹn, Jóṣúà rán wọn jáde, wọ́n sì lọ sí ibùba náà, wọ́n sì pa ibùdó sáàárín Bẹ́tẹ́lì àti Áì, sí ìwọ̀-oòrùn Áì, ṣùgbọ́n Jóṣúà wọ̀ sí àárín àwọn ènìyàn náà ní òru yẹn. 10  Nígbà náà ni Jóṣúà dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀,+ ó sì ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ènìyàn náà, òun àti àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sì gòkè lọ sí Áì, níwájú àwọn ènìyàn náà. 11  Gbogbo ènìyàn ogun+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì gòkè lọ, kí wọ́n lè sún mọ́ ìlú ńlá náà, kí wọ́n sì dé iwájú rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dó sí àríwá Áì, àfonífoj ì  sì wà láàárín àwọn àti Áì. 12  Láàárín àkókò náà, ó mú nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin, ó sì fi wọ́n sí ibùba+ láàárín Bẹ́tẹ́lì+ àti Áì, sí ìwọ̀-oòrùn ìlú ńlá náà. 13  Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ènìyàn náà pa ibùdó tí í ṣe lájorí, tí ó wà ní àríwá ìlú ńlá+ náà, àti apá ẹ̀yìn rẹ̀ pátápátá tí ó wà níhà ìwọ̀-oòrùn ìlú ńlá+ náà, Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ ní òru yẹn sí àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ náà. 14  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọba Áì rí èyí, àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà ṣe wéré, wọ́n sì dìde ní kùtùkùtù, wọ́n sì jáde lọ láti pàdé Ísírẹ́lì nínú ìjà ogun, òun àti gbogbo ènìyàn rẹ̀, ní àkókò tí a yàn kalẹ̀, níwájú pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀. Ní tirẹ̀, kò mọ̀ pé àwọn abadeni ba de òun ní ìhà ẹ̀yìn ìlú ńlá+ náà. 15  Nígbà tí ìyọnu àgbálù bá Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì níwájú wọn,+ wọ́n wá fẹsẹ̀ fẹ gba ọ̀nà aginjù.+ 16  Látàrí ìyẹn, a pe gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú ìlú ńlá náà jáde láti lépa wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa Jóṣúà, a sì fà wọ́n lọ kúrò ní ìlú ńlá+ náà. 17  Kò sì sí ọkùnrin kan tí ó ṣẹ́ kù sí Áì àti Bẹ́tẹ́lì tí kò jáde tọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n fi ìlú ńlá náà sílẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu, wọ́n sì ń lépa Ísírẹ́lì. 18  Wàyí o, Jèhófà wí fún Jóṣúà pé: “Na ẹ̀ṣín tí ó wà ní ọwọ́ rẹ jáde síhà Áì,+ nítorí èmi yóò fi í lé ọ lọ́wọ́.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jóṣúà na ẹ̀ṣín tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ jáde síhà ìlú ńlá náà. 19  Àwọn abadeni náà sì dìde kúrò ní ipò wọn kíákíá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ ní gbàrà tí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wọnú ìlú ńlá náà lọ, wọ́n sì gbà á.+ Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe wéré, wọ́n sì dáná ran ìlú ńlá náà.+ 20  Àwọn ọkùnrin Áì sì bẹ̀rẹ̀ sí bojú wo ẹ̀yìn, sì kíyè sí i, èéfín ìlú ńlá náà gòkè lọ sí ojú ọ̀run, kò sì sí agbára láti ṣe nǹkan kan nínú wọn láti sá lọ síhìn-ín tàbí sọ́hùn-ún. Àwọn ènìyàn tí ń sá lọ sí aginjù sì yí padà láti gbéjà ko àwọn olùlépa náà. 21  Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì sì rí i pé àwọn abadeni+ ti gba ìlú ńlá náà, àti pé èéfín ìlú ńlá náà ti gòkè, nítorí náà, wọ́n yíjú padà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ọkùnrin Áì balẹ̀. 22  Àwọn yòókù sì jáde wá láti inú ìlú ńlá náà láti pàdé wọn, tí ó fi wá jẹ́ pé wọ́n wà láàárín Ísírẹ́lì, àwọn ti ìhà ìhín àti àwọn ti ìhà ọ̀hún, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá wọn balẹ̀ títí kò fi ṣẹ́ ku yála olùlàájá kan tàbí olùsálà+ kan lára wọn. 23  Wọ́n sì mú ọba+ Áì láàyè, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti mú un wá sọ́dọ̀ Jóṣúà. 24  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí Ísírẹ́lì ti ń parí pípa gbogbo olùgbé Áì ní pápá, nínú aginjù tí wọ́n ti lépa wọn, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọn ń ṣubú lójú idà títí wọ́n fi wá sí òpin wọn. Lẹ́yìn náà, gbogbo Ísírẹ́lì padà sí Áì, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú. 25  Gbogbo àwọn tí wọ́n sì ṣubú ní ọjọ́ yẹn, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọkùnrin dórí obìnrin, jẹ́ ẹgbẹ̀rún méj ì lá, gbogbo ènìyàn Áì pátá. 26  Jóṣúà kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn, èyí tí ó fi na ẹ̀ṣín+ jáde, títí ó fi ya gbogbo olùgbé Áì sọ́tọ̀ fún ìparun.+ 27  K ì kì àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àti ohun ìfiṣèjẹ ìlú ńlá yẹn ni Ísírẹ́lì piyẹ́ fún ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó ti gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ fún Jóṣúà.+ 28  Lẹ́yìn náà, Jóṣúà fi iná sun Áì, ó sì sọ ọ́ di òkìtì+ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, gẹ́gẹ́ bí ahoro títí di òní yìí. 29  Ó sì gbé ọba Áì+ kọ́ sórí òpó igi títí di ìgbà ìrọ̀lẹ́;+ bí oòrùn sì ti ń wọ̀ lọ, Jóṣúà pàṣẹ, nígbà náà ni wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀+ láti orí òpó igi, wọ́n sì gbé e jù sí àbáwọ ẹnubodè ìlú ńlá náà, wọ́n sì kó òkúta jọ pelemọ lé e lórí, títí di òní yìí. 30  Ìgbà yẹn ni Jóṣúà bẹ̀rẹ̀ sí mọ pẹpẹ+ kan fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní Òkè Ńlá Ébálì,+ 31  gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin+ Mósè pé: “Pẹpẹ àwọn odindi òkúta, lára èyí tí a kò lo irinṣẹ́ tí a fi irin ṣe”;+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rú ọrẹ ẹbọ sísun lórí rẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n sì ń rú àwọn ẹbọ+ ìdàpọ̀. 32  Lẹ́yìn náà, ó kọ ẹ̀dà+ òfin Mósè tí ó ti kọ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ sí ara àwọn òkúta náà níbẹ̀. 33  Gbogbo Ísírẹ́lì àti àwọn àgbà ọkùnrin+ wọn àti àwọn onípò àṣẹ àti àwọn onídàájọ́ wọn sì dúró ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún Àpótí, ní iwájú àwọn àlùfáà,+ àwọn ọmọ Léf ì, tí wọ́n ru àpótí májẹ̀mú Jèhófà,+ àwọn àtìpó títí kan àwọn ọmọ ìbílẹ̀,+ ìdaj ì  wọn ní iwájú Òkè Ńlá Gérísímù+ àti ìdaj ì  yòókù ní iwájú Òkè Ńlá Ébálì,+ (gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ti pàṣẹ,)+ láti súre+ fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lákọ̀ọ́kọ́ ná. 34  Àti lẹ́yìn èyí, ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ òfin,+ ìbùkún+ àti ìfiré+ náà sókè, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé òfin náà. 35  Kò sì sí ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo èyí tí Mósè pa láṣẹ tí Jóṣúà kò kà sókè ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì,+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin+ àti àwọn ọmọ kéékèèké+ àti àwọn àtìpó+ tí ń rìn ní àárín wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé