Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 7:1-26

7  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà àìṣòótọ́ nípa nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun, ní ti pé Ákáánì+ ọmọkùnrin Kámì, ọmọkùnrin Sábídì, ọmọkùnrin Síírà, ti ẹ̀yà Júdà, kó lára nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Látàrí èyí, ìbínú Jèhófà gbóná sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Nígbà náà ni Jóṣúà rán àwọn ọkùnrin jáde láti Jẹ́rìkò lọ sí Áì,+ tí ó wà nítòsí Bẹti-áfénì,+ ní ìlà-oòrùn Bẹ́tẹ́lì,+ ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì ṣe amí ilẹ̀ náà.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkùnrin náà gòkè lọ, wọ́n sì ṣe amí Áì.+  Lẹ́yìn náà, wọ́n padà sọ́dọ̀ Jóṣúà, wọ́n sì wí fún un pé: “Má ṣe jẹ́ kí gbogbo ènìyàn gòkè lọ. Jẹ́ kí nǹkan bí ẹgbàá ọkùnrin tàbí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkùnrin gòkè lọ kí wọ́n sì kọlu Áì. Má ṣe fi lílọ sí ibẹ̀ tán gbogbo àwọn ènìyàn náà lókun, nítorí wọ́n kéré níye.”  Nítorí náà, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkùnrin lára àwọn ènìyàn náà gòkè lọ sí ibẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fẹsẹ̀ fẹ níwájú àwọn ọkùnrin Áì.+  Àwọn ọkùnrin Áì sì ṣá àwọn ọkùnrin bí mẹ́rìndínlógój ì  lára wọn balẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa+ wọn lọ láti iwájú ẹnubodè títí dé Ṣébárímù, wọ́n sì ń bá a lọ láti máa ṣá wọn balẹ̀ níbi ìsọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, ọkàn-àyà àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí yọ́, ó sì di omi.+  Látàrí èyí, Jóṣúà fa aṣọ àlàbora rẹ̀ ya, ó sì dojú+ bolẹ̀ níwájú àpótí Jèhófà títí di ìrọ̀lẹ́, òun àti àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń da ekuru sí orí+ ara wọn.  Jóṣúà sì ń bá a lọ láti wí pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, èé ṣe tí o fi mú àwọn ènìyàn yìí láti ọ̀nà tí ó j ì n tó bẹ́ẹ̀ sọdá Jọ́dánì, kìkì láti fi wá lé ọwọ́ àwọn Ámórì, kí wọ́n lè pa wá run? Ká ní a sì ti mọ̀ fúnra wa ni, à bá sì ti máa bá a lọ láti máa gbé níhà kej ì  Jọ́dánì!+  Dákun, Jèhófà, ṣúgbọ̀n kí ni mo lè sọ lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì ti yí ẹ̀yìn rẹ̀ padà níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀?  Àwọn ọmọ Kénáánì àti gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò sì gbọ́ nípa rẹ̀, dájúdájú, wọn yóò sì wá yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò lórí ilẹ̀ ayé;+ kí ni ìwọ yóò sì ṣe fún orúkọ ńlá rẹ?”+ 10  Ní tirẹ̀, Jèhófà wí fún Jóṣúà pé: “Dìde, ìwọ! Èé ṣe tí o fi dojú bolẹ̀? 11  Ísírẹ́lì ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì ti tẹ májẹ̀mú+ mi lójú, èyí tí mo gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ lé wọn lórí; wọ́n sì ti kó lára nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun,+ wọ́n sì ti jalè,+ wọ́n sì ti pa á mọ́,+ wọ́n sì ti fi í sínú àwọn ohun èlò wọn.+ 12  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sì ní lè dìde sí àwọn ọ̀tá wọn.+ Wọn yóò yí ẹ̀yìn padà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, nítorí tí wọ́n ti di ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun. Èmi kò tún ní wà pẹ̀lú yín mọ́, àyàfi tí ẹ bá pa ohun náà tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun rẹ́ ráúráú kúrò ní àárín yín.+ 13  Dìde! Sọ àwọn ènìyàn náà di mímọ́,+ kí o sì wí pé, ‘Ẹ sọ ara yín di mímọ́ ní ọ̀la, nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ohun kan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun wà ní àárín rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì.+ Ìwọ kò ní lè dìde sí àwọn ọ̀tá rẹ títí ẹ ó fi mú nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun kúrò ní àárín yín. 14  Kí ẹ sì wá ní òwúrọ̀, ní ẹ̀yà, ẹ̀yà, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹ̀yà tí Jèhófà yóò mú,+ yóò sún mọ́ tòsí, ní ìdílé, ìdílé, ìdílé tí Jèhófà yóò sì mú, yóò sún mọ́ tòsí, ní agbo ilé, agbo ilé, agbo ilé tí Jèhófà yóò sì mú, yóò sún mọ́ tòsí, ní ọkùnrin abarapá, ọkùnrin abarapá. 15  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹni tí a bá mú pẹ̀lú nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun ni a ó fi iná+ sun, òun àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀, nítorí pé ó ti tẹ májẹ̀mú+ Jèhófà lójú àti nítorí pé ó ti hu ìwà ẹ̀gọ̀ tí ń dójú tini ní Ísírẹ́lì.” ’ ”+ 16  Jóṣúà wá dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì mú kí Ísírẹ́lì sún mọ́ tòsí, ní ẹ̀yà, ẹ̀yà rẹ̀, a sì mú ẹ̀yà Júdà. 17  Lẹ́yìn náà, ó mú kí àwọn ìdílé Júdà sún mọ́ tòsí, a sì mú ìdílé àwọn ọmọ Síírà,+ lẹ́yìn náà, ó mú kí ìdílé àwọn ọmọ Síírà sún mọ́ tòsí, ní ọkùnrin abarapá, ọkùnrin abarapá, a sì mú Sábídì. 18  Níkẹyìn, ó mú kí agbo ilé rẹ̀ sún mọ́ tòsí, ní ọkùnrin abarapá, ọkùnrin abarapá, a sì mú+ Ákáánì ọmọkùnrin Kámì, ọmọkùnrin Sábídí, ọmọkùnrin Síírà, ti ẹ̀yà Júdà. 19  Nígbà náà ni Jóṣúà wí fún Ákáánì pé: “Ọmọkùnrin mi, jọ̀wọ́, fi ògo fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ kí o sì jẹ́wọ́ fún un,+ kí o sì jọ̀wọ́, sọ fún mi,+ Kí ni o ṣe? Má ṣe fi í pa mọ́+ fún mi.” 20  Látàrí èyí, Ákáánì dá Jóṣúà lóhùn pé: “Ní tòótọ́, èmi—èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ báyìí-báyìí ni mo ṣe. 21  Nígbà tí mo rí+ ẹ̀wù oyè kan láti Ṣínárì+ láàárín àwọn ohun ìfiṣèjẹ, ọ̀kan tí ìrísí rẹ̀ dára, àti igba ṣékélì fàdákà àti wúrà gbọọrọ kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta ṣékélì, nígbà náà ni mo fẹ́ ní wọn,+ mo sì kó wọn;+ sì wò ó! a fi wọ́n pa mọ́ sínú ilẹ̀ ní àárín àgọ́ mi pẹ̀lú owó náà lábẹ́ rẹ̀.”+ 22  Ní kíá, Jóṣúà rán àwọn ońṣẹ́, wọ́n sì sáré lọ sínú àgọ́ náà, sì wò ó! a fi í pa mọ́ sínú àgọ́ rẹ̀ pẹ̀lú owó náà lábẹ́ rẹ̀. 23  Nítorí náà, wọ́n kó wọn kúrò ní àárín àgọ́ náà, wọ́n sì kó wọn wá sọ́dọ̀ Jóṣúà àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì dà wọ́n sílẹ̀ níwájú Jèhófà. 24  Jóṣúà, àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, wá mú Ákáánì+ ọmọkùnrin Síírà àti fàdákà náà àti ẹ̀wù oyè náà àti wúrà+ gbọọrọ náà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti agbo ẹran rẹ̀ àti àgọ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó jẹ́ tirẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Ákórì.+ 25  Nígbà náà ni Jóṣúà wí pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí wa?+ Jèhófà yóò mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí rẹ ní òní yìí.” Pẹ̀lú ìyẹn, gbogbo Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ́ ní òkúta,+ lẹ́yìn èyí, wọ́n fi iná sun+ wọ́n. Nípa báyìí, wọ́n sọ wọ́n lókùúta. 26  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó òkúta jọ pelemọ lé e lórí, títí di òní yìí.+ Látàrí èyí, Jèhófà yí padà kúrò nínú ìbínú gbígbóná+ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí a fi ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Ákórì,+ títí di òní yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé