Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóṣúà 6:1-27

6  Wàyí o, Jẹ́ríkò ni a tì pa gbọn-⁠in gbọn-⁠in nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí ẹnì kankan tí ń jáde, kò sì sí ẹnì kankan tí ń wọlé.+  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Jóṣúà pé: “Wò ó, mo ti fi Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀, àwọn akíkanjú ọkùnrin alágbára ńlá, lé ọ lọ́wọ́.+  Kí gbogbo ẹ̀yin ọkùnrin ogun sì yan yí ìlú ńlá náà ká, ní lílọ yí ìlú ńlá náà po lẹ́ẹ̀kan. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe fún ọjọ́ mẹ́fà.  Kí àwọn àlùfáà méje sì gbé ìwo àgbò méje, níwájú Àpótí náà, àti ní ọjọ́ keje kí ẹ yan yí ìlú ńlá náà ká ní ìgbà méje, kí àwọn àlùfáà sì fun àwọn ìwo náà.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n bá fun ìwo àgbò náà, nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo náà, kí gbogbo ènìyàn kígbe+ ogun ńlá; ògiri ìlú ńlá náà yóò sì wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ,+ kí àwọn ènìyàn náà sì gòkè lọ, olúkúlùkù tààràtà sí iwájú rẹ̀.”  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì pe àwọn àlùfáà+ náà, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ gbé àpótí májẹ̀mú+ náà nílẹ̀, kí àlùfáà méje sì gbé ìwo àgbò méje náà níwájú àpótí+ Jèhófà.”  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ kọjá, kí ẹ sì yan yí ìlú ńlá náà ká, kí àwùjọ+ tí ó ti gbára dì fún ogun sì kọjá ṣáájú àpótí Jèhófà.”  Ó sì ṣẹlẹ̀ gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Jóṣúà ti wí fún àwọn ènìyàn náà; àwọn àlùfáà méje tí wọ́n ń gbé ìwo àgbò méje níwájú Jèhófà sì kọjá, wọ́n sì fun ìwo náà, àpótí májẹ̀mú Jèhófà sì ń tẹ̀ lé wọn.  Àwùjọ tí ó ti gbára dì fún ogun sì ń lọ níwájú àwọn àlùfáà tí ń fun ìwo, nígbà tí ẹ̀ṣọ́+ ìhà ẹ̀yìn ń tẹ̀ lé Àpótí náà bí wọ́n ti ń fun àwọn ìwo náà láìdáwọ́ dúró. 10  Wàyí o, Jóṣúà ti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn+ náà pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ kígbe, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí a gbọ́ ohùn yín, ọ̀rọ̀ kankan kò sì gbọ́dọ̀ jáde wá láti ẹnu yín títí di ọjọ́ tí èmi bá wí fún yín pé, ‘Ẹ kígbe!’ Ìgbà náà ni kí ẹ kígbe.”+ 11  Ó sì mú kí a gbé àpótí Jèhófà yan yí ìlú ńlá náà ká, ní lílọ yí po lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn èyí, wọ́n lọ sí ibùdó, wọ́n sì wà ní ibùdó mọ́jú. 12  Lẹ́yìn náà, Jóṣúà dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀,+ àwọn àlùfáà náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ru àpótí Jèhófà, 13  àlùfáà méje tí wọ́n gbé ìwo àgbò méje níwájú àpótí+ Jèhófà sì ń rìn lọ, wọ́n ń fun ìwo náà láìdáwọ́ dúró, àwọn àwùjọ tí ó ti gbára dì fún ogun sì ń rìn lọ níwájú wọn, nígbà tí ẹ̀ṣọ́ ìhà ẹ̀yìn náà ń tẹ̀ lé àpótí Jèhófà bí wọ́n ti ń fun ìwo láìdáwọ́ dúró.+ 14  Wọ́n sì yan yí ìlú ńlá náà ká ni ọjọ́ kej ì lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn èyí, wọ́n padà sí ibùdó. Bí wọ́n ti ṣe nìyẹn fún ọjọ́ mẹ́fà.+ 15  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ keje pé, wọ́n dìde ní kùtùkùtù, ní kété tí ọ̀yẹ̀ là, wọ́n sì yan yí ìlú ńlá náà ká ní irú ọ̀nà yìí ní ìgbà méje. Ní ọjọ́ yẹn nìkan, wọ́n yan yí ìlú ńlá náà ká ní ìgbà méje.+ 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ìgbà keje pé àwọn àlùfáà fun ìwo, Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ kígbe;+ nítorí Jèhófà ti fi ìlú ńlá náà fún yín.+ 17  Ìlú ńlá náà yóò sì di ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun;+ òun, pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀ jẹ́ ti Jèhófà. K ì kì kárùwà náà, Ráhábù+ ni yóò máa wà láàyè nìṣó, òun àti gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilé, nítorí tí ó fi àwọn ońṣẹ́ tí a rán jáde pa mọ́.+ 18  Ẹ̀yin ní tiyín, kìkì pé kí ẹ yẹra fún àwọn nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun,+ kí ojú yín má bàa wọ̀ ọ́,+ kí ẹ sì kó lára àwọn nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun,+ kí ẹ sì sọ ibùdó Ísírẹ́lì di ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ sì mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí rẹ̀.+ 19  Ṣùgbọ́n gbogbo fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò bàbà àti irin jẹ́ ohun mímọ́ lójú Jèhófà.+ Inú ìṣúra Jèhófà ni kí ó lọ.”+ 20  Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà kígbe, nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fun ìwo.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ìró ìwo tí àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe ogun ńlá, nígbà náà ni ògiri náà bẹ̀rẹ̀ sí wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+ Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ènìyàn náà gòkè lọ sínú ìlú ńlá náà, olúkúlùkù tààràtà sí iwájú rẹ̀, wọ́n sì gba ìlú ńlá náà. 21  Wọ́n sì ń fi ojú idà ya gbogbo nǹkan tí ó wà nínú ìlú ńlá náà sọ́tọ̀ fún ìparun,+ láti orí ọkùnrin dórí obìnrin, láti orí ọ̀dọ́ dórí arúgbó àti dórí akọ màlúù àti àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 22  Àwọn ọkùnrin méj ì tí wọ́n ṣe amí ilẹ̀ náà ni Jóṣúà sì wí fún pé: “Ẹ wọnú ilé obìnrin náà lọ, kárùwà náà, kí ẹ sì mú obìnrin náà àti gbogbo ẹni tí ó jẹ́ tirẹ̀ jáde kúrò níbẹ̀, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti búra fún un.”+ 23  Nítorí náà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ṣe amí náà wọlé, wọ́n sì mú Ráhábù àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí ó jẹ́ tirẹ̀ jáde, bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ẹbí rẹ̀ ni wọ́n mú jáde;+ wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti fi wọ́n sí òde ibùdó Ísírẹ́lì. 24  Wọ́n sì fi iná sun ìlú ńlá náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.+ K ì kì fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò bàbà àti irin ni wọ́n fi fún ìṣúra ilé+ Jèhófà. 25  Kárùwà náà, Ráhábù àti agbo ilé baba rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí ó jẹ́ tirẹ̀ sì ni Jóṣúà pa mọ́ láàyè;+ ó sì ń gbé ní àárín Ísírẹ́lì títí di òní yìí,+ nítorí tí ó fi àwọn ońṣẹ́ tí Jóṣúà rán jáde láti ṣe amí Jẹ́ríkò+ pa mọ́. 26  Nígbà náà ni Jóṣúà mú kí a kéde ìbúra ní àkókò yẹn gan-⁠an pé: “Ègún ni fún ọkùnrin náà níwájú Jèhófà, tí ó bá dìde, tí ó sì tẹ ìlú ńlá yìí dó, àní Jẹ́ríkò. Pẹ̀lú ìpàdánù àkọ́bí rẹ̀ ni kí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, àti pẹ̀lú ìpàdánù àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni kí ó gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró.”+ 27  Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà wà pẹ̀lú Jóṣúà,+ òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé