Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóṣúà 4:1-24

4  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà ti parí ríré Jọ́dánì+ kọjá, Jèhófà tẹ̀ síwájú láti wí fún Jóṣúà pé:  “Ẹ mú ọkùnrin méj ì lá fún ara yín láti inú àwọn ènìyàn náà, ọkùnrin kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,+  kí o sì pàṣẹ fún wọn pé, ‘Ẹ gbé òkúta+ méj ì lá fún ara yín láti àárín Jọ́dánì gan-⁠an, láti ibi tí ẹsẹ̀ àwọn àlùfáà dúró pa+ sí, kí ẹ sì gbé wọn dání pẹ̀lú yín, kí ẹ sì kó wọn kalẹ̀ ní ibùwọ̀+ tí ẹ ó wọ̀ sí ní òru òní.’ ”  Nítorí náà, Jóṣúà pe ọkùnrin méj ì lá+ tí ó yàn láti inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọkùnrin kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan;  Jóṣúà sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Ẹ kọjá síwájú àpótí Jèhófà Ọlọ́run yín, sí àárín Jọ́dánì, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín sì gbé òkúta kan sórí èj ì ká rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,  kí èyí lè jẹ́ àmì láàárín+ yín. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ yín béèrè lẹ́yìnwá ọ̀la, pé, ‘Èé ṣe tí ẹ fi ní àwọn òkúta wọ̀nyí?’+  Kí ẹ wí fún àwọn pẹ̀lú pé, ‘Nítorí pé omi Jọ́dánì ni a ké kúrò níwájú àpótí májẹ̀mú Jèhófà.+ Nígbà tí àpótí náà la Jọ́dánì kọjá, omi Jọ́dánì ni a ké kúrò, àwọn òkúta wọ̀nyí sì jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ ”+  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Jóṣúà ti pàṣẹ, wọ́n sì gbé òkúta méj ì lá láti àárín Jọ́dánì, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti wí fún Jóṣúà, láti ṣe rẹ́gí pẹ̀lú iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;+ wọ́n sì gbé wọn dání pẹ̀lú wọn lọ sí ibùwọ̀ náà,+ wọ́n sì kó wọn kalẹ̀ níbẹ̀.  Òkúta méj ì lá kan tún wà tí Jóṣúà tò jọ sí àárín Jọ́dánì ní ibi tí àwọn àlùfáà tí wọ́n ru àpótí májẹ̀mú náà fi ẹsẹ̀ wọn dúró lé,+ wọ́n sì ń bá a lọ láti wà níbẹ̀ títí di òní yìí. 10  Àwọn àlùfáà tí ó ru Àpótí náà sì dúró sí àárín+ Jọ́dánì títí gbogbo ọ̀ràn tí Jèhófà pa láṣẹ fún Jóṣúà láti sọ fún àwọn ènìyàn náà fi parí, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mósè ti pa láṣẹ fún Jóṣúà.+ Ní gbogbo àkókò náà, àwọn ènìyàn náà ṣe wéré,+ wọ́n sì ré kọjá. 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí gbogbo ènìyàn náà ti parí rírékọjá, nígbà náà ni àpótí+ Jèhófà ré kọjá, àti àwọn àlùfáà, níwájú àwọn ènìyàn náà. 12  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ sì bẹ̀rẹ̀ sí ré kọjá pẹ̀lú ìtẹ́gun+ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti sọ fún wọn.+ 13  Nǹkan bí ọ̀kẹ́ méj ì tí ó gbára dì fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ré kọjá níwájú Jèhófà fún ogun, sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Jẹ́ríkò. 14  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà mú kí Jóṣúà di ẹni ńlá ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù rẹ̀, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Mósè ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+ 15  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Jóṣúà pé: 16  “Pàṣẹ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí gbólóhùn ẹ̀rí+ pé kí wọ́n gòkè kúrò nínú Jọ́dánì.” 17  Nítorí náà, Jóṣúà pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé: “Ẹ gòkè kúrò nínú Jọ́dánì.” 18  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà gòkè kúrò ní àárín Jọ́dánì, tí àtẹ́lẹsẹ̀+ àwọn àlùfáà náà sì jáde sórí ilẹ̀ gbígbẹ, nígbà náà ni omi Jọ́dánì bẹ̀rẹ̀ sí padà sí ipò rẹ̀ tí ó sì kún bo+ gbogbo bèbè rẹ̀ bí ti tẹ́lẹ̀ rí. 19  Àwọn ènìyàn náà sì gòkè kúrò nínú Jọ́dánì ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìíní, wọ́n sì dó sí Gílígálì+ ní ojú ààlà ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò. 20  Ní ti òkúta méj ì lá tí wọ́n kó jáde láti inú Jọ́dánì, Jóṣúà to ìwọ̀nyí jọ ní Gílígálì.+ 21  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ àwọn baba wọn lẹ́yìnwá ọ̀la, pé, ‘Kí ni àwọn òkúta wọ̀nyí túmọ̀ sí?’+ 22  Nígbà náà, kí ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀, pé, ‘Orí ilẹ̀ gbígbẹ ni Ísírẹ́lì gbà ré kọjá Jọ́dánì+ yìí, 23  nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run yín gbẹ omi Jọ́dánì táútáú níwájú wọn títí wọ́n fi ré kọjá, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ti ṣe sí Òkun Pupa nígbà tí ó mú un gbẹ táútáú kúrò níwájú wa títí a fi ré kọjá;+ 24  kí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé lè mọ ọwọ́+ Jèhófà, pé ó le;+ kí ẹ lè máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín ní ti gidi nígbà gbogbo.’ ”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé