Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 24:1-33

24  Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí pe gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọpọ̀ sí Ṣékémù,+ ó sì pe àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì+ àti àwọn olórí rẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ rẹ̀ àti àwọn onípò àṣẹ láàárín rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìdúró wọn níwájú Ọlọ́run+ tòótọ́.  Jóṣúà sì ń bá a lọ láti wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ní ìhà kej ì  Odò+ ni àwọn baba ńlá+ yín gbé ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, Térà baba Ábúráhámù àti baba Náhórì,+ wọn a sì máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn.  “ ‘Nígbà tí ó ṣe, mo mú baba ńlá yín Ábúráhámù+ kúrò ní ìhà kej ì  Odò,+ mo sì mú kí ó rin gbogbo ilẹ̀ Kénáánì já, mo sì sọ irú-ọmọ rẹ̀ di púpọ̀.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo fi Ísákì+ fún un.  Ísákì ni mo sì fi Jékọ́bù àti Ísọ̀+ fún. Lẹ́yìn náà, Ísọ̀ ni mo fún ní Òkè Ńlá Séírì láti gbà á;+ Jékọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì.+  Lẹ́yìn náà, mo rán Mósè àti Áárónì,+ mo sì mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá Íjíbítì pẹ̀lú ohun tí mo ṣe ní àárín rẹ̀;+ lẹ́yìn ìgbà náà, mo mú yín jáde.+  Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Íjíbítì,+ tí ẹ sì dé ibi òkun, àwọn ará Íjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti àwọn agẹṣinjagun lépa+ àwọn baba yín dé Òkun Pupa.  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà.+ Nítorí náà, ó fi òkùnkùn sáàárín ẹ̀yin àti àwọn ará Íjíbítì,+ ó sì mú òkun wá sórí wọn, ó sì fi bò wọ́n,+ ojú yín sì rí ohun tí mo ṣe ní Íjíbítì;+ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní aginjù fún ọjọ́ púpọ̀.+  “ ‘Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn Ámórì tí wọ́n ń gbé ní ìhà kej ì  Jọ́dánì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá yín jà.+ Látàrí èyí, mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, kí ẹ lè gba ilẹ̀ wọn, mo sì pa wọ́n rẹ́ ráúráú kúrò níwájú yín.+  Lẹ́yìn náà ni Bálákì ọmọkùnrin Sípórì,+ ọba Móábù dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Ísírẹ́lì jà.+ Nítorí náà, ó ránṣẹ́, ó sì fi ọlá àṣẹ pe Báláámù ọmọkùnrin Béórì láti pe ibi wá sórí yín.+ 10  Èmi kò sì fẹ́ fetí sí Báláámù.+ Nítorí náà, ó súre fún yín léraléra.+ Nípa báyìí, mo dá yín nídè kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 11  “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ bẹ̀rẹ̀ sí sọdá Jọ́dánì,+ tí ẹ sì wá sí Jẹ́ríkò.+ Àwọn onílẹ̀ Jẹ́ríkò, àwọn Ámórì àti àwọn Pérísì àti àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Gẹ́gáṣì àti àwọn Híf ì àti àwọn ará Jébúsì sì bẹ̀rẹ̀ sí bá yín jà; ṣùgbọ́n èmi fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.+ 12  Nítorí náà, mo rán ẹ̀mí ìrẹ̀wẹ̀sì ṣáájú yín, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó lé wọn jáde kúrò níwájú yín+—àwọn ọba Ámórì méj ì —kì í ṣe pẹ̀lú idà yín, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe pẹ̀lú ọrun yín.+ 13  Nípa báyìí, mo fún yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣe làálàá fún àti àwọn ìlú ńlá tí ẹ̀yin kò tẹ̀ dó,+ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú wọn. Àwọn ọgbà àjàrà àti oko ólíf ì tí ẹ̀yin kò gbìn ni ẹ ń jẹ.’+ 14  “Wàyí o, ẹ bẹ̀rù Jèhófà,+ kí ẹ sì máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́,+ kí ẹ sì mú àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìhà kej ì  Odò àti ní Íjíbítì+ kúrò, kí ẹ sì máa sin Jèhófà. 15  Wàyí o, bí ó bá burú ní ojú yín láti máa sin Jèhófà, lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn+ fún ara yín, yálà àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín tí wọ́n wà ní ìhà kej ì  Odò tẹ́lẹ̀ sìn+ ni tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì ní ilẹ̀ àwọn ẹni tí ẹ ń gbé.+ Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”+ 16  Látàrí èyí, àwọn ènìyàn náà dáhùn pé: “Kò ṣeé ronú kàn fún àwa, láti fi Jèhófà sílẹ̀ láti lè sin àwọn ọlọ́run mìíràn. 17  Nítorí Jèhófà Ọlọ́run wa ni ẹni tí ó mú àwa àti àwọn baba wa gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò ní ilé ẹrú,+ tí ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ńláǹlà wọ̀nyí ní ojú wa,+ tí ó sì ń ṣọ́ wa ní gbogbo ọ̀nà tí àwa rìn àti láàárín gbogbo àwọn ènìyàn, àárín àwọn tí àwa là kọjá.+ 18  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo àwọn ènìyàn+ náà jáde kúrò níwájú wa, àní àwọn Ámórì, tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ náà. Àwa ní tiwa, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn, nítorí òun ni Ọlọ́run wa.”+ 19  Jóṣúà sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ kò lè sin Jèhófà, nítorí ó jẹ́ Ọlọ́run mímọ́;+ ó jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.+ Òun kì yóò dárí ìdìtẹ̀ yín àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín j ì  yín.+ 20  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ fi Jèhófà+ sílẹ̀, tí ẹ sì sin àwọn ọlọ́run+ ilẹ̀ òkèèrè, dájúdájú, òun náà yóò yí padà, yóò sì ṣe yín ní èṣe, yóò sì pa yín run pátápátá lẹ́yìn tí ó bá ti ṣe rere+ fún yín.” 21  Ní tiwọn, àwọn ènìyàn náà wí fún Jóṣúà pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n Jèhófà ni àwa yóò máa sìn!”+ 22  Látàrí èyí, Jóṣúà wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lòdì sí ara yín+ pé, ẹ̀yin, láti inú ìdánúṣe ara yín, ti yan Jèhófà fún ara yín láti máa sìn ín.”+ Wọ́n fèsì pé: “Àwa ni ẹlẹ́rìí.” 23  “Wàyí o, ẹ kó àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè tí ó wà láàárín yín kúrò,+ kí ẹ sì tẹ ọkàn-àyà yín sí ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” 24  Ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn náà wí fún Jóṣúà pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa ni àwa yóò máa sìn, ohùn rẹ̀ sì ni àwa yóò fetí sí!”+ 25  Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ènìyàn náà dá májẹ̀mú ní ọjọ́ yẹn, ó sì gbé ìlànà àti ìpinnu ìdájọ́+ kalẹ̀ fún wọn ní Ṣékémù. 26  Lẹ́yìn náà, Jóṣúà kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sínú ìwé òfin+ Ọlọ́run, ó sì gbé òkúta+ ńlá kan, ó sì gbé e kalẹ̀ níbẹ̀ lábẹ́ igi+ ràgàj ì  tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùjọsìn Jèhófà. 27  Jóṣúà sì ń bá a lọ láti wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ wò ó! Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí wa,+ nítorí òkúta náà pàápàá ti gbọ́ gbogbo àsọjáde tí Jèhófà bá wa sọ, yóò sì jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí yín, kí ẹ má bàa sẹ́ Ọlọ́run yín.” 28  Látàrí ìyẹn, Jóṣúà rán àwọn ènìyàn náà lọ, olúkúlùkù sí ogún+ rẹ̀. 29  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì, ìránṣẹ́ Jèhófà, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún.+ 30  Wọ́n sì sin ín sí ìpínlẹ̀ ogún rẹ̀ ní Timunati-sérà,+ èyí tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù, ní àríwá Òkè Ńlá Gááṣì. 31  Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ láti sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ ayé àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n wà láàyè lẹ́yìn Jóṣúà,+ tí wọ́n sì ti mọ gbogbo iṣẹ́ Jèhófà tí ó ṣe fún Ísírẹ́lì.+ 32  Àwọn egungun+ Jósẹ́fù, èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó gòkè kúrò ní Íjíbítì, ni wọ́n sin sí Ṣékémù ní abá pápá tí Jékọ́bù rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì,+ baba Ṣékémù, ní ọgọ́rùn-ún ẹyọ owó;+ ó sì wá di ti àwọn ọmọ Jósẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ogún.+ 33  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Élíásárì ọmọkùnrin Áárónì kú.+ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sin ín sí Òkè Kékeré Fíníhásì ọmọkùnrin rẹ̀,+ èyí tí ó ti fi fún un ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé