Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 23:1-16

23  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn tí Jèhófà ti fún Ísírẹ́lì ní ìsinmi+ lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá wọn yí ká, nígbà tí Jóṣúà darúgbó, tí ó sì pọ̀ ní ọjọ́,+  pé Jóṣúà bẹ̀rẹ̀ sí pe gbogbo Ísírẹ́lì,+ àwọn àgbà ọkùnrin rẹ̀ àti àwọn olórí rẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ rẹ̀ àti àwọn onípò àṣẹ+ láàárín rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé: “Ní tèmi, mo ti di arúgbó, mo ti pọ̀ ní ọjọ́.  Ní tiyín, ẹ ti rí gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ní tìtorí yín,+ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run yín ni ẹni tí ń jà fún yín.+  Wò ó, nípa kèké,+ èmi ti fi àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí ó kù fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún fún àwọn ẹ̀yà yín, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ké kúrò,+ láti Jọ́dánì títí dé Òkun Ńlá níbi wíwọ̀ oòrùn.+  Jèhófà Ọlọ́run yín sì ni ẹni tí ń tì wọ́n kúrò níwájú yín,+ òun sì ni ẹni tí ó lé wọn kúrò ní tìtorí yín, ẹ sì gba ilẹ̀ wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ti ṣèlérí fún yín.+  “Kí ẹ sì jẹ́ onígboyà+ gidigidi láti pa gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé+ òfin Mósè mọ́ àti láti tẹ̀ lé wọn nípa ṣíṣàìyí padà kúrò nínú rẹ̀ láé sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+  nípa ṣíṣàìṣe wọlé-wọ̀de láàárín àwọn orílẹ̀-èdè+ wọ̀nyí rárá, ìwọ̀nyí tí ó ṣẹ́ kù pẹ̀lú yín. Kí ẹ má sì ṣe dá orúkọ àwọn ọlọ́run+ wọn, tàbí kí ẹ fi wọ́n búra,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n tàbí kí ẹ tẹrí ba fún wọn.+  Ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ rọ̀ mọ́,+ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe títí di òní yìí.  Jèhófà yóò sì lé àwọn orílẹ̀-èdè ńlá tí ó lágbára ńlá kúrò níwájú yín.+ (Ní tiyín, kò sí ọkùnrin kan tí ó tí ì dúró níwájú yín títí di òní yìí.)+ 10  Ọkùnrin kan ṣoṣo nínú yín yóò lépa ẹgbẹ̀rún,+ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run yín ni ẹni tí ń jà fún yín,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.+ 11  Kí ẹ sì máa ṣọ́+ ọkàn yín ní ìgbà gbogbo nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ yín. 12  “Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà pẹ́nrẹ́n,+ tí ẹ sì rọ̀ mọ́ ìyókù àwọn orílẹ̀-èdè+ wọ̀nyí, àwọn tí ó ṣẹ́ kù láàárín yín wọ̀nyí, tí ẹ ń bá wọn dána,+ tí ẹ sì ń ṣe wọlé-wọ̀de láàárín wọn, àti àwọn láàárín yín, 13  kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé Jèhófà Ọlọ́run yín kò ní máa bá a lọ láti lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kúrò ní tìtorí+ yín; wọn yóò sì di pańpẹ́ àti ìdẹkùn fún yín, àti ọrẹ́ ní ìhà+ yín, àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò lórí ilẹ̀ dáradára yìí tí Jèhófà Ọlọ́run yín ti fi fún yín.+ 14  “Wàyí o, wò ó! èmi ń lọ lónìí ní ọ̀nà gbogbo ilẹ̀ ayé,+ ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.+ 15  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín ti wá sórí yín,+ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yóò mú gbogbo ọ̀rọ̀ ibi wá sórí yín títí yóò fi pa yín rẹ́ ráúráú kúrò lórí ilẹ̀ dáradára yìí tí Jèhófà Ọlọ́run yín fi fún yín,+ 16  nítorí títẹ̀ tí ẹ tẹ májẹ̀mú tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín lójú, àti nítorí pé ẹ̀yin lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì tẹrí ba fún wọn.+ Dájúdájú, ìbínú Jèhófà yóò ru sí yín,+ dájúdájú, ẹ̀ ó sì ṣègbé wéréwéré kúrò lórí ilẹ̀ dáradára tí ó fi fún yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé