Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóṣúà 22:1-34

22  Ní àkókò yẹn, Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí pe àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè,+  ó sì wí fún wọ́n pé: “Ní tiyín, ẹ ti pa gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ fún yín+ mọ́, ẹ sì jẹ́ onígbọràn sí ohùn mi nínú gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín.+  Ẹ̀yin kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọjọ́+ wọ̀nyí wá títí di òní yìí, ẹ sì ti pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run+ yín mọ́.  Wàyí o, Jèhófà Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.+ Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ yí padà, kí ẹ sì mú ọ̀nà yín pọ̀n lọ sínú àwọn àgọ́ yín ní ilẹ̀ ìní yín, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fi fún yín ní ìhà kej ì Jọ́dánì.+  K ì kì pé kí ẹ kíyè sára gidigidi láti mú àṣẹ+ àti òfin tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ fún yín ṣẹ nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ yín àti nípa rírìn ní gbogbo ọ̀nà+ rẹ̀ àti nípa pípa àwọn àṣẹ+ rẹ̀ mọ́ àti nípa rírọ̀ mọ́ ọn+ àti nípa sísìn+ ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà+ yín àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn+ yín.”  Látàrí ìyẹn, Jóṣúà súre+ fún wọn, ó sì rán wọn lọ, kí wọ́n lè máa lọ sínú àgọ́ wọn.  Ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè sì ni Mósè ti fi ẹ̀bùn fún ní Báṣánì,+ ààbọ̀ rẹ̀ yòókù sì ni Jóṣúà fi ẹ̀bùn fún pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì níhà ìwọ̀-oòrùn.+ Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, nígbà tí Jóṣúà rán wọn lọ sínú àgọ́ wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn.  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Ẹ padà sínú àgọ́ yín, ti ẹ̀yin ti ọrọ̀ púpọ̀ àti ohun ọ̀sìn púpọ̀ gidigidi, pẹ̀lú fàdákà àti wúrà àti bàbà àti irin àti ẹ̀wù ní ìwọ̀n púpọ̀ rẹpẹtẹ gan-⁠an.+ Ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín, ẹ kó ìpín tiyín nínú ohun ìfiṣèjẹ+ tí ó jẹ́ ti àwọn ọ̀tá yín.”  Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè padà, wọ́n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, láti Ṣílò, èyí tí ó wà ní ilẹ̀ Kénáánì, kí wọ́n lè lọ sí ilẹ̀ Gílíádì,+ sí ilẹ̀ ìní wọn, inú èyí tí a tẹ̀ wọ́n dó sí nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà nípasẹ̀ Mósè.+ 10  Nígbà tí wọ́n dé àwọn ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì tí ó wà ní ilẹ̀ Kénáánì, nígbà náà ni àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè mọ pẹpẹ sí ibẹ̀ lẹ́bàá Jọ́dánì, pẹpẹ+ kan tí ó tóbi lọ́nà tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà. 11  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù gbọ́+ tí a sọ pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ti mọ pẹpẹ kan sí ààlà ilẹ̀ ti ilẹ̀ Kénáánì ní àwọn ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì ní ìhà tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” 12  Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ nípa rẹ̀, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ni a mú kí wọ́n péjọ pọ̀ ní Ṣílò+ láti gòkè lọ fún ìgbésẹ̀ ológun lòdì sí wọn.+ 13  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rán+ Fíníhásì+ ọmọkùnrin Élíásárì àlùfáà sí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ilẹ̀ Gílíádì, 14  ìjòyè mẹ́wàá sì pẹ̀lú rẹ̀, ìjòyè kan láti ìdí ilé baba kọ̀ọ̀kan láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ olórí ilé baba wọn nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì.+ 15  Nígbà tí ó ṣe, wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ilẹ̀ Gílíádì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn+ sọ̀rọ̀, pé: 16  “Èyí ni ohun tí gbogbo àpéjọ Jèhófà+ wí, ‘Ìwà àìṣòótọ́+ wo ni ẹ hù sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì yìí, ní yíyípadà+ lónìí kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn nípa mímọ pẹpẹ+ kan fún ara yín, kí ẹ lè ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà lónìí? 17  Ṣé ìṣìnà Péórù+ kéré jù fún wa ni, inú èyí tí àwa kò tí ì wẹ ara wa mọ́ kúrò títí di òní yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyọnu àjàkálẹ̀ náà wá wà lórí àpéjọ Jèhófà?+ 18  Àti pé ẹ̀yin​—⁠ẹ̀yin yóò yí padà lónìí kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí ẹ̀yin, ní tiyín, bá ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà lónìí, ní ọ̀la, ìkannú+ rẹ̀ yóò wá ru sí gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì pátá. 19  Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́ pé ilẹ̀ ìní yín di àìmọ́,+ ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n láti sọdá sí ilẹ̀ ìní+ Jèhófà níbi tí àgọ́ ìjọsìn Jèhófà ń gbé,+ kí ẹ sì tẹ̀ dó ní àárín wa; kí ẹ má sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, kí ẹ má sì sọ wá di ẹni tí ó ṣọ̀tẹ̀ nípa mímọ pẹpẹ kan fún ara yín ní àfikún sí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run+ wa. 20  K ì  í ha ṣe Ákáánì+ ọmọkùnrin Síírà ni ó hu ìwà àìṣòótọ́ ní ti ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kì í ha ṣe gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì ni ìkannú+ sì ru sí? K ì  í sì í ṣe òun nìkan ṣoṣo ni ó gbẹ́mìí mì nínú ìṣìnà+ rẹ̀.’ ” 21  Látàrí èyí, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè dáhùn,+ wọ́n sì sọ fún àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì+ pé: 22  “Olú Ọ̀run,+ Ọlọ́run,+ Jèhófà, Olú Ọ̀run, Ọlọ́run, Jèhófà,+ òun ni ó mọ̀,+ àti Ísírẹ́lì, òun náà yóò mọ̀.+ Bí ó bá jẹ́ nínú ìṣọ̀tẹ̀,+ bí ó bá sì jẹ́ nínú ìwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà,+ má ṣe gbà wá là ní òní yìí. 23  Bí ó bá jẹ́ pé láti mọ pẹpẹ fún ara wa, kí a bàa lè yí padà kúrò nínú títọ Jèhófà lẹ́yìn ni, bí ó bá sì jẹ́ pé láti fi àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà rúbọ lórí rẹ̀ ni,+ bí ó bá sì jẹ́ pé láti rú ẹbọ ìdàpọ̀ lórí rẹ̀ ni, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò ṣàwárí;+ 24  tàbí bí kì í bá kúkú ṣe láti inú àníyàn ṣíṣe fún ohun mìíràn kan ni àwa ti ṣe èyí, pé, ‘Ní ọjọ́ iwájú, àwọn ọmọ yín yóò wí fún àwọn ọmọ wa pé: “Kí ni ohun tí ó pa ẹ̀yin àti Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì pọ̀? 25  Ààlà kan sì wà tí Jèhófà ti fi sáàárín àwa àti ẹ̀yin, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, èyíinì ni, Jọ́dánì. Ẹ̀yin kò ní ìpín kankan nínú Jèhófà.”+ Dájúdájú, àwọn ọmọ yín yóò mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun bíbẹ̀rù Jèhófà.’+ 26  “Nítorí èyí, àwa wí pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, nítorí tiwa, ẹ jẹ́ kí a gbé ìgbésẹ̀ nípa mímọ pẹpẹ náà, kì í ṣe fún ọrẹ ẹbọ sísun tàbí fún ẹbọ, 27  ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ ẹ̀rí láàárín àwa+ àti ẹ̀yin àti àwọn ìran wa lẹ́yìn wa, kí àwa lè fi àwọn ọrẹ ẹbọ wa àti àwọn ẹbọ sísun wa àti àwọn ẹbọ+ ìdàpọ̀ wa ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà níwájú rẹ̀, kí àwọn ọmọ yín má bàa wí fún àwọn ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú pé: “Ẹ̀yin kò ní ìpín kankan nínú Jèhófà.” ’ 28  Nítorí náà, àwa wí pé, ‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n bá wí bẹ́ẹ̀ fún àwa àti àwọn ìran wa ní ọjọ́ iwájú, àwa pẹ̀lú yóò wí pé: “Ẹ wo àwòrán pẹpẹ Jèhófà tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ọrẹ ẹbọ sísun, tàbí fún ẹbọ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ẹ̀rí láàárín àwa àti ẹ̀yin.” ’ 29  Kò ṣeé ronú kàn fún àwa, láti ṣọ̀tẹ̀ láti inú ìdánúṣe wa sí Jèhófà, kí a sì yí padà lónìí kúrò nínú títọ Jèhófà+ lẹ́yìn nípa mímọ pẹpẹ kan fún ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ọkà àti ẹbọ ní àfikún sí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run wa, èyí tí ó wà níwájú àgọ́ ìjọsìn+ rẹ̀!” 30  Wàyí o, nígbà tí Fíníhásì+ àlùfáà àti àwọn ìjòyè àpéjọ+ àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Mánásè sọ, ó dára ní ojú wọn. 31  Nítorí náà, Fíníhásì ọmọkùnrin Élíásárì àlùfáà wí fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Mánásè pé: “Lónìí, àwa mọ̀ pé Jèhófà wà ní àárín wa,+ nítorí tí ẹ̀yin kò hu ìwà àìṣòótọ́ yìí sí Jèhófà. Nísinsìnyí, ẹ dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní ọwọ́ Jèhófà.”+ 32  Látàrí ìyẹn, Fíníhásì ọmọkùnrin Élíásárì àlùfáà àti àwọn ìjòyè padà+ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì ní ilẹ̀ Gílíádì sí ilẹ̀ Kénáánì, sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, wọ́n sì mú ọ̀rọ̀ padà wá fún wọn.+ 33  Ọ̀rọ̀ náà sì dára ní ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìbùkún fún Ọlọ́run,+ wọn kò sì sọ̀rọ̀ nípa gígòkè lọ fún iṣẹ́ ìsìn ológun ní ìgbéjàkò wọ́n láti run ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì ń gbé. 34  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì sì fún pẹpẹ náà ní orúkọ, nítorí tí “ó jẹ́ ẹ̀rí láàárín wa pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé