Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóṣúà 21:1-45

21  Wàyí o, àwọn olórí àwọn baba àwọn ọmọ Léf ì sì lọ bá Élíásárì+ àlùfáà àti Jóṣúà+ ọmọkùnrin Núnì àti àwọn olórí nínú àwọn baba ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,  wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn ní Ṣílò+ ní ilẹ̀ Kénáánì, pé: “Jèhófà nípasẹ̀ Mósè pàṣẹ pé kí a fún wa ní àwọn ìlú ńlá nínú èyí tí àwa yóò máa gbé, pa pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìjẹko wọn fún àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wa.”+  Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ọmọ Léf ì+ ní ìlú ńlá wọ̀nyí àti ilẹ̀ ìjẹko wọn láti inú ogún+ wọn, nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà.  Nígbà náà ni kèké jáde wá fún àwọn ìdílé ọmọ Kóhátì,+ ìlú ńlá mẹ́tàlá sì wá jẹ́ ti àwọn ọmọ Áárónì àlùfáà, ti àwọn ọmọ Léf ì, nípa kèké láti inú ẹ̀yà Júdà+ àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì+ àti láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.+  Àti ní ti àwọn ọmọ Kóhátì+ tí ó ṣẹ́ kù, wọ́n ní ìlú ńlá mẹ́wàá nípa kèké láti inú àwọn ìdílé ẹ̀yà Éfúráímù+ àti láti inú ẹ̀yà Dánì+ àti láti inú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.+  Àti ní ti àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì,+ wọ́n ní ìlú ńlá mẹ́tàlá nípa kèké láti inú àwọn ìdílé ẹ̀yà Ísákárì+ àti láti inú ẹ̀yà Áṣérì+ àti láti inú ẹ̀yà Náfútálì+ àti láti inú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní Báṣánì.+  Ní ti àwọn ọmọ Mérárì+ nípa àwọn ìdílé wọn, wọ́n ní ìlú ńlá méj ì lá láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì+ àti láti inú ẹ̀yà Gádì+ àti láti inú ẹ̀yà Sébúlúnì.+  Nípa báyìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ọmọ Léf ì ní ìlú ńlá wọ̀nyí àti ilẹ̀ ìjẹko+ wọn nípa kèké,+ gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+  Nítorí náà, láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Júdà àti láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì, wọ́n fi àwọn ìlú ńlá tí a dárúkọ wọ̀nyí fún wọn,+ 10  wọ́n sì wá jẹ́ ti àwọn ọmọ Áárónì láti inú àwọn ìdílé ọmọ Kóhátì nínú àwọn ọmọ Léf ì, nítorí pé kèké àkọ́kọ́ jẹ́ tiwọn.+ 11  Nípa báyìí, wọ́n fi Kiriati-áríbà+ fún wọn, (Áríbà náà ni baba Ánákì),+ èyíinì ni, Hébúrónì,+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Júdà+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ tí ó yí i ká; 12  pápá ìlú ńlá náà àti àwọn ibi ìtẹ̀dó rẹ̀ ni wọ́n sì fi fún Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀.+ 13  Àwọn ọmọ Áárónì àlùfáà ni wọ́n sì fún ní ìlú ńlá ìsádi+ tí ó wà fún àwọn apànìyàn,+ èyíinì ni, Hébúrónì,+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, pẹ̀lú Líbínà+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 14  àti Játírì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Éṣítémóà+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 15  àti Hólónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Débírì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 16  àti Áyínì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Jútà+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́sàn-⁠án láti inú ẹ̀yà méj ì wọ̀nyí. 17  Àti láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Gíbéónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Gébà+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 18  Ánátótì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Álímónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́rin. 19  Gbogbo ìlú ńlá àwọn ọmọ Áárónì,+ àwọn àlùfáà, jẹ́ ìlú ńlá mẹ́tàlá àti àwọn ilẹ̀ ìjẹko wọn.+ 20  Àti ní ti àwọn ìdílé ọmọ Kóhátì, àwọn ọmọ Léf ì tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Kóhátì, wọ́n wá ní àwọn ìlú ńlá láti inú ẹ̀yà Éfúráímù+ nípa kèké wọn. 21  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n fún wọn ní ìlú ńlá ìsádi+ tí ó wà fún apànìyàn,+ èyíinì ni, Ṣékémù,+ àti ilẹ̀ ìjẹko+ rẹ̀ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù, àti Gésérì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 22  àti Kíbúsáímù+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Bẹti-hórónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́rin. 23  Àti láti inú ẹ̀yà Dánì, Élítékè àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Gíbétónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 24  Áíjálónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Gati-rímónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́rin. 25  Àti láti inú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, Táánákì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Gati-rímónì àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá méj ì . 26  Gbogbo àwọn ìlú ńlá náà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko wọn, tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé ọmọ Kóhátì tí ó ṣẹ́ kù jẹ́ mẹ́wàá. 27  Àti ní ti àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì,+ ti àwọn ìdílé ọmọ Léf ì, láti inú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè,+ wọ́n ní ìlú ńlá ìsádi tí ó wà fún apànìyàn, èyíinì ni, Gólánì,+ ní Báṣánì, àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Bééṣítérà+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá méj ì . 28  Àti láti inú ẹ̀yà Ísákárì,+ Kíṣíónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Dábérátì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 29  Jámútì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Ẹ́ń-gánímù+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́rin. 30  Àti láti inú ẹ̀yà Áṣérì,+ Míṣálì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Ábídónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 31  Hélíkátì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Réhóbù+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́rin. 32  Àti láti inú ẹ̀yà Náfútálì,+ ìlú ńlá ìsádi+ tí ó wà fún àwọn apànìyàn,+ èyíinì ni, Kédéṣì+ ní Gálílì, àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Hamoti-dórì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Kátánì àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́ta. 33  Gbogbo ìlú ńlá àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì nípa àwọn ìdílé wọn jẹ́ ìlú ńlá mẹ́tàlá àti ilẹ̀ ìjẹko wọn. 34  Àti àwọn ìdílé àwọn ọmọ Mérárì,+ àwọn ọmọ Léf ì tí ó ṣẹ́ kù, láti inú ẹ̀yà Sébúlúnì,+ wọ́n ní Jókínéámù+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Kárítà àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 35  Dímúnà+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Náhálálì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́rin. 36  Àti láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì,+ Bésérì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Jáhásì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 37  Kédémótì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Mẹ́fáátì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; ìlú ńlá mẹ́rin. 38  Àti láti inú ẹ̀yà Gádì,+ ìlú ńlá ìsádi tí ó wà fún àwọn apànìyàn, èyíinì ni, Rámótì ní Gílíádì,+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, àti Máhánáímù+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, 39  Hẹ́ṣíbónì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀, Jásérì+ àti ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀; gbogbo ìlú ńlá náà jẹ́ mẹ́rin. 40  Gbogbo ìlú ńlá tí ó wá jẹ́ ti àwọn ọmọ Mérárì+ nípa àwọn ìdílé wọn, àwọn tí ó ṣẹ́ kù láti inú àwọn ìdílé ọmọ Léf ì, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, jẹ́ ìlú ńlá méj ì lá. 41  Gbogbo ìlú ńlá àwọn ọmọ Léf ì láàárín ohun ìní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ìlú ńlá+ méj ì -dín-láàádọ́ta pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko wọn.+ 42  Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú ńlá wọ̀nyí wá jẹ́ ìlú ńlá kan pẹ̀lú ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ tí ó yí i ká​—⁠báyìí ni gbogbo ìlú ńlá wọ̀nyí rí.+ 43  Nítorí náà, Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní gbogbo ilẹ̀ tí ó búra láti fi fún àwọn baba ńlá+ wọn, wọ́n sì ń gbà á,+ wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀. 44  Síwájú sí i, Jèhófà fún wọn ní ìsinmi+ yí ká, ní ìbámu pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó búra+ fún àwọn baba ńlá wọn, kò sì sí ẹnì kankan nínú gbogbo àwọn ọ̀tá wọn tí ó dúró níwájú wọn.+ Gbogbo ọ̀tá wọn ni Jèhófà fi lé wọn lọ́wọ́.+ 45  Kò sí ìlérí kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí dáradára tí Jèhófà ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé