Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 20:1-9

20  Lẹ́yìn náà ni Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé:  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Ẹ pèsè àwọn ìlú ńlá ìsádi+ fún ara yín, èyí tí mo sọ fún yín nípasẹ̀ Mósè,  fún apànìyàn+ tí ó fi àìmọ̀ọ́mọ̀ kọlu ọkàn kan lọ́nà tí ó yọrí sí ikú, kí ó lè sá lọ sí ibẹ̀; kí wọ́n sì jẹ́ ibi ìsádi fún yín kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.+  Kí ó sì sá+ lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá wọ̀nyí, kí ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ẹnubodè+ ìlú ńlá náà, kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní etí-ìgbọ́ àwọn àgbà ọkùnrin+ ìlú ńlá yẹn; kí wọ́n sì gbà á sínú ìlú ńlá náà sọ́dọ̀ ara wọn, kí wọ́n sì fún un ní ibì kan, kí ó sì máa bá wọn gbé.  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lépa rẹ̀, nígbà náà, kí wọ́n má ṣe fi apànìyàn náà lé e lọ́wọ́;+ nítorí pé ó fi àìmọ̀ kọlu ọmọnìkej ì  rẹ̀ lọ́nà tí ó yọrí sí ikú, òun kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí.+  Kí ó sì máa gbé inú ìlú ńlá yẹn títí yóò fi dúró níwájú àpéjọ fún ìdájọ́,+ títí di ìgbà ikú àlùfáà+ àgbà tí ó wà ní ọjọ́ wọnnì. Lẹ́yìn náà ni apànìyàn náà tó lè padà,+ òun yóò sì wọnú ìlú ńlá rẹ̀ àti inú ilé rẹ̀, inú ìlú ńlá tí ó ti sá kúrò.’ ”  Nítorí náà, wọ́n fi ipò ọlọ́wọ̀ fún Kédéṣì+ ní Gálílì ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Náfútálì àti Ṣékémù+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Éfúráímù àti Kiriati-ábà,+ èyíinì ni, Hébúrónì, ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Júdà.  Àti ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì, ní Jẹ́ríkò, níhà ìlà-oòrùn, wọ́n pèsè Bésérì+ ní aginjù tí ó wà lórí ilẹ̀ títẹ́ pẹrẹsẹ, láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì,+ àti Rámótì+ ní Gílíádì láti inú ẹ̀yà Gádì, àti Gólánì+ ní Báṣánì láti inú ẹ̀yà Mánásè.  Ìwọ̀nyí ni ó di àwọn ìlú ńlá tí a yàn kalẹ̀ fún gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín wọn, fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àìmọ̀ọ́mọ̀+ kọlu ọkàn kan lọ́nà tí ó yọrí sí ikú, kí ó lè sá lọ sí ibẹ̀, kí ó má bàa kú láti ọwọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ títí òun yóò fi dúró níwájú àpéjọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé