Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 2:1-24

2  Lẹ́yìn náà, Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì rán ọkùnrin méj ì  jáde ní bòókẹ́lẹ́ láti Ṣítímù,+ gẹ́gẹ́ bí amí, pé: “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà àti Jẹ́ríkò.” Nítorí náà, wọ́n lọ, wọ́n sì dé ilé obìnrin kárùwà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ráhábù,+ wọ́n sì wọ̀ sí ibẹ̀.  Nígbà tí ó yá, a sọ ọ́ fún ọba Jẹ́ríkò pé: “Wò ó! Àwọn ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wọlé síhìn-ín ní òru òní láti ṣàyẹ̀wò ilẹ̀ yìí.”  Látàrí ìyẹn, ọba Jẹ́ríkò ránṣẹ́ sí Ráhábù pé: “Mú àwọn ọkùnrin tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ jáde, tí wọ́n wá sí ilé rẹ, nítorí láti ṣàyẹ̀wò gbogbo ilẹ̀ yìí ni wọ́n ṣe wá.”+  Láàárín àkókò yìí, obìnrin náà mú àwọn ọkùnrin méjèèj ì , ó sì fi wọ́n pa mọ́. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ mi ní tòótọ́, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n ti wá.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí àkókò ti ń tó láti ti ẹnubodè+ nígbà tí ilẹ̀ ṣú ni àwọn ọkùnrin náà jáde lọ. Èmi kò sáà mọ ibi tí àwọn ọkùnrin náà lọ. Ẹ tètè lépa wọn, nítorí ẹ óò bá wọn.”  (Obìnrin náà, bí ó ti wù kí ó rí, ti mú wọn gun òrùlé+ lọ, ó sì fi wọ́n pa mọ́ kúrò ní ojútáyé, sáàárín pòròpórò ọ̀gbọ̀ tí a bá a tò ní ẹsẹẹsẹ sórí òrùlé náà.)  Àwọn ọkùnrin náà sì lépa wọn gba ìhà ọ̀nà Jọ́dánì níbi odò pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́,+ wọ́n sì ti ẹnubodè lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn tí ń lépa wọn ti jáde lọ.  Ní ti àwọn wọ̀nyí, kí wọ́n tó dùbúlẹ̀, òun fúnra rẹ̀ gòkè lọ bá wọn lórí òrùlé.  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún àwọn ọkùnrin náà pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ilẹ̀ yìí fún yín dájúdájú,+ j ì nnìj ì nnì yín sì ti bá wa,+ àti pé gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí ni ọkàn wọn ti domi nítorí yín.+ 10  Nítorí a ti gbọ́ bí Jèhófà ti gbẹ omi Òkun Pupa táútáú kúrò níwájú yín nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Íjíbítì,+ àti ohun tí ẹ ṣe sí àwọn ọba méj ì  ti àwọn Ámórì tí wọ́n wà ní ìhà kej ì  Jọ́dánì, èyíinì ni, Síhónì+ àti Ógù,+ tí ẹ yà sọ́tọ̀ fún ìparun.+ 11  Nígbà tí a gbọ́ nípa rẹ̀, nígbà náà ni ọkàn-àyà wa bẹ̀rẹ̀ sí domi,+ ẹ̀mí kankan kò sì tí ì dìde síbẹ̀ nínú ẹnikẹ́ni nítorí yín,+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run nínú ọ̀run lókè àti lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.+ 12  Wàyí o, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi Jèhófà+ búra fún mi pé, nítorí tí mo lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí yín, ẹ̀yin pẹ̀lú yóò lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí agbo ilé baba mi,+ kí ẹ sì fún mi ní àmì+ kan tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. 13  Kí ẹ sì pa baba mi+ àti ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn arábìnrin mi àti gbogbo ẹni tí ó jẹ́ tiwọn mọ́ láàyè, kí ẹ sì dá ọkàn wa nídè kúrò lọ́wọ́ ikú.”+ 14  Látàrí ìyẹn, àwọn ọkùnrin náà wí fún un pé: “Ọkàn wa ni kí ó kú dípò yín!+ Bí ẹ̀yin kò bá ní sọ nípa ọ̀ràn wa yìí, yóò sì ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú pé nígbà tí Jèhófà bá fi ilẹ̀ yìí fún wa, dájúdájú, àwa pẹ̀lú yóò lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé sí ọ.”+ 15  Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú kí wọ́n fi ìjàrá sọ̀ kalẹ̀ lójú fèrèsé, nítorí ilé rẹ̀ wà ní ara ògiri, orí ògiri náà ni ó sì ń gbé.+ 16  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Ẹ lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, kí àwọn tí ń lépa yín má bàa kàn yín lára; kí ẹ sì fi ara yín pa mọ́ níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn tí ń lépa yín yóò fi padà dé, lẹ́yìn ìgbà náà, ẹ lè máa bá ọ̀nà tiyín lọ.” 17  Ní tiwọn, àwọn ọkùnrin náà wí fún un pé: “Àwa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ní ti ìbúra rẹ yìí tí ìwọ ti mú kí a búra.+ 18  Wò ó! Àwa ń bọ̀ wá sí ilẹ̀ yìí. Okùn fọ́nrán òwú rírẹ̀dòdò yìí ni kí ìwọ so mọ́ fèrèsé tí o fi mú wa sọ̀ kalẹ̀, baba rẹ àti ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ àti gbogbo agbo ilé baba rẹ sì ni kí o kó jọ sọ́dọ̀ ara rẹ nínú ilé.+ 19  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde sí ìta+ àwọn ilẹ̀kùn ilé rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí ara rẹ̀, àwa yóò sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi; olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú rẹ nínú ilé, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí wa bí ọwọ́ kan bá kàn án. 20  Bí ìwọ bá sì ròyìn ọ̀ràn wa yìí,+ àwa pẹ̀lú yóò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ní ti ìbúra rẹ yìí tí ìwọ ti mú kí a búra.” 21  Ó fèsì pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí.” Pẹ̀lú ìyẹn, ó rán wọn lọ, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ. Lẹ́yìn náà, ó so okùn rírẹ̀dòdò náà mọ́ fèrèsé náà. 22  Nítorí náà, wọ́n lọ, wọ́n sì dé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, wọ́n sì ń bá a lọ láti máa gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn olùlépa náà fi padà dé. Wàyí o, àwọn olùlépa náà ń wá wọn ní gbogbo ojú ọ̀nà, wọn kò sì rí wọn. 23  Àwọn ọkùnrin méj ì  náà sì tún bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, wọ́n sì sọdá, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un. 24  Wọ́n sì ń bá a lọ láti wí fún Jóṣúà pé: “Jèhófà ti fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́.+ Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà ni ọkàn wọn ti domi nítorí wa.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé