Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 19:1-51

19  Lẹ́yìn náà ni kèké+ kej ì  jáde wá fún Síméónì,+ fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì nípa àwọn ìdílé wọn. Ogún wọn sì wá wà ní àárín ogún àwọn ọmọ Júdà.+  Wọ́n sì wá ní Bíá-ṣébà+ pẹ̀lú Ṣébà àti Móládà+ nínú ogún wọn,  àti Hasari-ṣúálì+ àti Bálà àti Ésémù,+  àti Élítóládì+ àti Bẹ́túlì àti Hóómà,  àti Síkílágì+ àti Bẹti-mákábótì àti Hasari-súsà,+  àti Bẹti-lébáótì+ àti Ṣárúhénì; ìlú ńlá mẹ́tàlá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn.  Áyínì,+ Rímónì+ àti Étérì àti Áṣánì;+ ìlú ńlá mẹ́rin àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn,  àti gbogbo ibi ìtẹ̀dó tí ó wà ní gbogbo àyíká ìlú ńlá wọ̀nyí títí dé Baalati-bí à,+ Rámà+ ti gúúsù. Èyí ni ogún ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì nípa àwọn ìdílé wọn.  Ogún àwọn ọmọ Síméónì jẹ́ láti inú ìwọ̀n ìpín àwọn ọmọ Júdà, nítorí pé ìpín àwọn ọmọ Júdà wá pọ̀ jù fún wọn.+ Nítorí náà, àwọn ọmọ Síméónì rí ohun ìní gbà ní àárín ogún+ wọn. 10  Lẹ́yìn èyí, kèké+ kẹta jáde fún àwọn ọmọ Sébúlúnì+ nípa àwọn ìdílé wọn, ààlà ogún wọn sì wá jẹ́ títí dé Sárídì. 11  Ààlà wọn sì gòkè lọ síhà ìwọ̀-oòrùn àti sí Márálà, ó sì lọ dé Dábéṣétì àti dé àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá tí ó wà ní iwájú Jókínéámù.+ 12  Ó sì yí padà láti Sárídì sí ìhà ìlà-oòrùn síhà yíyọ oòrùn dé ojú ààlà Kisiloti-tábórì, ó sì jáde sí Dábérátì,+ ó sì gòkè lọ títí dé Jáfí à. 13  Láti ibẹ̀ ni ó sì ti ré kọjá sí ìhà ìlà-oòrùn síhà yíyọ oòrùn dé Gati-héférì,+ dé Ẹti-kásínì, ó sì jáde sí Rímónì, a sì fi àmì sí i dé Néà. 14  Ààlà náà sì lọ yí i ká ní àríwá dé Hánátónì, ibi tí ó sì dópin sí ni àfonífoj ì  Ifita-élì, 15  àti Kátátì àti Náhálálì àti Ṣímúrónì+ àti Ídálà àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù;+ ìlú ńlá méj ì lá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 16  Èyí ni ogún+ àwọn ọmọ Sébúlúnì nípa àwọn ìdílé+ wọn. Ìwọ̀nyí ni ìlú ńlá náà àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 17  Ísákárì ni kèké kẹrin jáde wá fún, fún àwọn ọmọ Ísákárì+ nípa àwọn ìdílé wọn. 18  Ààlà wọn sì wá dé Jésíréélì+ àti Kẹ́súlótì àti Ṣúnẹ́mù,+ 19  àti Háfáráímù àti Ṣíónì àti Ánáhárátì, 20  àti Rábítì àti Kíṣíónì àti Ébésì, 21  àti Rémétì àti Ẹ́ń-gánímù+ àti Ẹ́ń-hádà àti Bẹti-pásésì. 22  Ààlà náà sì lọ dé Tábórì+ àti Ṣáhásúmà àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì, ibi tí ojú ààlà wọn sì dópin sí ni Jọ́dánì; ìlú ńlá mẹ́rìndínlógún àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 23  Èyí ni ogún ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákárì nípa àwọn ìdílé+ wọn, àwọn ìlú ńlá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 24  Lẹ́yìn náà ni kèké+ karùn-ún jáde wá fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì+ nípa àwọn ìdílé wọn. 25  Ààlà wọn sì wá jẹ́ Hélíkátì+ àti Hálì àti Béténì àti Ákíṣáfù,+ 26  àti Alamélékì àti Ámádì àti Míṣálì.+ Ó sì dé ìhà ìwọ̀-oòrùn, lọ dé Kámẹ́lì+ àti dé Ṣihori-líbínátì, 27  ó sì yí padà síhà yíyọ oòrùn dé Bẹti-dágónì, ó sì dé Sébúlúnì+ àti àfonífoj ì  Ifita-élì ní àríwá, dé Bẹti-émékì àti Néélì, ó sì jáde sí Kábúlù ní apá òsì, 28  àti sí Ébúrónì àti Réhóbù àti Hámónì àti Kánà títí dé Sídónì+ elénìyàn púpọ̀. 29  Ààlà náà sì yí padà sí Rámà àti títí dé Tírè+ ìlú ńlá olódi. Ààlà náà sì yí padà sí Hósà, ibi tí ó sì dópin sí jẹ́ òkun, ní ẹkùn ilẹ̀ Ákísíbù,+ 30  àti Úmà àti Áfékì+ àti Réhóbù;+ ìlú ńlá méj ì lélógún àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 31  Èyí ni ogún ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì nípa àwọn ìdílé+ wọn. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlú ńlá náà àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 32  Àwọn ọmọ Náfútálì+ ni kèké+ kẹfà jáde wá fún, fún àwọn ọmọ Náfútálì nípa àwọn ìdílé wọn. 33  Ààlà wọn sì wá jẹ́ láti Héléf ì, láti ibi igi ńlá ní Sáánánímù+ àti Adami-nékébù àti Jábínéélì títí dé Lákúmì; ibi tí ó sì dópin sí ni Jọ́dánì. 34  Ààlà náà sì yí padà síhà ìwọ̀-oòrùn sí Asinoti-tábórì, ó sì ti ibẹ̀ jáde sí Húkókù, ó sì dé Sébúlúnì+ ní gúúsù, ó sì dé Áṣérì+ ní ìwọ̀-oòrùn àti Júdà+ ní Jọ́dánì síhà yíyọ oòrùn. 35  Àwọn ìlú ńlá olódi náà sì ni Sídíímù, Sérì àti Hémátì,+ Rákátì àti Kínérétì,+ 36  àti Ádámà àti Rámà àti Hásórì,+ 37  àti Kédéṣì+ àti Édíréì àti Ẹ́ń-hásórì, 38  àti Yírónì àti Migidali-élì, Hórémù àti Bẹti-ánátì àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì;+ ìlú ńlá mọ́kàndínlógún àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 39  Èyí ni ogún+ ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfútálì nípa àwọn ìdílé+ wọn, àwọn ìlú ńlá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 40  Ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni kèké+ keje jáde wá fún. 41  Ojú ààlà ogún wọn sì wá jẹ́ Sórà+ àti Éṣítáólì àti Iri-ṣéméṣì, 42  àti Ṣáálábínì+ àti Áíjálónì+ àti Ítílà, 43  àti Élónì àti Tímúnà+ àti Ékírónì,+ 44  àti Élétékè àti Gíbétónì+ àti Báálátì,+ 45  àti Jéhúdù àti Bẹne-bérákì àti Gati-rímónì,+ 46  àti Me-jákónì àti Rákónì, tí ojú ààlà náà sì wà ní iwájú Jópà.+ 47  Ìpínlẹ̀ àwọn ọmọ Dánì sì há+ jù fún wọn. Àwọn ọmọ Dánì sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ bá Léṣémù+ jagun, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú. Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbà á, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pe Léṣémù ní Dánì, ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ Dánì baba ńlá+ wọn. 48  Èyí ni ogún ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì nípa àwọn ìdílé wọn. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlú ńlá náà àti ibi ìtẹ̀dó wọn. 49  Báyìí ni wọ́n parí pípín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ohun ìní nípa àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ogún fún Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì ní àárín wọn. 50  Nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọ́n fún un ní ìlú ńlá tí ó béèrè,+ èyíinì ni, Timunati-sérà,+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ìlú ńlá náà, ó sì ń gbé inú rẹ̀. 51  Ìwọ̀nyí ni àwọn ogún tí Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì àti àwọn olórí àwọn baba ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín+ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní nípa kèké ní Ṣílò+ níwájú Jèhófà, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ Nípa báyìí, wọ́n dẹ́kun pípín ilẹ̀ náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé