Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 17:1-18

17  Kèké+ sì wá wà fún ẹ̀yà Mánásè,+ nítorí òun ni àkọ́bí+ Jósẹ́fù, fún Mákírù+ àkọ́bí Mánásè, baba Gílíádì,+ nítorí ó jẹ́ ọkùnrin ogun;+ Gílíádì+ àti Báṣánì sì wá jẹ́ tirẹ̀.  Kèké sì wá wà fún àwọn ọmọkùnrin Mánásè tí ó ṣẹ́ kù ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdílé wọn, fún àwọn ọmọ Abi-ésérì+ àti àwọn ọmọ Hélékì+ àti àwọn ọmọ Ásíríélì àti àwọn ọmọ Ṣékémù+ àti àwọn ọmọ Héfà àti àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Mánásè, ọmọkùnrin Jósẹ́fù, àwọn ọkùnrin ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdílé wọn.  Ní ti Sélóféhádì,+ ọmọkùnrin Héfà, ọmọkùnrin Gílíádì, ọmọkùnrin Mákírù, ọmọkùnrin Mánásè, òun ni kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin, ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀: Málà àti Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà.+  Nítorí náà, wọ́n wá síwájú Élíásárì+ àlùfáà àti Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì àti àwọn ìjòyè, pé: “Jèhófà ni ó pàṣẹ fún Mósè láti fún wa ní ogún láàárín àwọn arákùnrin wa.”+ Nítorí náà, nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, ó fi ogún fún wọn, láàárín àwọn arákùnrin baba wọn.+  Ìwọ̀n ìpín mẹ́wàá ni ó sì kan Mánásè yàtọ̀ sí ilẹ̀ Gílíádì àti Báṣánì, èyí tí ó wà ní ìhà kej ì  Jọ́dánì;+  nítorí àwọn ọmọbìnrin Mánásè wá jogún láàárín àwọn ọmọkùnrin rẹ̀; ilẹ̀ Gílíádì sì wá di dúkìá àwọn ọmọkùnrin Mánásè tí ó ṣẹ́ kù.  Ààlà Mánásè sì wá jẹ́ láti Áṣérì títí dé Míkímẹ́tátì,+ èyí tí ó wà ní iwájú Ṣékémù,+ ààlà náà sì sún sí apá ọ̀tún, sọ́dọ̀ àwọn olùgbé Ẹ́ń-Tápúà.  Ilẹ̀ Tápúà+ di ti Mánásè, ṣùgbọ́n Tápúà tí ó wà ní ààlà Mánásè jẹ́ ti àwọn ọmọ Éfúráímù.  Ààlà náà sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá ti Kánà, síhà gúúsù sí àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá ti àwọn ìlú ńlá+ Éfúráímù wọ̀nyí, ní àárín àwọn ìlú ńlá Mánásè, ààlà Mánásè sì wà ní àríwá àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá náà, ibi tí ó sì dópin sí jẹ́ òkun.+ 10  Sí ìhà gúúsù ó jẹ́ ti Éfúráímù, àti sí ìhà àríwá ó jẹ́ ti Mánásè, òkun náà sì wá jẹ́ ààlà rẹ̀;+ àti ní àríwá, wọ́n dé Áṣérì àti ní ìlà-oòrùn, wọ́n dé Ísákárì. 11  Mánásè+ sì wá ní ní Ísákárì àti ní Áṣérì Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti Íbíléámù+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Ẹ́ń-dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Mẹ́gídò+ àti àwọn àrọko rẹ̀, mẹ́ta lára àwọn ibi gíga. 12  Àwọn ọmọ Mánásè kò sì lè gba àwọn ìlú ńlá+ wọ̀nyí, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kénáánì ń bá a lọ ní gbígbé ilẹ̀ yìí.+ 13  Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di alágbára,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọmọ Kénáánì sínú òpò+ àfipámúniṣe, wọn kò sì lé wọn kúrò pátápátá.+ 14  Àwọn ọmọ Jósẹ́fù sì ń bá Jóṣúà sọ̀rọ̀, pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé ìpín ẹyọ kan tí a fi kèké yàn àti ìwọ̀n ìpín+ ẹyọ kan ni o fún mi gẹ́gẹ́ bí ogún, nígbà tí ó jẹ́ pé ènìyàn tí ó pọ̀ níye ni mí nítorí ìdí náà pé Jèhófà ti bù kún mi títí di ìsinsìnyí?”+ 15  Látàrí èyí, Jóṣúà wí fún wọn pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ènìyàn tí ó pọ̀ níye, mú ọ̀nà rẹ pọ̀n gòkè lọ sínú igbó, kí o sì ṣán an fún ara rẹ níbẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn Pérísì+ àti àwọn Réfáímù,+ nítorí pé ẹkùn ilẹ̀+ olókè ńláńlá Éfúráímù ti ṣe tóóró jù fún ọ.” 16  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Jósẹ́fù wí pé: “Ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà kò tó fún wa, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ ogun pẹ̀lú dòjé tí a fi irin ṣe sì wà láàárín gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀, àti àwọn tí ó wà ní Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Jésíréélì.”+ 17  Nítorí náà, Jóṣúà sọ èyí fún ilé Jósẹ́fù, fún Éfúráímù àti Mánásè pé: “Ènìyàn tí ó pọ̀ níye ni ìwọ, o sì ní agbára tí ó pọ̀.+ K ì  í ṣe ìpín+ ẹyọ kan ni ó yẹ kí o ní, 18  ṣùgbọ́n ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà yóò di tìrẹ.+ Nítorí igbó ni, ìwọ yóò ṣán an, yóò sì di ibi tí ó dópin sí fún ọ. Nítorí ìwọ yóò lé àwọn ọmọ Kénáánì lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun pẹ̀lú dòjé tí a fi irin ṣe, tí wọ́n sì ní agbára.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé