Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 16:1-10

16  Ìpín+ fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù+ sì jáde wá láti Jọ́dánì+ ní Jẹ́ríkò dé omi Jẹ́ríkò níhà ìlà-oòrùn, aginjù tí ó gòkè láti Jẹ́ríkò lọ wọnú ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Bẹ́tẹ́lì.+  Ó sì lọ láti Bẹ́tẹ́lì tí ó jẹ́ ti Lúsì,+ ó sì ré kọjá ààlà àwọn Áríkì+ ní Átárótì,  ó sì sọ̀ kalẹ̀ síhà ìwọ̀-oòrùn dé ààlà àwọn ọmọ Jáfílétì títí dé ààlà Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀+ àti Gésérì,+ ibi tí ó sì dópin sí jẹ́ òkun.+  Àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù,+ Mánásè àti Éfúráímù,+ sì bẹ̀rẹ̀ sí gba ilẹ̀.+  Ààlà àwọn ọmọ Éfúráímù nípa àwọn ìdílé wọn sì wá jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni, ààlà ogún wọn níhà ìlà-oòrùn sì jẹ́ Ataroti-ádárì,+ títí dé Bẹti-hórónì Òkè;+  ààlà náà sì lọ dé òkun. Míkímẹ́tátì+ wà ní àríwá, ààlà náà sì yí lọ síhà ìlà-oòrùn sí Taanati-ṣílò, ó sì ré kọjá síhà ìlà-oòrùn sí Jánóà.  Ó sì sọ̀ kalẹ̀ láti Jánóà lọ sí Átárótì àti Náárà, ó sì dé Jẹ́ríkò,+ ó sì lọ dé Jọ́dánì.  Láti Tápúà,+ ààlà náà lọ síwájú síhà ìwọ̀-oòrùn sí àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá ti Kánà,+ ibi tí ó sì dópin sí jẹ́ ibi òkun.+ Èyí ni ogún ẹ̀yà àwọn ọmọ Éfúráímù nípa àwọn ìdílé wọn.  Àwọn ọmọ Éfúráímù sì ní àwọn ìlú ńlá+ tí a yà sọ́tọ̀ ní àárín ogún àwọn ọmọ Mánásè, gbogbo àwọn ìlú ńlá náà àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 10  Wọn kò sì lé àwọn ọmọ Kénáánì+ tí ń gbé Gésérì+ lọ, àwọn ọmọ Kénáánì sì ń bá a lọ láti máa gbé láàárín Éfúráímù títí di òní+ yìí, wọ́n sì wá di ẹni tí ó wà lábẹ́ òpò+ àfipámúniṣe ti ìsìnrú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé