Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 15:1-63

15  Ìpín+ ẹ̀yà àwọn ọmọ Júdà nípa ìdílé wọn sì wá jẹ́ títí dé ààlà Édómù,+ aginjù Síínì,+ dé Négébù+ ní ìpẹ̀kun rẹ̀ ti ìhà gúúsù.  Ààlà wọn ní ìhà gúúsù sì jẹ́ láti ìkángun Òkun Iyọ̀,+ láti ìyawọ̀ omi tí ó dojú kọ ìhà gúúsù.  Ó sì lọ síhà gúúsù dé ìgòkè Ákírábímù,+ ó sì ré kọjá dé Síínì,+ ó sì gòkè lọ láti gúúsù Kadeṣi-bání à,+ ó sì ré kọjá sí Hésírónì, ó sì gòkè lọ dé Ádáárì, ó sì lọ yí ká dé Káríkà.  Ó sì kọjá lọ sí Ásímónì,+ ó sì lọ sí àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì;+ ibi tí ààlà náà dópin sí sì jẹ́ òkun. Èyí wá jẹ́ ààlà wọn ní ìhà gúúsù.  Ààlà ti ìhà ìlà-oòrùn sì jẹ́ Òkun Iyọ̀ títí dé ìpẹ̀kun Jọ́dánì, ààlà igun ìhà àríwá sì wà ní ìyawọ̀ omi òkun, ní ìpẹ̀kun Jọ́dánì.+  Ààlà náà sì gòkè lọ dé Bẹti-hógílà,+ ó sì ré kọjá ní àríwá Bẹti-árábà,+ ààlà náà sì gòkè lọ dé ibi òkúta Bóhánì+ ọmọkùnrin Rúbẹ́nì.  Ààlà náà sì gòkè lọ dé Débírì níbi pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Ákórì,+ ó sì yí lọ síhà àríwá sí Gílígálì,+ èyí tí ó wà ní iwájú ìgòkè Ádúmímù, èyí tí ó jẹ́ gúúsù àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá; ààlà náà sì ré kọjá sí ibi omi Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì,+ ibi tí ó dópin sí sì jẹ́ Ẹ́ń-rógélì.+  Ààlà náà sì gòkè lọ dé àfonífoj ì  ọmọ Hínómù,+ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, èyíinì ni, Jerúsálẹ́mù;+ ààlà náà sì gòkè lọ dé orí òkè ńlá tí ó dojú kọ àfonífoj ì  Hínómù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, èyí tí ó wà ní ìkángun pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Réfáímù+ ní ìhà àríwá.  A sì sàmì sí ààlà náà láti orí òkè ńlá náà dé ibi ìsun omi Néfítóà,+ ó sì lọ dé àwọn ìlú ńlá ti Òkè Ńlá Éfúrónì; a sì sàmì sí ààlà dé Báálà,+ èyíinì ni, Kiriati-jéárímù.+ 10  Ààlà náà sì yí lọ láti Báálà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn dé Òkè Ńlá Séírì, ó sì ré kọjá sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Ńlá Jéárímù ní àríwá, èyíinì ni, Kẹ́sálónì; ó sì sọ̀ kalẹ̀ dé Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ ó sì ré kọjá sí Tímúnà.+ 11  Ààlà náà sì lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Ékírónì+ níhà àríwá, a sì sàmì sí ààlà náà dé Ṣíkẹ́rónì, ó sì ré kọjá Òkè Ńlá Báálà, ó sì lọ sí Jábínéélì; ibi tí ààlà náà dópin sí sì jẹ́ òkun. 12  Ààlà ti ìwọ̀-oòrùn sì wà ní Òkun Ńlá+ àti ilẹ̀ èbúté rẹ̀. Èyí ni ààlà náà yí ká, fún àwọn ọmọ Júdà nípa àwọn ìdílé wọn. 13  Kálébù+ ọmọkùnrin Jéfúnè ni ó sì fi ìpín fún ní àárín àwọn ọmọ Júdà nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà fún Jóṣúà, èyíinì ni, Kiriati-áríbà, (Áríbà náà ni baba Ánákì), èyíinì ni, Hébúrónì.+ 14  Nítorí náà, Kálébù lé àwọn ọmọ Ánákì+ mẹ́ta kúrò níbẹ̀, èyíinì ni, Ṣéṣáì+ àti Áhímánì àti Tálímáì,+ àwọn tí a bí fún Ánákì.+ 15  Ó sì gòkè láti ibẹ̀ tọ àwọn olùgbé Débírì+ lọ. (Wàyí o, orúkọ Débírì ṣáájú ìgbà yẹn ni Kiriati-séférì.)+ 16  Kálébù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọlu Kiriati-séférì tí ó sì gbà á, dájúdájú èmi yóò fi Ákúsà+ ọmọbìnrin mi fún un ṣe aya.” 17  Látàrí ìyẹn, Ótíníẹ́lì+ ọmọkùnrin Kénásì,+ arákùnrin Kálébù, gbà á. Nítorí náà, ó fi Ákúsà+ ọmọbìnrin rẹ̀ fún un ṣe aya. 18  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sí ilé, ó ń ru ọmọkùnrin náà lọ́kàn sókè ṣáá pé kí ó béèrè pápá lọ́wọ́ baba òun. Lẹ́yìn náà ni ọmọbìnrin náà pàtẹ́wọ́ nígbà tí ó wà lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Látàrí èyí, Kálébù wí fún ọmọbìnrin náà pé: “Kí ni o ń fẹ́?”+ 19  Bẹ́ẹ̀ ni òun wí pé: “Fún mi ní ìbùkún, nítorí ilẹ̀ kan ní gúúsù ni ìwọ fún mi, kí o sì fún mi ní Guloti-máímù.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì Ìsàlẹ̀.+ 20  Èyí ni ogún+ ẹ̀yà àwọn ọmọ Júdà+ nípa àwọn ìdílé wọn. 21  Àwọn ìlú ńlá tí ó wà ní ìkángun ẹ̀yà àwọn ọmọ Júdà níhà ààlà Édómù+ ní gúúsù sì jẹ́ Kábúséélì+ àti Édérì àti Jágúrì, 22  àti Kínà àti Dímónà àti Ádádà, 23  àti Kédéṣì àti Hásórì àti Ítínánì, 24  Sífù àti Télémù+ àti Béálótì, 25  àti Hasori-hádátà àti Kerioti-hésírónì, èyíinì ni, Hásórì, 26  Ámámù àti Ṣémà àti Móládà,+ 27  àti Hasari-gádà àti Hẹ́ṣímónì àti Bẹti-pélétì,+ 28  àti Hasari-ṣúálì+ àti Bíá-ṣébà+ àti Bisiotáyà, 29  Báálà+ àti Ímù àti Ésémù,+ 30  àti Élítóládì àti Kẹ́sílì àti Hóómà,+ 31  àti Síkílágì+ àti Mádímánà àti Sánsánà, 32  àti Lẹ́báótì àti Ṣílíhímù àti Áyínì+ àti Rímónì;+ gbogbo ìlú ńlá náà jẹ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 33  Ní Ṣẹ́fẹ́là,+ Éṣítáólì+ àti Sórà+ àti Áṣínà ń bẹ, 34  àti Sánóà+ àti Ẹ́ń-gánímù, Tápúà àti Énámù, 35  Jámútì+ àti Ádúlámù,+ Sókóhì+ àti Ásékà,+ 36  àti Ṣááráímù+ àti Ádítáímù àti Gédérà àti Gédérótáímù; àwọn ìlú ńlá mẹ́rìnlá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 37  Sénánì àti Hádáṣà àti Migidali-gádì, 38  àti Díléánì àti Mísípè àti Jókítéélì, 39  Lákíṣì+ àti Bósíkátì+ àti Ẹ́gílónì,+ 40  àti Kábónì àti Lámámù àti Kítílíṣì, 41  àti Gédérótì, Bẹti-dágónì àti Náámà àti Mákédà;+ àwọn ìlú ńlá mẹ́rìndínlógún àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 42  Líbínà+ àti Étérì+ àti Áṣánì, 43  àti Ífítà àti Áṣínà àti Nésíbù, 44  àti Kéílà+ àti Ákísíbù+ àti Máréṣà;+ àwọn ìlú ńlá mẹ́sàn-án àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 45  Ékírónì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn ibi ìtẹ̀dó rẹ̀. 46  Láti Ékírónì sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, gbogbo ohun tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Áṣídódì àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 47  Áṣídódì,+ àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn ibi ìtẹ̀dó rẹ̀; Gásà,+ àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn ibi ìtẹ̀dó rẹ̀, dé àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì àti Òkun Ńlá àti ẹkùn ilẹ̀ tí ó wà ní tòsí.+ 48  Àti ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, Ṣámírù àti Játírì+ àti Sókóhì, 49  àti Dánà àti Kiriati-sánà, èyíinì ni, Débírì, 50  àti Ánábù àti Éṣítémò+ àti Ánímù, 51  àti Góṣénì+ àti Hólónì àti Gílò;+ àwọn ìlú ńlá mọ́kànlá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 52  Árábù àti Dúmà àti Éṣánì, 53  àti Jánímù àti Bẹti-tápúà àti Áfékà, 54  àti Húmítà àti Kiriati-ábà, èyíinì ni, Hébúrónì+ àti Síórì; ìlú ńlá mẹ́sàn-án àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 55  Máónì,+ Kámẹ́lì àti Sífù+ àti Jútà, 56  àti Jésíréélì àti Jókídéámù àti Sánóà, 57  Kénì, Gíbí à àti Tímúnà;+ àwọn ìlú ńlá mẹ́wàá àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 58  Hálíhúlù, Bẹti-súrì àti Gédórì, 59  àti Máárátì àti Bẹti-ánótì àti Élítékónì; àwọn ìlú ńlá mẹ́fà àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 60  Kiriati-báálì,+ èyíinì ni, Kiriati-jéárímù+ àti Rábà; ìlú ńlá méj ì  àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 61  Ní aginjù, Bẹti-árábà,+ Mídínì àti Sékákà, 62  àti Níbúṣánì àti Ìlú Ńlá Iyọ̀ àti Ẹ́ń-gédì;+ ìlú ńlá mẹ́fà àti àwọn ibi ìtẹ̀dó wọn. 63  Ní ti àwọn ará Jébúsì+ tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù,+ àwọn ọmọ Júdà kò lè lé wọn lọ;+ àwọn ará Jébúsì sì ń bá a lọ láti máa gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Júdà ní Jerúsálẹ́mù títí di òní yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé