Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 13:1-33

13  Wàyí o, Jóṣúà ti darúgbó, ó sì pọ̀ ní ọdún.+ Nítorí náà, Jèhófà wí fún un pé: “Ìwọ alára ti dàgbà, o sì ti pọ̀ ní ọdún, àti pé, ní ìwọ̀n púpọ̀ gan-an, ilẹ̀ ṣì ṣẹ́ kù láti gbà.+  Ilẹ̀ tí ó ṣì ṣẹ́ kù+ nìyí: gbogbo àwọn ẹkùn ilẹ̀ Filísínì+ àti gbogbo ará Géṣúrì+  (láti ẹ̀ka Náílì tí ó wà ní iwájú Íjíbítì àti títí dé ojú ààlà Ékírónì níhà àríwá,+ tí a ṣírò pé ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Kénáánì);+ àwọn olúwa+ alájùmọ̀ṣepọ̀ márààrùn-ún ti Filísínì, àwọn ará Gásà+ àti àwọn ará Áṣídódì,+ àwọn ará Áṣíkẹ́lónì,+ àwọn ará Gátì+ àti àwọn ará Ékírónì;+ àti àwọn Áfímù.+  Níhà gúúsù ní gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì; àti Méárà, èyí tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Sídónì,+ títí dé Áfékì, títí dé ojú ààlà àwọn Ámórì;  àti ilẹ̀ àwọn ará Gébálì+ àti gbogbo Lẹ́bánónì níhà yíyọ oòrùn, láti Baali-gádì+ ní ìsàlẹ̀ Òkè Ńlá Hámónì títí dé àtiwọ Hámátì;+  gbogbo olùgbé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, láti Lẹ́bánónì+ dé Misirefoti-máímù,+ gbogbo àwọn ọmọ Sídónì;+ èmi fúnra mi yóò lé wọn kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ K ì kì pé kí o jẹ́ kí ó bọ́ sọ́wọ́ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ.+  Wàyí o, pín ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ogún fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.”+  Pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà kej ì  ni àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì ti gba ogún tí Mósè fi fún wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì níhà ìlà-oòrùn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ti fi fún wọn,+  láti Áróérì,+ èyí tí ó wà ní bèbè àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì+ àti ìlú ńlá tí ó wà ní àárín àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá, àti gbogbo ilẹ̀ títẹ́ pẹrẹsẹ Médébà+ títí dé Díbónì;+ 10  àti gbogbo àwọn ìlú ńlá ti Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó jọba ní Hẹ́ṣíbónì, títí dé ojú ààlà àwọn ọmọ Ámónì;+ 11  àti Gílíádì àti ìpínlẹ̀ àwọn ará Géṣúrì+ àti àwọn ará Máákátì àti gbogbo Òkè Ńlá Hámónì+ àti gbogbo Báṣánì+ títí dé Sálékà;+ 12  gbogbo ilẹ̀ ọba ti Ógù+ ní Báṣánì, ẹni tí ó jọba ní Áṣítárótì àti ní Édíréì+—òun ni ẹni tí ó ṣẹ́ kù lára ohun tí ó ṣẹ́ kù lára Réfáímù+—Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n, ó sì lé+ wọn kúrò.+ 13  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sì lé àwọn ará Géṣúrì+ àti àwọn ará Máákátì kúrò, ṣùgbọ́n Géṣúrì àti Máákátì ń bá a nìṣó láti máa gbé ní àárín Ísírẹ́lì títí di òní yìí. 14  K ì kì ẹ̀yà àwọn ọmọ Léf ì ni kò fún ní ogún.+ Ọrẹ ẹbọ tí a fi iná+ sun sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún+ wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.+ 15  Mósè sì fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ẹ̀bùn nípa ìdílé wọn, 16  ìpínlẹ̀ náà sì wá di tiwọn láti Áróérì,+ èyí tí ó wà ní bèbè àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì, àti ìlú ńlá tí ó wà ní àárín àfonífoj ì  olójú ọ̀gbàrá, àti gbogbo ilẹ̀ títẹ́ pẹrẹsẹ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Médébà;+ 17  Hẹ́ṣíbónì+ àti gbogbo àwọn ìlú+ ibẹ̀ tí ó wà lórí ilẹ̀ títẹ́ pẹrẹsẹ, Díbónì+ àti Bamoti-báálì+ àti Bẹti-baali-méónì,+ 18  àti Jáhásì+ àti Kédémótì+ àti Mẹ́fáátì,+ 19  àti Kíríátáímù+ àti Síbúmà+ àti Sereti-ṣáhà ní òkè ńlá ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀, 20  àti Bẹti-péórù àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà+ àti Bẹti-jẹ́ṣímótì,+ 21  àti gbogbo àwọn ìlú ńlá ilẹ̀ títẹ́ pẹrẹsẹ+ àti gbogbo ilẹ̀ ọba ti Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó jọba ní Hẹ́ṣíbónì,+ tí Mósè kọlù,+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Mídíánì, Éf ì àti Rékémù àti Súúrì àti Húrì àti Rébà,+ tí í ṣe mọ́gàjí Síhónì, tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ náà. 22  Báláámù ọmọkùnrin Béórì,+ woṣẹ́woṣẹ́,+ sì ni ẹni tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa pẹ̀lú àwọn tí wọ́n pa. 23  Jọ́dánì sì wá di ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì; àti pé èyí, gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀, jẹ́ ogún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ nípa ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn ìlú ńlá àti ibi ìtẹ̀dó wọn. 24  Síwájú sí i, Mósè fi ẹ̀bùn fún ẹ̀yà Gádì, àwọn ọmọ Gádì nípa ìdílé wọn,+ 25  ìpínlẹ̀ wọn sì wá jẹ́ Jásérì+ àti gbogbo àwọn ìlú ńlá Gílíádì+ àti ààbọ̀ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì+ títí dé Áróérì,+ èyí tí ó wà níwájú Rábà;+ 26  àti láti Hẹ́ṣíbónì+ dé Ramati-mísípè àti Bẹ́tónímù àti láti Máhánáímù+ títí de ojú ààlà Débírì;+ 27  àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Bẹti-hárámù+ àti Bẹti-nímírà+ àti Súkótù+ àti Sáfónì, ìyókù ilẹ̀ ọba ti Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì,+ tí Jọ́dánì jẹ́ ojú ààlà títí dé ìkángun òkun Kínérétì+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì níhà ìlà-oòrùn. 28  Èyí ni ogún àwọn ọmọ Gádì+ nípa ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn ìlú ńlá àti ibi ìtẹ̀dó wọn. 29  Síwájú sí i, Mósè fi ẹ̀bùn fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ó sì wá jẹ́ ti ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè nípa ìdílé wọn.+ 30  Ìpínlẹ̀ wọn sì wá jẹ́ láti Máhánáímù,+ gbogbo Báṣánì, gbogbo ilẹ̀ ọba ti Ógù ọba Báṣánì,+ àti gbogbo abúlé àgọ́ Jáírì+ tí ó wà ní Báṣánì, ọgọ́ta ìlú. 31  Ààbọ̀ Gílíádì àti Áṣítárótì+ àti Édíréì,+ àwọn ìlú ńlá ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì, sì bọ́ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Mákírù,+ ọmọkùnrin Mánásè, sọ́dọ̀ ààbọ̀ àwọn ọmọ Mákírù nípa ìdílé wọn. 32  Ìwọ̀nyí ni ohun tí Mósè mú kí wọ́n jogún, lórí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì, ní Jẹ́ríkò, níhà ìlà-oòrùn.+ 33  Ṣùgbọ́n ẹ̀yà àwọn ọmọ Léf ì ni Mósè kò fún ní ogún.+ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé