Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 11:1-23

11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Jábínì ọba Hásórì gbọ́ nípa rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ránṣẹ́ sí Jóbábù ọba Mádónì+ àti sí ọba Ṣímúrónì àti sí ọba Ákíṣáfù,+  àti sí àwọn ọba tí ó wà ní ìhà àríwá ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá àti ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ gúúsù Kínérétì+ àti ní Ṣẹ́fẹ́là+ àti lórí ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá Dórì+ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn,  àwọn ọmọ Kénáánì+ ní ìhà ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti àwọn Ámórì+ àti àwọn ọmọ Hétì+ àti àwọn Pérísì+ àti àwọn ará Jébúsì+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá àti àwọn Híf ì+ ní ìsàlẹ̀ Hámónì+ ní ilẹ̀ Mísípà.+  Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jáde lọ, àwọn àti gbogbo ibùdó wọn pẹ̀lú wọn, àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun nítorí tí wọ́n jẹ́ ògìdìgbó,+ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin+ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun.  Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí pàdé pọ̀ nípasẹ̀ àdéhùn, tí wọ́n sì dó pà pọ̀ síbi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà.+  Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Má fòyà nítorí wọn,+ nítorí ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo wọn fún Ísírẹ́lì ní pípa. Àwọn ẹṣin wọn ni ìwọ yóò já ní pátì,+ ìwọ yóò sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn nínú iná.”+  Jóṣúà àti gbogbo ènìyàn ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì wá gbéjà kò wọ́n lójij ì  lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi Mérómù, wọ́n sì rọ́ lù wọ́n.  Nígbà náà ni Jèhófà fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n, wọ́n sì ń lépa wọn títí dé Sídónì+ elénìyàn púpọ̀ àti Misirefoti-máímù+ àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífoj ì  Mísípè+ níhà ìlà-oòrùn; wọ́n sì ń kọlù wọ́n ṣáá títí wọn kò fi jẹ́ kí olùlàájá kan ṣẹ́ kù lára wọn.+  Lẹ́yìn náà, Jóṣúà ṣe sí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti wí fún un: àwọn ẹṣin wọn ni ó já ní pátì,+ ó sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn nínú iná.+ 10  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jóṣúà yíjú padà ní àkókò yẹn,+ ó sì gba Hásórì;+ ọba ibẹ̀ ni ó sì fi idà+ ṣá balẹ̀, nítorí pé ṣáájú ìyẹn, Hásórì ni olórí gbogbo ìjọba wọ̀nyí. 11  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kọlu olúkúlùkù ọkàn tí ó wà ní ibẹ̀, ní yíyà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Kò sí ohun eléèémí kankan rárá tí ó ṣẹ́ kù,+ ó sì sun Hásórì nínú iná. 12  Gbogbo ìlú ńlá àwọn ọba wọ̀nyí àti gbogbo ọba wọn ni Jóṣúà gbà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kọlù wọ́n.+ Ó yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ti pa á láṣẹ.+ 13  K ì kì gbogbo ìlú ńlá tí ó dúró lórí òkìtì tiwọn ni Ísírẹ́lì kò fi iná sun, àyàfi Hásórì nìkan ṣoṣo tí Jóṣúà fi iná sun. 14  Gbogbo ohun ìfiṣèjẹ ìlú ńlá wọ̀nyí àti ẹran agbéléjẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì piyẹ́ fún ara wọn.+ K ì kì gbogbo ìran ènìyàn ni wọ́n fi ojú idà kọlù títí wọ́n fi pa wọ́n rẹ́ ráúráú.+ Wọn kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ti ń mí ṣẹ́ kù.+ 15  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Mósè pàṣẹ fún Jóṣúà,+ bẹ́ẹ̀ sì ni Jóṣúà ṣe. Kò mú ọ̀rọ̀ kan kúrò nínú gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún Mósè.+ 16  Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí gba gbogbo ilẹ̀ yìí, ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá àti gbogbo Négébù+ àti gbogbo ilẹ̀ Góṣénì+ àti Ṣẹ́fẹ́là+ àti Árábà+ àti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Ísírẹ́lì àti Ṣẹ́fẹ́là+ ibẹ̀, 17  láti Òkè Ńlá Hálákì,+ èyí tí ó lọ dé Séírì+ àti títí dé Baali-gádì+ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífoj ì  Lẹ́bánónì ní ìsàlẹ̀ Òkè Ńlá Hámónì,+ ó sì kó gbogbo ọba wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n, ó sì ń fi ikú pa wọ́n.+ 18  Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni Jóṣúà fi bá gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ja ogun. 19  Kò sì wá sí ìlú ńlá kankan tí ó wá àlàáfí à pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí kò ṣe àwọn Híf ì+ tí ń gbé Gíbéónì.+ Gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n fi ogun gbà.+ 20  Nítorí pé ó jẹ́ ipa ọ̀nà Jèhófà láti jẹ́ kí ọkàn-àyà wọn di alágídí+ láti polongo ogun lòdì sí Ísírẹ́lì, kí ó bàa lè yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun, kí wọ́n má bàa lè rí àfiyèsí olójúrere kankan gbà,+ ṣùgbọ́n kí ó bàa lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.+ 21  Síwájú sí i, ní àkókò yẹn gan-an, Jóṣúà lọ, ó sì ké àwọn Ánákímù+ kúrò ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, láti Hébúrónì, láti Débírì, láti Ánábù+ àti láti gbogbo ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Júdà àti láti gbogbo ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Ísírẹ́lì.+ Àwọn pa pọ̀ pẹ̀lú ìlú ńlá wọn ni Jóṣúà yà sọ́tọ̀ fún ìparun.+ 22  Kò ku Ánákímù kankan ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. K ì kì ní Gásà,+ ní Gátì+ àti ní Áṣídódì+ ni wọ́n ṣẹ́ kù sí.+ 23  Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí fún Mósè,+ Jóṣúà sì wá fi í fún Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà+ wọn. Ilẹ̀ náà sì bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu ogun.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé