Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóṣúà 10:1-43

10  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Adoni-sédékì ọba Jerúsálẹ́mù gbọ́ pé Jóṣúà ti gba Áì,+ tí ó sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun+ lẹ́yìn náà, pé gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jẹ́ríkò+ àti ọba+ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí Áì àti ọba+ rẹ̀, àti pé àwọn olùgbé Gíbéónì ti wá àlàáfí à pẹ̀lú Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì ń bá a lọ láti wà ní àárín wọn,  àyà fò ó gidigidi,+ nítorí pé Gíbéónì jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó tóbi, ó dà bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá ọba, àti nítorí pé ó tóbi ju Áì+ lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ sì jẹ́ àwọn alágbára ńlá.  Nítorí náà, Adoni-sédékì ọba Jerúsálẹ́mù+ ránṣẹ́ sí Hóhámù ọba Hébúrónì+ àti sí Pírámù ọba Jámútì+ àti sí Jáfí à ọba Lákíṣì+ àti sí Débírì ọba Ẹ́gílónì,+ pé,  “Gòkè wá sọ́dọ̀ mi, kí o sì ràn mi lọ́wọ́, kí a lè kọlu Gíbéónì, nítorí pé ó ti wá àlàáfí à pẹ̀lú Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+  Látàrí èyí, wọ́n kóra jọpọ̀, wọ́n sì gòkè lọ, àwọn ọba Ámórì+ márùn-⁠ún, ọba Jerúsálẹ́mù, ọba Hébúrónì, ọba Jámútì, ọba Lákíṣì, ọba Ẹ́gílónì, àwọn wọ̀nyí àti gbogbo ibùdó wọn sì tẹ̀ síwájú láti dó ti Gíbéónì láti bá a jagun.  Látàrí ìyẹn, àwọn ọkùnrin Gíbéónì ránṣẹ́ sí Jóṣúà ní ibùdó Gílígálì,+ pé: “Má ṣe dẹ ọwọ́ rẹ lọ́dọ̀ àwọn ẹrú rẹ.+ Gòkè wá sọ́dọ̀ wa kíákíá, kí o sì gbà wá là, kí o sì ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Ámórì tí ń gbé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti kóra jọpọ̀ láti gbéjà kò wá.”  Nítorí náà, Jóṣúà gòkè lọ láti Gílígálì, òun àti gbogbo ènìyàn ogun pẹ̀lú rẹ̀+ àti gbogbo akíkanjú ọkùnrin alágbára ńlá.+  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Jóṣúà pé: “Má fòyà wọn,+ nítorí mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+ K ì yóò sí ọkùnrin kan nínú wọn tí yóò dìde sí ọ.”+  Jóṣúà sì wá gbéjà kò wọ́n lójij ì . Ó sì gòkè lọ láti Gílígálì ní òru mọ́jú. 10  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀ níwájú Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n ní ìpakúpa rẹpẹtẹ ní Gíbéónì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa wọn lọ ní gbígba ti ìgòkè Bẹti-hórónì, wọ́n sì pa wọ́n títí dé Ásékà+ àti Mákédà.+ 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọn ti ń sá lọ kúrò níwájú Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì wà níbi ìsọ̀kalẹ̀ Bẹti-hórónì, Jèhófà sọ àwọn òkútà+ ńlá lù wọ́n títí dé Ásékà láti ọ̀run, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kú. Àwọn tí ó kú láti ọwọ́ òkúta yìnyín sì pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa lọ. 12  Nígbà náà ni Jóṣúà bẹ̀rẹ̀ sí bá Jèhófà sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ tí Jèhófà jọ̀wọ́ àwọn Ámórì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì ń bá a lọ láti sọ lójú Ísírẹ́lì pé:“Oòrùn,+ dúró sójú kan lórí Gíbéónì,+Àti, òṣùpá, lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Áíjálónì.”+ 13  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, oòrùn dúró sójú kan, òṣùpá sì dúró jẹ́ẹ́, títí orílẹ̀-èdè náà fi lè gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.+ A kò ha kọ ọ́ sínú ìwé Jáṣárì?+ Oòrùn sì dúró jẹ́ẹ́ ní àárín ojú ọ̀run, kò sì yára láti wọ̀ fún nǹkan bí ọjọ́ kan gbáko.+ 14  Kò sì sí ọjọ́ kankan tí ó tí ì dà bí ìyẹn, yálà ṣáájú rẹ̀ tàbí lẹ́yìn rẹ̀, ní ti pé Jèhófà fetí sí ohùn ènìyàn,+ nítorí Jèhófà ni ó ń jà fún Ísírẹ́lì.+ 15  Lẹ́yìn ìyẹn, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì padà sí ibùdó ní Gílígálì.+ 16  Láàárín àkókò náà, àwọn ọba márùn-⁠ún wọ̀nyí sá lọ,+ wọ́n sì lọ fi ara wọn pa mọ́ sínú hòrò kan ní Mákédà.+ 17  Lẹ́yìn náà ni a ròyìn fún Jóṣúà, pé: “Àwọn ọba márààrùn-⁠ún náà ni a rí tí wọ́n fara pa mọ́ sínú hòrò kan ní Mákédà.”+ 18  Látàrí ìyẹn, Jóṣúà wí pé: “Ẹ yí àwọn òkúta ńlá sí ẹnu hòrò náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin tì í láti ṣọ́ wọn. 19  Ní tiyín, ẹ má ṣe dúró jẹ́ẹ́. Ẹ lépa àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì kọlù wọ́n láti ìhà ẹ̀yìn.+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n wọnú àwọn ìlú ńlá wọn, nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín ti fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”+ 20  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì parí pípa wọ́n ní ìpakúpa rẹpẹtẹ, títí àwọn wọ̀nyí fi wá sí òpin wọn,+ àwọn tí ó sì là á já lára wọn sá àsálà, wọ́n sì wọnú àwọn ìlú ńlá olódi,+ 21  gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí padà sí ibùdó, sọ́dọ̀ Jóṣúà, ní Mákédà ní àlàáfí à. Kò sí ènìyàn kankan tí ó fi ìháragàgà yọ ahọ́n rẹ̀ lòdì sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 22  Nígbà náà ni Jóṣúà wí pé: “Ẹ ṣí ẹnu hòrò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba márààrùn-⁠ún wọ̀nyí jáde láti inú hòrò náà tọ̀ mí wá.” 23  Látàrí ìyẹn, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú àwọn ọba márààrùn-⁠ún wọ̀nyí, ọba Jerúsálẹ́mù,+ ọba Hébúrónì,+ ọba Jámútì, ọba Lákíṣì,+ ọba Ẹ́gílónì,+ jáde tọ̀ ọ́ wá láti inú hòrò náà. 24  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n mú àwọn ọba wọ̀nyí jáde tọ Jóṣúà wá, Jóṣúà bẹ̀rẹ̀ sí pe gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì, ó sì wí fún àwọn ọ̀gágun àwọn ọkùnrin ogun tí ó bá a lọ pé: “Ẹ wá síwájú. Ẹ gbé ẹsẹ̀ yín lé ẹ̀yìn ọrùn àwọn ọba+ yìí.” Nítorí náà, wọ́n wá síwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ wọn lé ẹ̀yìn ọrùn+ wọn. 25  Jóṣúà sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Ẹ má fòyà, tàbí kí ẹ jáyà.+ Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára, nítorí báyìí ni Jèhófà yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí ẹ ń bá jagun.”+ 26  Lẹ́yìn ìyẹn, Jóṣúà bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n, ó sì fi ikú pa wọ́n, ó sì gbé wọn kọ́ sórí òpó igi márùn-⁠ún, wọ́n sì ń bá a lọ láti wà ní gbígbé kọ́ sórí òpó igi títí di ìrọ̀lẹ́.+ 27  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní àkókò wíwọ̀ oòrùn, Jóṣúà pàṣẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ wọ́n sínú hòrò tí wọ́n ti fi ara wọn pa mọ́ sí. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé àwọn òkúta ńlá sí ẹnu hòrò náà⁠—títí di òní yìí gan-⁠an. 28  Jóṣúà sì gba Mákédà+ ní ọjọ́ náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kọlù ú. Ní ti ọba ibẹ̀, ó ya òun àti olúkúlùkù ọkàn tí ń bẹ níbẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Kò jẹ́ kí olùlàájá kankan ṣẹ́ kù. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí ọba Mákédà,+ gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò. 29  Lẹ́yìn náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Mákédà lọ sí Líbínà, wọ́n sì bá Líbínà+ jagun. 30  Nítorí náà, Jèhófà fi ibẹ̀ àti ọba ibẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ibẹ̀ àti olúkúlùkù ọkàn tí ń bẹ níbẹ̀. Wọn kò jẹ́ kí olùlàájá kankan ṣẹ́ kù sínú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ọba ibẹ̀, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò.+ 31  Lẹ́yìn èyí, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Líbínà lọ sí Lákíṣì,+ wọ́n dó tì í, wọ́n sì jagun níbẹ̀. 32  Nítorí náà, Jèhófà fi Lákíṣì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbà á ní ọjọ́ kej ì , wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà+ kọlu ibẹ̀ àti olúkúlùkù ọkàn tí ń bẹ níbẹ̀, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe sí Líbínà. 33  Nígbà náà ni Hórámù ọba Gésérì+ gòkè lọ láti ran Lákíṣì lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà kọlu òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ títí kò fi ṣẹ́ olùlàájá kan kù fún un.+ 34  Lẹ́yìn náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lákíṣì lọ sí Ẹ́gílónì,+ wọ́n sì dó tì í, tí wọ́n sì bá a jagun. 35  Wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ yẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kọlu ibẹ̀, wọ́n sì ya olúkúlùkù ọkàn tí ń bẹ níbẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun ní ọjọ́ yẹn, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe sí Lákíṣì.+ 36  Lẹ́yìn náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì gòkè láti Ẹ́gílónì lọ sí Hébúrónì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jagun. 37  Wọ́n sì gbà á, wọ́n sì lọ fi ojú idà kọlu ibẹ̀ àti ọba ibẹ̀ àti gbogbo ìlú ibẹ̀ àti olúkúlùkù ọkàn ti ń bẹ níbẹ̀. Kò jẹ́ kí olùlàájá kankan ṣẹ́ kù, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ṣe sí Ẹ́gílónì. Bẹ́ẹ̀ ni ó ya ibẹ̀ àti olúkúlùkù ọkàn tí ń bẹ̀ níbẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun.+ 38  Níkẹyìn, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ padà wá sí Débírì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jagun. 39  Ó sì gba ibẹ̀ àti ọba ibẹ̀ àti gbogbo ìlú ibẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì ya olúkúlùkù ọkàn tí ń bẹ níbẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Kò jẹ́ kí olùlàájá kankan ṣẹ́ kù.+ Gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Hébúrónì, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí Débírì àti ọba ibẹ̀, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ṣe sí Líbínà àti ọba ibẹ̀.+ 40  Jóṣúà sì ń bá a lọ láti kọlu gbogbo ilẹ̀ ẹkùn ilẹ̀+ olókè ńláńlá náà àti Négébù+ àti Ṣẹ́fẹ́là+ àti àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́+ àti gbogbo ọba ibẹ̀. Kò jẹ́ kí olùlàájá kankan ṣẹ́ kù, ohun gbogbo tí ó sì ń mí+ ni ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun,+ gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti pàṣẹ.+ 41  Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n láti Kadeṣi-bání à+ títí dé Gásà+ àti gbogbo ilẹ̀ Góṣénì+ àti títí dé Gíbéónì.+ 42  Jóṣúà sì gba gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní ìgbà kan náà,+ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ẹni tí ǹ jà fún Ísírẹ́lì.+ 43  Lẹ́yìn ìyẹn, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì padà sí ibùdó ní Gílígálì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé