Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóṣúà 1:1-18

1  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pé Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Jóṣúà+ ọmọkùnrin Núnì, òjíṣẹ́+ Mósè pé:  “Mósè ìránṣẹ́ mi ti kú;+ dìde nísinsìnyí, kí o sì sọdá Jọ́dánì yìí, ìwọ àti gbogbo ènìyàn yìí, sórí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn, fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Ibi gbogbo tí àtẹ́lẹsẹ̀ yín yóò tẹ̀, ẹ̀yin ni èmi yóò fi í fún dájúdájú, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Mósè.+  Láti aginjù àti Lẹ́bánónì yìí títí dé odò ńlá náà, Odò Yúfírétì, èyíinì ni, gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì,+ àti títí dé Òkun Ńlá síhà wíwọ̀ oòrùn ni ìpínlẹ̀ yín yóò jẹ́.+  Ẹnikẹ́ni kì yóò mú ìdúró gbọn-⁠in gbọn-⁠in níwájú rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.+ Gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí mo ti wà pẹ̀lú Mósè ni èmi yóò ṣe wà pẹ̀lú rẹ.+ Èmi kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá.+  Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ nítorí ìwọ ni yóò mú kí àwọn ènìyàn yìí jogún+ ilẹ̀ tí mo búra fún àwọn baba ńlá wọn láti fi fún wọn.+  “K ì kì pé kí o jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi láti máa kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún ọ.+ Má yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ kí o lè máa hùwà ọgbọ́n níbi gbogbo tí o bá lọ.+  Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ,+ kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀;+ nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.+  Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí?+ Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà,+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.”+ 10  Jóṣúà sì bẹ̀rẹ̀ sí pàṣẹ fún àwọn onípò àṣẹ láàárín àwọn ènìyàn náà pé: 11  “Ẹ la àárín ibùdó kọjá, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà, pé, ‘Ẹ ṣètò àwọn ìpèsè oúnjẹ sílẹ̀ fún ara yín, nítorí pé ní ọjọ́ mẹ́ta òní, ẹ ó sọdá Jọ́dánì yìí láti wọlé lọ gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín yóò fi fún yín láti gbà.’ ”+ 12  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ni Jóṣúà sì wí fún pé:+ 13  “Kí ìrántí máa wà nípa ọ̀rọ̀ tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ fún yín pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run yín yóò fún yín ní ìsinmi, ó sì ti fi ilẹ̀ yìí fún yín. 14  Àwọn aya yín, àwọn ọmọ yín kéékèèké àti àwọn ohun ọ̀sìn yín yóò máa gbé lórí ilẹ̀ tí Mósè ti fi fún yín ní ìhà ìhín Jọ́dánì;+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ré kọjá pẹ̀lú ìtẹ́gun+ níwájú àwọn arákùnrin yín, gbogbo akíkanjú ọkùnrin alágbára ńlá,+ kí ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́. 15  Ìgbà tí Jèhófà bá fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bákan náà bí ó ti fún yín, tí àwọn náà sì ti gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín yóò fi fún wọn,+ ni kí ẹ tó padà sí ilẹ̀ ìní yín, kí ẹ sì gbà á,+ èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ti fi fún yín ní ìhà Jọ́dánì, síhà yíyọ oòrùn.’ ”+ 16  Nítorì náà, wọ́n dá Jóṣúà lóhùn pé: “Gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún wa ni àwa yóò pa mọ́, ibikíbi tí o bá sì rán wa ni àwa yóò lọ.+ 17  Bí àwa ti fetí sí Mósè nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò fetí sí ọ. K ì kì pé kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,+ gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú Mósè.+ 18  Ènìyàn èyíkéyìí tí ó bá ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni+ rẹ, tí kò sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí o bá pa láṣẹ fún un ni a ó fi ikú pa.+ K ì kì pé kí ìwọ jẹ́ onígboyà àti alágbára.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé