Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 8:1-22

8  Bílídádì ọmọ Ṣúáhì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa sọ nǹkan wọ̀nyí jáde,+ Nígbà tí àwọn àsọjáde ẹnu rẹ jẹ́ kìkì ẹ̀fúùfù lílágbára?+   Ọlọ́run yóò ha yí ìdájọ́ po,+ Tàbí kẹ̀, Olódùmarè yóò ha yí òdodo po?+   Bí àwọn ọmọ rẹ bá ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, Tí ó fi jẹ́ kí wọ́n bọ́ sí ọwọ́ ìdìtẹ̀ wọn,   Bí ìwọ fúnra rẹ bá wá Ọlọ́run,+ Bí ìwọ bá sì fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere lọ́dọ̀ Olódùmarè,   Bí ìwọ bá mọ́ gaara tí o sì dúró ṣánṣán,+ Ì bá ti jí fún ọ nísinsìnyí, Dájúdájú, òun ì bá sì ti mú ibi gbígbé òdodo rẹ padà bọ̀ sípò.   Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ ti lè jẹ́ ohun kékeré, Ṣùgbọ́n òpin rẹ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ yóò di ńlá gidigidi.+   Ní tòótọ́, jọ̀wọ́ béèrè lọ́wọ́ ìran àtijọ́,+ Kí o sì darí àfiyèsí rẹ sí àwọn nǹkan tí àwọn baba wọ́n wá jáde.+   Nítorí pé ọmọ àná+ ni wá, a kò sì mọ nǹkan kan, Nítorí pé òjìji ni àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé.+ 10  Àwọn fúnra wọn kì yóò ha fún ọ ní ìtọ́ni, kí wọ́n sì sọ fún ọ, Wọn kì yóò ha sì mú ọ̀rọ̀ jáde wá láti inú ọkàn-àyà wọn? 11  Òrépèté+ ha lè dàgbà sókè láìsí ibi irà? Esùsú ha lè di ńlá láìsí omi? 12  Nígbà tí ó ṣì wà nínú ìrudi rẹ̀, tí a kò tíì ya á kúrò, Àní yóò gbẹ dànù ṣáájú gbogbo koríko mìíràn.+ 13  Bí ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run ṣe rí nìyẹn,+ Àní ìrètí apẹ̀yìndà yóò sì ṣègbé,+ 14  Ẹni tí a ké ìgbọ́kànlé rẹ̀ kúrò, Tí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sì jẹ́ ilé aláǹtakùn.+ 15  Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n ilé náà kì yóò máa bá a lọ ní dídúró; Yóò dì í mú, ṣùgbọ́n kì yóò wà pẹ́. 16  Ó kún fún oje níwájú oòrùn, Ẹ̀ka igi rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.+ 17  Gbòǹgbò rẹ̀ ti hun pọ̀ mọ́ra nínú òkìtì òkúta, Ilé òkúta ni ó ń rí. 18  Bí ẹnì kan bá gbé e mì kúrò ní ipò rẹ̀,+ Yóò sì sẹ́ ẹ dájúdájú, wí pé, ‘Èmi kò rí ọ rí.’+ 19  Wò ó! Ìyẹn ni yíyọ́ ọ̀nà rẹ̀;+ Àwọn mìíràn sì ń rú láti inú ekuru. 20  Wò ó! Ọlọ́run kì yóò kọ aláìlẹ́bi sílẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò di ọwọ́ àwọn aṣebi mú, 21  Títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ẹnu rẹ, Tí yóò si fi igbe ìdùnnú kún ètè rẹ. 22  Àní àwọn tí ó kórìíra rẹ ni a ó da ìtìjú bò,+ Àgọ́ àwọn ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé