Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 7:1-21

7  “Òpò àpàpàǹdodo+ kò ha sí fún ẹni kíkú lórí ilẹ̀, Àwọn ọjọ́ rẹ̀ kò ha sì dà bí àwọn ọjọ́ lébìrà tí a háyà?+  Bí ẹrú, ó ń fi ìháragàgà ṣàfẹ́rí òjìji,+ Àti bí lébìrà tí a háyà, ó ń dúró de owó ọ̀yà rẹ̀.+   Nípa báyìí, a ti mú kí n ní àwọn oṣù òṣùpá tí kò ní láárí,+ Àwọn òru ìdààmú+ ni wọ́n sì ti ka iye rẹ̀ fún mi.   Nígbà tí mo dùbúlẹ̀, mo tún sọ pé, ‘Ìgbà wo ni èmi yóò dìde?’+ Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́ tán ní ti gidi, a tún fi àìlègbéjẹ́ rọ mí yó títí di wíríwírí òwúrọ̀.   Ìdin+ àti ìṣùpọ̀ ekuru+ ti bo ara mi; Awọ ara mi ti séèépá, ó sì yọ́.+   Àwọn ọjọ́ mi pàápàá yára+ ju ọkọ̀ ìhunṣọ, Wọ́n sì ti wá sí òpin ní àìnírètí.+   Rántí pé ẹ̀fúùfù ni ìwàláàyè mi;+ Pé ojú mi kì yóò tún rí ire mọ́.   Ojú ẹni tí ń rí mi kì yóò rí mi mọ́; Ojú rẹ yóò wà lára mi, ṣùgbọ́n èmi kì yóò sí mọ́.+   Dájúdájú, àwọsánmà ń wá sí òpin rẹ̀, ó sì ń lọ; Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù kì yóò gòkè wá.+ 10  Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́, Ipò rẹ̀ kì yóò sì mọ̀ ọ́n mọ́.+ 11  Èmi, àní, èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́. Dájúdájú, èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú wàhálà ẹ̀mí mi; Èmi yóò ṣàníyàn nípa ìkorò ọkàn mi!+ 12  Ṣé òkun tàbí ẹran ńlá abàmì inú òkun ni mí ni, Tí ìwọ yóò fi yan ẹ̀ṣọ́ tì mí?+ 13  Nígbà tí mo sọ pé, ‘Àga ìnàyìn mi yóò tù mí nínú, Ibùsùn mi yóò ṣèrànwọ́ ní ríru ìdàníyàn mi,’ 14  Àní ìwọ ti fi àwọn àlá dáyà já mi, O sì fi àwọn ìran mú mi ta gìrì nítorí jìnnìjìnnì, 15  Tí ọkàn mi fi yan ìfúnpa, Ikú+ dípò egungun mi. 16  Mo kọ̀ ọ́;+ èmi kì yóò wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin. Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí pé èémí àmíjáde ni àwọn ọjọ́ mi.+ 17  Kí ni ẹni kíkú+ tí ìwọ yóò fi máa tọ́ ọ dàgbà, Tí ìwọ yóò sì máa ṣàníyàn nípa rẹ̀ nínú ọ̀kàn-àyà rẹ, 18  Tí ìwọ yóò fi máa fetí sí i ní òròòwúrọ̀, Tí ìwọ yóò fi máa dán an wò ní ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú?+ 19  Èé ṣe tí ìwọ kì yóò fi yí ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi,+ Tàbí kí o jọ̀wọ́ mi jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi dá itọ́ mi mì? 20  Bí mo bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni mo lè ṣe àṣeparí rẹ̀ lòdì sí ọ, ìwọ Olùkíyèsí aráyé?+ Èé ṣe tí o fi fi mí ṣe àfojúsùn rẹ, tí èmi yóò fi di ẹrù ìnira fún ọ? 21  Èé sì ti ṣe tí ìwọ kò dárí ìrélànàkọjá mi jì,+ Kí o sì gbójú fo ìṣìnà mi dá? Nítorí èmi yóò dùbúlẹ̀ sínú ekuru+ nísinsìnyí; Dájúdájú, ìwọ yóò wá mi, èmi kì yóò sì sí mọ́.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé