Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 42:1-17

42  Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dá Jèhófà lóhùn, ó sì wí pé:   “Mo ti wá mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo,+Kò sì sí èrò-ọkàn kankan tí ó jẹ́ aláìṣeélébá fún ọ.+   ‘Ta nìyí tí ń ṣú òkùnkùn bo ìmọ̀ràn láìní ìmọ̀?’+Nítorí náà, mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò lóyeÀwọn ohun tí ó jẹ́ àgbàyanu gidigidi fún mi, èyí tí èmi kò mọ̀.+   ‘Jọ̀wọ́, gbọ́, èmi alára yóò sì sọ̀rọ̀.Èmi yóò bi ọ́ léèrè, kí o sì sọ fún mi.’+   Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ,Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.   Ìdí nìyẹn tí mo fi yíhùn padà,Mo sì ronú pìwà dà+ nínú ekuru àti eérú.”  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà ti bá Jóòbù sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, pé Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bá Élífásì ará Témánì sọ̀rọ̀ pé:“Ìbínú mi gbóná sí ìwọ àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ méjèèjì,+ nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́+ nípa mi bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ti ṣe.  Wàyí o, ẹ mú akọ màlúù méje àti àgbò méje+ fún ara yín, kí ẹ sì tọ ìránṣẹ́ mi Jóòbù lọ,+ kí ẹ sì rú ẹbọ sísun nítorí ara yín; Jóòbù ìránṣẹ́ mi yóò sì fúnra rẹ̀ gbàdúrà fún yín.+ Ojú rẹ̀ nìkan ni èmi yóò tẹ́wọ́ gbà láti má ṣe hu ìwà ẹ̀gọ̀ tí ń dójú tini sí yín, nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa mi, bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ti ṣe.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Élífásì ará Témánì àti Bílídádì ọmọ Ṣúáhì àti Sófárì ọmọ Náámà lọ, wọ́n sì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún wọn; Jèhófà sì tipa bẹ́ẹ̀ tẹ́wọ́ gba ojú Jóòbù. 10  Jèhófà tìkára rẹ̀ sì yí ipò òǹdè Jóòbù+ padà nígbà tí ó gbàdúrà nítorí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀,+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fún Jóòbù ní àfikún ohun gbogbo tí ó jẹ́ tirẹ̀ rí, ní ìlọ́po méjì.+ 11  Gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn tí ó mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí+ sì ń tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jẹ oúnjẹ+ nínú ilé rẹ̀, wọ́n sì ń bá a kẹ́dùn, wọ́n sì ń tù ú nínú lórí gbogbo ìyọnu àjálù tí Jèhófà ti jẹ́ kí ó dé bá a; olúkúlùkù wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti fún un ní ẹyọ owó, olúkúlùkù sì fún un ní òrùka wúrà. 12  Ní ti Jèhófà, ó bù kún+ ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀+ lọ, tí ó fi wá ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àgùntàn àti ẹgbàáta ràkúnmí àti ẹgbẹ̀rún àdìpọ̀ méjì-méjì màlúù àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 13  Ó sì wá ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta pẹ̀lú.+ 14  Ó sì pe orúkọ àkọ́kọ́ ní Jémímà àti orúkọ ìkejì ní Kẹsáyà àti orúkọ ìkẹta ní Kereni-hápúkì. 15  Kò sì sí obìnrin kankan tí a rí ní gbogbo ilẹ̀ náà tí ó rẹwà bí àwọn ọmọbìnrin Jóòbù, baba wọn sì tẹ̀ síwájú láti fún wọn ní ogún láàárín àwọn arákùnrin wọn.+ 16  Jóòbù sì wà láàyè lẹ́yìn èyí fún ogóje ọdún,+ ó sì wá rí àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀+—ìran mẹ́rin. 17  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Jóòbù kú, ó darúgbó, ó sì kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún ọjọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé