Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 41:1-34

41  “Ìwọ ha lè fi ìwọ̀ ẹja fa Léfíátánì+ jáde,Tàbí ìwọ ha lè fi ìjàrá mú ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?   Ìwọ ha lè ti koríko etídò bọ ihò imú rẹ̀,+Tàbí ìwọ ha lè fi ẹ̀gún dá páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ lu?   Yóò ha pa àrọwà púpọ̀ sí ọ,Tàbí yóò ha bá ọ sọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́?   Yóò ha bá ọ dá májẹ̀mú,Kí o bàa lè mú un ṣe ẹrú fún àkókò tí ó lọ kánrin?   Ìwọ yóò ha bá a ṣeré bí ẹni pé ẹyẹ ni,Tàbí ìwọ yóò ha so ó fún àwọn ọmọdébìnrin rẹ?   Àwọn alájọṣe yóò ha fi í gba ìpààrọ̀?Wọn yóò ha pín in láàárín àwọn oníṣòwò?   Ìwọ yóò ha fi àwọn akásì+ kún awọ ara rẹ̀,Tàbí fi àwọn ọ̀kọ̀ ìpẹja kún orí rẹ̀?   Gbé ọwọ́ rẹ lé e.Rántí ìjà ogun náà. Má ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.   Wò ó! Ìfojúsọ́nà ẹni nípa rẹ̀ ni ó dájú pé yóò já kulẹ̀.Ènìyàn yóò sì ṣubú lulẹ̀ ní rírí i lásán. 10  Kò sí ẹnì kankan tí ó ṣàyàgbàǹgbà tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi ru ú sókè.Ta sì ni ẹni tí ó lè kò mí lójú?+ 11  Ta ní ti kọ́kọ́ fi ohun kan fún mi, tí ó fi yẹ kí n san+ án padà fún un?Gbogbo abẹ́ ọ̀run jẹ́ tèmi.+ 12  Èmi kì yóò dákẹ́ nípa àwọn apá kan ara rẹ̀Tàbí ọ̀ràn nípa agbára ńlá rẹ̀ àti ẹwà kíkọyọyọ ìrísí rẹ̀. 13  Ta ní ti ká ojú aṣọ rẹ̀?Ta ni yóò wọnú páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ ìlọ́po méjì? 14  Ta ní ti ṣí àwọn ilẹ̀kùn ojú rẹ̀?Eyín rẹ̀ yí ká ń kó jìnnìjìnnì báni. 15  Aporo àwọn ìpẹ́ ni ìrera rẹ̀,Ó pa dé bí ẹni pé pẹ̀lú èdìdì lílepinpin. 16  Ọ̀kan lẹ̀ típẹ́-típẹ́ mọ́ ìkejì,Afẹ́fẹ́ pàápàá kò sì lè wọ àárín wọn. 17  Ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ ìkejì, wọ́n lẹ̀ mọ́ra;Wọ́n gbá ara wọn mú, a kò sì lè yà wọ́n sọ́tọ̀. 18  Àní sísín rẹ̀ ń mú kí ìmọ́lẹ̀ kọ mànà,Ojú rẹ̀ sì dà bí ìtànyanran ọ̀yẹ̀. 19  Láti ẹnu rẹ̀ ni ìkọyẹ̀rì mànàmáná ti ń jáde lọ,Àni ìtapàrà iná ń jáde lọ. 20  Láti ihò imú rẹ̀ ni èéfín ti ń jáde lọ,Bí ìléru tí a fi koríko etídò pàápàá mú jó lala. 21  Ọkàn rẹ̀ ń mú ẹyín iná jó,Àní ọwọ́ iná sì ń ti ẹnu rẹ̀ jáde lọ. 22  Ọrùn rẹ̀ ni okun wà,Ìbọ́hùn sì ń fò sókè níwájú rẹ̀. 23  Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ mọ́ra;Ó dà bí ohun tí a rọ sára rẹ̀, láìṣeéṣínípò. 24  A rọ ọkàn-àyà rẹ̀ bí òkúta,Bẹ́ẹ̀ ni, a rọ ọ́ bí ìyá ọlọ. 25  Nítorí dídìde tí ó dìde, jìnnìjìnnì bo alágbára;+Nítorí ìfòyà, ìdàrúdàpọ̀-ọkàn bá wọn. 26  Ní lílé e bá, àní idà kò bá a dọ́gba,Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kọ̀, igaga tàbí orí ọfà+ kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. 27  Ó ka irin sí+ èérún pòròpórò lásán-làsàn,Bàbà bí igi jíjẹrà lásán-làsàn. 28  Ọfà kò lè lé e lọ;Òkúta kànnàkànnà+ ti yí padà di àgékù pòròpórò fún un. 29  Ọ̀gọ ni ó kà sí àgékù pòròpórò lásán-làsàn,+Ó sì ń fi dídún ẹ̀ṣín rẹ́rìn-ín. 30  Bí àwọn àpáàdì aborí-ṣóńṣó ni àwọn apá ìsàlẹ̀ rẹ̀ rí;Ó ń tẹ́ ohun èlò ìpakà+ sórí ẹrẹ̀. 31  Ó ń mú kí ibú máa hó bí ìkòkò;Àní ó ń ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìkunra. 32  Ó mú kí ipa ọ̀nà mọ́lẹ̀ lẹ́yìn ara rẹ̀;Ènìyàn a ka ibú omi sí orí ewú. 33  Lórí ekuru, kò sí èyí tí ó dà bí rẹ̀,Ọ̀kan tí a ṣe láti wà láìní ìpayà. 34  Ohun gíga gbogbo ni ó ń rí.Ọba ni lórí gbogbo ẹranko ẹhànnà ọlọ́lá-ńlá.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé