Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 40:1-24

40  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti dá Jóòbù lóhùn, ó sì wí pé:   “Ó ha yẹ kí àríyànjiyàn ṣíṣe èyíkéyìí wáyé níhà ọ̀dọ̀ ẹni tí ń wá àléébù Olódùmarè?+Kí ẹni tí ń fi ìbáwí tọ́ Ọlọ́run sọ́nà dáhùn rẹ̀.”+  Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dá Jèhófà lóhùn, ó sì wí pé:   “Wò ó! Mo ti di aláìjámọ́ pàtàkì.+Kí ni èmi yóò fi fún ọ lésì?Mo ti fi ọwọ́ mi lé ẹnu mi.+   Mo ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, èmi kì yóò sì dáhùn mọ́;Àti lẹ́ẹ̀mejì, èmi kì yóò sì fi nǹkan kan kún un mọ́.”   Jèhófà sì ń bá a lọ ní dídá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì ẹlẹ́fùúùfù,+ ó sì wí pé:   “Jọ̀wọ́, di abẹ́nú rẹ lámùrè bí abarapá ọkùnrin;+Èmi yóò bi ọ́ léèrè, kí o sì sọ fún mi.+   Ní ti tòótọ́, ìwọ yóò ha sọ ìdájọ́ òdodo mi di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀?Ìwọ yóò ha pè mí ní ẹni burúkú, kí o bàa lè jàre?+   Tàbí ìwọ ha ní apá bí ti Ọlọ́run tòótọ́,+Àti pé, pẹ̀lú ohùn bí tirẹ̀, ìwọ ha lè sán ààrá?+ 10  Jọ̀wọ́, fi ìlọ́lájù+ àti ipò gíga+ ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́;Kí o sì fi iyì+ àti ọlá ńlá+ wọ ara rẹ láṣọ. 11  Jẹ́ kí ìbújáde ìbínú kíkankíkan+ rẹ ṣàn jáde,Kí o sì rí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ onírera, kí o sì rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀. 12  Rí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ onírera, sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,+Kí o sì tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀ ní ibi tí wọ́n wà gan-an. 13  Fi wọ́n pa mọ́ pa pọ̀ sínú ekuru,+Àní kí o de ojú wọn ní ibi tí ó fara sin, 14  Èmi, àní èmi, yóò sì gbóríyìn fún ọ,Nítorí pé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè gbà ọ́ là. 15  Wàyí o, Béhémótì ń bẹ tí mo ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìwọ.Koríko tútù+ ni ó ń jẹ bí akọ màlúù. 16  Wàyí o, agbára rẹ̀ wà ní ìgbáròkó rẹ̀,Okun rẹ̀ alágbára gíga+ sì wà ní iṣan yíyi ikùn rẹ̀. 17  Ó ń tẹ ìrù rẹ̀ ba bí kédárì;Àwọn fọ́nrán iṣan tí ó wà ní itan rẹ̀ hun pọ̀ mọ́ra. 18  Egungun rẹ̀ jẹ́ túùbù bàbà;Egungun rẹ̀ lílágbára dà bí àwọn ọ̀pá irin àsèjiná. 19  Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn ọ̀nà Ọlọ́run ni;Olùṣẹ̀dá rẹ̀+ lè mú idà rẹ̀ sún mọ́ tòsí. 20  Nítorí àwọn òkè ńlá ń so eso wọn fún un,+Gbogbo ẹranko inú pápá sì ń ṣeré níbẹ̀. 21  Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótọ́sì ẹlẹ́gùn-ún,Ní ibi esùsú+ tí ó lùmọ́ àti ibi irà.+ 22  Àwọn igi lótọ́sì ẹlẹ́gùn-ún fi òjìji wọn dí i pa;Àwọn igi pọ́pílà tí ó wà ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá yí i ká. 23  Bí odò bá ru gùdù, kì í fi ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì sá.Ó ní ìgbọ́kànlé, bí Jọ́dánì+ bá tilẹ̀ ya dé ẹnu rẹ̀. 24  Lójú ara rẹ̀, ẹnikẹ́ni ha lè mú un bí?Ẹnikẹ́ni ha lè fi àwọn ìdẹkùn dá imú rẹ̀ lu?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé