Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 39:1-30

39  “Ìwọ ha ti wá mọ àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá ti àpáta gàǹgà láti bímọ?+Ìwọ ha ń ṣàkíyèsí ìgbà náà gan-an tí egbin ń bímọ+ nínú ìroragógó?   Ìwọ ha ń ka iye oṣù òṣùpá tí wọ́n ń pé,Tàbí ìwọ ha ti wá mọ àkókò tí a yàn kalẹ̀ tí wọ́n fi ń bímọ?   Wọ́n ń tẹ̀ ba nígbà tí wọ́n bá ń bí àwọn ọmọ wọn,Nígbà tí wọ́n rẹ́yìn ìroragógó wọn.   Ọmọ wọ́n sanra bọ̀kíbọ̀kí, wọ́n sì ń tóbi nínú pápá gbalasa;Wọ́n jáde lọ ní ti tòótọ́, wọn kò sì padà sọ́dọ̀ wọn mọ́.   Ta ní rán kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà+ jáde lómìnira,Ta sì ni ó tú àní àwọn ọ̀já kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́,   Èyí tí mo yan pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ṣe ilé rẹ̀Èyí tí àwọn ibi gbígbé rẹ̀ sì jẹ́ ilẹ̀ iyọ̀?+   Ó ń fi yánpọnyánrin ìlú rẹ́rìn-ín;Kì í gbọ́ ariwo ayọ́dẹ.+   Ó ń yẹ àwọn òkè ńlá wò kiri fún pápá ìjẹko rẹ̀,+Ó sì ń wá gbogbo onírúurú ọ̀gbìn tútù.+   Akọ màlúù ìgbẹ́ ha fẹ́ láti sìn ọ́,+Tàbí yóò ha sùn mọ́jú lẹ́bàá ibùjẹ ẹran rẹ? 10  Ìwọ ha lè fi ìjàrá akọ màlúù ìgbẹ́ dè é pinpin nínú aporo,Tàbí yóò ha fọ́ ògúlùtu+ lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn? 11  Ìwọ yóò ha ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ nítorí pé agbára rẹ̀ pọ̀ yanturu,Ìwọ yóò ha sì fi làálàá rẹ sílẹ̀ fún un? 12  Ìwọ yóò ha gbójú lé e pé yóò mú irúgbìn rẹ padà wá,Pé yóò sì kó o jọ sí ilẹ̀ ìpakà rẹ? 13  Ìyẹ́ apá abo ògòǹgò ha ti fi ìdùnnú lù pìpì,Tàbí ó ha ní ìyẹ́ àfifò ti ẹyẹ àkọ̀+ àti ìyẹ́-òun-ìhùùhù? 14  Nítorí ó ń fi ẹyin rẹ̀ sílẹ̀ sí ilẹ̀yílẹ̀,Ó sì ń fi ekuru mú wọn móoru, 15  Ó sì gbàgbé pé ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́,Tàbí pé ẹranko inú pápá pàápàá lè tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. 16  Ó ń ṣe àwọn ọmọ rẹ̀ ṣúkaṣùka, bí ẹni pé kì í ṣe tirẹ̀+Asán ni làálàá rẹ̀ jẹ́ nítorí pé kò ní ìbẹ̀rùbojo kankan. 17  Nítorí Ọlọ́run tí mú kí ó gbàgbé ọgbọ́n,Kò sì fi ìpín òye fún un.+ 18  Ní ìgbà tí ó bá ju ìyẹ́ apá rẹ̀ sókè pìpì,Ó ń fi ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún rẹ́rìn-ín. 19  Ìwọ ha lè fún ẹṣin ní agbára ńlá?+Ìwọ ha lè fi gọ̀gọ̀ tí ń ṣe harahara bo ọrùn rẹ̀? 20  Ìwọ ha lè mú kí ó tọ sókè bí eéṣú?Iyì ìfọnmú rẹ̀ ń kó jìnnìjìnnì báni.+ 21  Ó ń fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀+ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀, ó sì ń yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú agbára;Ó ń jáde lọ láti pàdé ìhámọ́ra.+ 22  Ẹ̀rín ni ó ń fi ìbẹ̀rùbojo rín, kì í sì í jáyà;+Bẹ́ẹ̀ ni kì í yí padà ní tìtorí idà. 23  Apó ń mì pẹkẹpẹkẹ sí i,Abẹ ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín. 24  Ó ń fi ìbìlù àti ìrusókè gbé ilẹ̀ ayé mì,Kò sì gbà gbọ́ pé ìró ìwo ni. 25  Gbàrà tí ìwo bá dún, a sọ pé Àháà!Ó sì ń gbóòórùn ìjà ogun láti ibi jíjìnnàréré wá,Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àwọn olórí àti igbe ogun.+ 26  Ṣé òye rẹ ni ó mú kí àṣáǹwéwé ròkè lálá,Tí ó fi na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ẹ̀fúùfù gúúsù? 27  Tàbí ṣé nípa àṣẹ ìtọ́ni rẹ ni idì+ fi ń fò lọ síhà òkè,Tí ó sì fi ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè fíofío,+ 28  Tí ó fi ń gbé orí àpáta gàǹgà, tí ó sì máa ń wọ̀ síbẹ̀ ní òruLórí eyín àpáta gàǹgà àti ibi tí kò ṣée dé? 29  Láti ibẹ̀ ni ó ti ń wá oúnjẹ;+Ojú rẹ̀ ń wo ọ̀nà jíjìn. 30  Àní àwọn ọmọ rẹ̀ sì ń sófèrè ẹ̀jẹ̀;Ibi tí àwọn ohun tí a pa bá wà, ibẹ̀ ni ó ń wà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé