Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 36:1-33

36  Élíhù sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé:   “Mú sùúrù fún mi nígbà díẹ̀ sí i, èmi yóò sì polongo fún ọ Pé ọ̀rọ̀ ṣì wà láti sọ fún Ọlọ́run.   Èmi yóò mú ìmọ̀ mi láti ibi jíjìnnàréré wá, Èmi yóò sì gbé òdodo fún Oníṣẹ́ ọnà mi.+   Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ mi, ní tòótọ́, kì í ṣe èké rárá; Ẹni pípé nínú ìmọ̀+ ń bẹ pẹ̀lú rẹ.   Wò ó! Ọlọ́run jẹ́ alágbára ńlá,+ kì yóò sì tani nù; Ó pọ̀ ní agbára ọkàn-àyà;   Òun kì yóò pa ẹni burúkú mọ́ láàyè,+ Ṣùgbọ́n òun yóò fi ìdájọ́ fún àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+   Òun kì yóò mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo;+ Àní àwọn ọba tí ó wà lórí ìtẹ́ pàápàá+ Òun yóò mú wọn jókòó títí láé pẹ̀lú, a ó sì gbé wọn ga.   Bí a bá sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,+ Tí a fi ìjàrá ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́ mú wọn lẹ́rú.   Nígbà náà ni òun yóò sọ fún wọn nípa bí wọ́n ti hùwà Àti ìrélànàkọjá wọn, nítorí pé wọ́n gbé àgbéré mo-jù-wọ́n-lọ. 10  Òun yóò sì ṣí etí wọn sí ìgbani-níyànjú,+ Òun yóò sì sọ pé kí wọ́n yí padà kúrò nínú ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́.+ 11  Bí wọ́n bá ṣègbọràn tí wọ́n sì sìn ín, Wọn yóò parí ọjọ́ wọn nínú ohun rere Àti ọdún wọn nínú adùn.+ 12  Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá ṣègbọràn, wọn yóò kọjá lọ+ àní nípasẹ̀ ohun ọṣẹ́,+ Wọn yóò sì gbẹ́mìí mì láìní ìmọ̀. 13  Àwọn tí ó sì jẹ́ apẹ̀yìndà ní ọkàn-àyà yóò to ìbínú jọ.+ Wọn kò gbọ́dọ̀ kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nítorí pé ó ti dè wọ́n. 14  Ọkàn wọn yóò kú ní ìgbà èwe,+ Àti ìwàláàyè wọn láàárín àwọn kárùwà ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì.+ 15  Òun yóò gba ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ sílẹ̀ nínú ìṣẹ́ rẹ̀, Òun yóò sì ṣí etí wọn nínú ìnilára. 16  Dájúdájú, òun yóò sì dẹ ọ́ lọ kúrò ní ẹnu wàhálà!+ Àyè fífẹ̀ sí i,+ kì í ṣe èyí tí ó há pinpin, yóò wà ní àyè rẹ̀, Ìtùnú tábìlì rẹ yóò sì kún fún ọ̀rá.+ 17  Dájúdájú, ìwọ yóò kún fún ìdájọ́ ẹ̀tọ́ fún ẹni burúkú;+ Ìdájọ́ ẹ̀tọ́ àti ìdájọ́ òdodo yóò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. 18  Nítorí, ṣọ́ra kí ìhónú+ má bàa dẹ ọ́ lọ sínú àtẹ́wọ́ pípa lọ́nà ìpẹ̀gàn, Má sì ṣe jẹ́ kí ìràpadà+ títóbi mú ọ ṣáko lọ. 19  Igbe rẹ fún ìrànlọ́wọ́ yóò ha gbéṣẹ́ bí?+ Rárá, kì í tilẹ̀ ṣe nínú wàhálà Àní gbogbo ìsapá rẹ lílágbára.+ 20  Má fi ìháragàgà ṣàfẹ́rí òru, Fún àwọn ènìyàn láti sá padà kúrò ní ibi tí wọ́n wà. 21  Ṣọ́ra kí o má ṣe yíjú sí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́,+ Nítorí èyí ni ìwọ yàn dípò ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́.+ 22  Wò ó! Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ń fi agbára rẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gíga; Ta ni olùkọ́ni tí ó dà bí rẹ̀? 23  Ta ní ti pè é láti wá jíhìn fún ọ̀nà rẹ̀,+ Ta sì ni ó ti sọ pé, ‘O ti hùwà àìṣòdodo’?+ 24  Rántí pé ìwọ ní láti gbé ìgbòkègbodò rẹ̀ ga lọ́lá+ Èyí tí àwọn ènìyàn ti fi kọrin.+ 25  Gbogbo aráyé tẹjú mọ́ ọn; Ẹni kíkú ń wò ó láti ibi jíjìnnàréré.+ 26  Kíyè sí i! Ọlọ́run ga ju bí a ṣe lè mọ̀;+ Àwọn ọdún rẹ̀ ré kọjá àwárí ní iye.+ 27  Nítorí òun a máa fa ẹ̀kán omi sókè;+ Wọ́n a máa kán wínníwínní bí òjò fún ìkùukùu rẹ̀, 28  Tí àwọsánmà fi ń sẹ̀,+ Wọ́n ń kán tótó lọ́pọ̀ yanturu sórí aráyé. 29  Ní tòótọ́, ta ní lè lóye ipele àwọsánmà, Ariwo sísán wàá láti inú àtíbàbà rẹ̀?+ 30  Wò ó! Ó na ìmọ́lẹ̀+ rẹ̀ jáde sórí rẹ̀, Ó sì bo àwọn gbòǹgbò òkun. 31  Nítorí nípa wọn ni ó ń gba ẹjọ́ àwọn ènìyàn rò;+ Ó ń pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu.+ 32  Ó bo mànàmáná mọ́lẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, Ó sì gbé àṣẹ kà á lórí lòdì sí afipákọluni.+ 33  Ìbúramúramù+ rẹ̀ ń sọ nípa rẹ̀, Àti ohun ọ̀sìn pẹ̀lú ń sọ nípa ẹni tí ń jáde bọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé