Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 35:1-16

35  Élíhù sì ń bá a lọ ní dídáhùn, ó sì wí pé:   “Ṣé èyí ni ohun tí ìwọ kà sí ìdájọ́ òdodo? Ìwọ wí pé, ‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ.’+   Nítorí ìwọ wí pé, ‘Kí ni ó wúlò fún ọ fún?+ Àǹfààní wo ni mo ní ju ti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ń ṣẹ̀?’+   Èmi fúnra mi yóò fún ọ lésì Àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́+ rẹ pẹ̀lú rẹ.   Gbé ojú sókè ọ̀run,+ kí o sì wò, Sì wo àwọsánmà,+ pé wọ́n ga jù ọ́ lọ ní tòótọ́.   Bí o bá dẹ́ṣẹ̀ ní ti tòótọ́, kí ni ìwọ ṣe àṣeparí rẹ̀ lòdì sí i?+ Bí àwọn ìdìtẹ̀ rẹ bá sì pọ̀ sí i ní ti tòótọ́, kí ni ìwọ ṣe sí i?   Bí o bá jàre ní tòótọ́, kí ni ìwọ fi fún un, Tàbí kí ni ó rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?+   Ìwà burúkú rẹ lè jẹ́ sí ènìyàn bí ìwọ,+ Àti Òdodo rẹ sí ọmọ ará ayé.+   Nítorí ògìdìgbó ìnilára, wọ́n ń pè fún ìrànlọ́wọ́;+ Wọ́n ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nítorí apá àwọn ẹni ńlá.+ 10  Síbẹ̀, kò sí ẹnì kankan tí ó sọ pé, ‘Ọlọ́run Olùṣẹ̀dá mi Atóbilọ́lá dà,+ Ẹni tí ń fúnni ní orin atunilára ní òru?’+ 11  Òun ni Ẹni tí ń kọ́+ wa ju àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé,+ Ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹ̀dá tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá. 12  Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń ké jáde ṣáá, ṣùgbọ́n kò dáhùn,+ Nítorí ìgbéraga+ àwọn ẹni búburú. 13  Kìkì pé Ọlọ́run kì í gbọ́ àìṣòótọ́,+ Olódùmarè kì í sì í rí i.+ 14  Áńbọ̀sìbọ́sí ìgbà tí o bá wá sọ pé ìwọ kò rí i!+ Ẹjọ́ ń bẹ níwájú rẹ̀, nítorí náà kí o fi tàníyàn-tàníyàn dúró dè é.+ 15  Nísinsìnyí, nítorí pé ìbínú rẹ̀ kò tíì béèrè fún ìjíhìn,+ Àti pé òun kò tíì fiyè sí ìwàǹwára tí ó dé góńgó.+ 16  Jóòbù alára kàn la ẹnu rẹ̀ lásán; Ó kàn ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìní ìmọ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé