Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 33:1-33

33  “Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, Jóòbù, jọ̀wọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,Kí o sì fi etí sí gbogbo ohun tí mo ń sọ.   Jọ̀wọ́, wò ó! mo ní láti la ẹnu mi;Ahọ́n mi pẹ̀lú òkè ẹnu+ mi ní láti sọ̀rọ̀.   Àwọn àsọjáde mi ni ìdúróṣánṣán ọkàn-àyà mi,+Ìmọ̀ sì ni ohun tí ètè mi ń fi òtítọ́ inú sọ jáde.+   Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó ṣẹ̀dá mi,+Èémí Olódùmarè sì ni ó mú mi wá sì ìyè.+   Bí o bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, fún mi lésì,To ọ̀rọ̀ lẹ́sẹẹsẹ níwájú mi; mú ìdúró rẹ.   Wò ó! Bí ìwọ ti jẹ́ sí Ọlọ́run tòótọ́ gẹ́lẹ́ ni èmi jẹ́;+Amọ̀ ni a fi mọ mí jáde,+ èmi pẹ̀lú.   Wò ó! Kò sí jìnnìjìnnì kankan nínú mi tí yóò kó ìpayà bá ọ,Kò sì sí ìkìmọ́lẹ̀+ kankan láti ọ̀dọ̀ mi tí yóò wúwo lára rẹ.   Kìkì pé o ti sọ ní etí mi,Mo sì ń gbọ́ ìró ọ̀rọ̀ rẹ pé,   ‘Mo mọ́ gaara láìní ìrélànàkọjá;+Mo mọ́, n kò sì ní ìṣìnà.+ 10  Wò ó! Àyè fún kíkọjú ìjà sí mi ni ó ń wá,Ó kà mí sí ọ̀tá ara rẹ̀.+ 11  Ó fi ẹsẹ̀ mi sínú àbà,+Ó ń ṣọ́ ipa ọ̀nà mi gbogbo.’+ 12  Wò ó! Nínú èyí ìwọ kò tọ̀nà,+ mo dá ọ lóhùn;Nítorí Ọlọ́run fi púpọ̀púpọ̀ ju ẹni kíkú lọ.+ 13  Èé ṣe tí o fi ń bá a fà á,+Ṣé nítorí pé kò dáhùn gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ?+ 14  Nítorí tí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan,Àti lẹ́ẹ̀mejì+—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn kò kà á sí— 15  Lójú àlá,+ àní nínú ìran+ òru,Nígbà tí oorun àsùnwọra bá gbé ènìyàn lọ,Nígbà oorun yẹ́ẹ́ lórí ibùsùn.+ 16  Ìgbà náà ni ó ń ṣí etí ènìyàn,+A sì fi èdìdì rẹ̀ sí gbígbà wọ́n níyànjú, 17  Láti yí ènìyàn kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀,+Àti pé kí ó lè pa ìgbéraga mọ́+ kúrò lọ́dọ̀ abarapá ọkùnrin. 18  Ó fa ọkàn rẹ̀ sẹ́yìn kúrò nínú kòtò+Àti ìwàláàyè rẹ̀ kúrò nínú kíkọjá lọ nípasẹ̀ ohun ọṣẹ́.+ 19  Níti tòótọ́, òun a sì fi ìrora fún un ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà lórí ibùsùn rẹ̀,Aáwọ̀ egungun rẹ̀ sì ń bá a lọ láìdáwọ́ dúró. 20  Dájúdájú, ìwàláàyè rẹ̀ sì mú kí oúnjẹ di ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin,+Ọkàn rẹ̀ sì mú kí oúnjẹ fífani-lọ́kàn-mọ́ra di ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin. 21  Ẹran ara rẹ̀ ń joro lọ lójú,Egungun rẹ̀ tí a kò rí sì di ṣíṣípayá sí gbangba dájúdájú. 22  Ọkàn rẹ̀ sì sún mọ́ kòtò,+Ìwàláàyè rẹ̀ sì sún mọ́ àwọn tí ń fi ikú pani. 23  Bí ońṣẹ́ bá wà fún un,Agbọ̀rọ̀sọ, ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún,Láti sọ fún ènìyàn nípa ìdúróṣánṣán rẹ̀, 24  Nígbà náà, òun a ṣe ojú rere sí i, a sì wí pé,‘Gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ sísọ̀ kalẹ̀ sínú kòtò!+Mo ti rí ìràpadà!+ 25  Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe;+Kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.’+ 26  Òun yóò pàrọwà sí Ọlọ́run kí ó lè ní ìdùnnú sí òun,+Yóò sì rí ojú rẹ̀ tòun ti igbe ìdùnnú,Òun yóò sì mú òdodo Rẹ̀ padà bọ̀ sípò fún ẹni kíkú. 27  Yóò kọrin fún ènìyàn, yóò sì wí pé,‘Mo ti dẹ́ṣẹ̀;+ ohun tí ó dúró ṣánṣán ni mo sì ti yí po,Dájúdájú, kì í sì í ṣe ohun tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún mi. 28  Ó ti tún ọkàn mi rà padà kúrò nínú kíkọjá sínú kòtò,+Ìwàláàyè mi yóò sì rí ìmọ́lẹ̀.’ 29  Wò ó! Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run ń ṣe,Lẹ́ẹ̀mejì, lẹ́ẹ̀mẹ́ta, nínú ọ̀ràn abarapá ọkùnrin, 30  Láti darí ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú kòtò,+Kí a lè fi ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè+ là á lóye. 31  Fiyè sílẹ̀, Jóòbù! Fetí sí mi!Dákẹ́, èmi alára yóò sì máa sọ̀rọ̀ lọ. 32  Bí ọ̀rọ̀ èyíkéyìí bá wà láti sọ, fún mi lésì;Sọ̀rọ̀, nítorí tí èmi ní inú dídùn sí òdodo rẹ. 33  Bí kò bá sí ìkankan, kí ìwọ alára fetí sí mi;+Dákẹ́, èmi yóò sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé