Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jóòbù 32:1-22

32  Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ṣíwọ́ dídá Jóòbù lóhùn, nítorí tí ó jẹ́ olódodo ní ojú ara rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n ìbínú Élíhù ọmọkùnrin Bárákélì ọmọ Búsì+ ti ìdílé Rámù wá gbóná. Ìbínú rẹ̀ ru sí Jóòbù lórí pípolongo tí ó polongo ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìbínú rẹ̀ ru sí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lórí òtítọ́ náà pé wọn kò rí ìdáhùn, ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pe Ọlọ́run ní ẹni burúkú.+  Élíhù alára sì dúró kí Jóòbù sọ̀rọ̀ tán, nítorí tí wọ́n jù ú lọ ní ọjọ́ orí.+  Élíhù sì rí i ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé kò sí ìdáhùn lẹ́nu+ àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, ìbínú rẹ̀ sì túbọ̀ ń gbóná sí i.  Élíhù ọmọkùnrin Bárákélì ọmọ Búsì sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:“Ọ̀dọ́ ni mí ní ọjọ́ orí,Àgbàlagbà sì ni ẹ̀yin.+Ìdí nìyẹn tí mo fi fà sẹ́yìn, àyà sì fò míLáti polongo ìmọ̀ mi fún yín.   Mo sọ pé, ‘Àní àwọn ọjọ́ ni kí ó sọ̀rọ̀,Ògìdìgbó ọdún sì ni ó yẹ kí ó sọ ọgbọ́n di mímọ̀.’+   Dájúdájú, ẹ̀mí tí ó wà nínú àwọn ẹni kíkúÀti èémí Olódùmarè ni ó ń fún wọn ní òye.+   Kì í ṣe àwọn tí ó wulẹ̀ pọ̀ yanturu ní ọjọ́ orí ni ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n,+Tàbí àwọn tí ó kàn darúgbó ni ó lóye ìdájọ́.+ 10  Nítorí náà, mo wí pé, ‘Fetí sí mi.Èmi yóò polongo ìmọ̀ mi, àní èmi.’ 11  Wò ó! Mo ti dúró de ọ̀rọ̀ yín,Mo ń fi etí sí ìfèròwérò yín,+Títí ẹ fi lè wá ọ̀rọ̀ láti sọ. 12  Mo sì yí àfiyèsí mi sọ́dọ̀ yín,Sì kíyè sí i, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ìbáwí tọ́ Jóòbù sọ́nà,Kò sí ìkankan lára yín tí ó dá a lóhùn àwọn àsọjáde rẹ̀, 13  Kí ẹ má sọ pé, ‘Àwa ti rí ọgbọ́n;+Ọlọ́run ni ó lé e lọ, kì í ṣe ènìyàn.’ 14  Níwọ̀n bí kò ti to ọ̀rọ̀ lẹ́sẹẹsẹ lòdì sí mi,Nítorí náà, èmi kì yóò fi àsọjáde yín fún un lésì. 15  A ti já wọn láyà, wọn kò dáhùn mọ́;Ọ̀rọ̀ ti ṣí kúrò lọ́dọ̀ wọn. 16  Mo sì ti dúró, nítorí wọn kò sọ̀rọ̀ mọ́;Nítorí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọn kò dáhùn mọ́. 17  Èmi yóò dáhùn ipa tèmi, àní èmi;Èmi yóò polongo ìmọ̀ mi, àní èmi; 18  Nítorí mo ti kún fún ọ̀rọ̀;Ẹ̀mí ti kó ìdààmú+ bá mi nínú ikùn mi. 19  Wò ó! Ikùn mi dà bí wáìnì tí kò ní ojú ìtújáde;Bí àwọn ìgò awọ tuntun, ó fẹ́ bẹ́.+ 20  Jẹ́ kí n sọ̀rọ̀, kí ara lè tù mí.Èmi yóò ṣí ètè mi kí n lè dáhùn.+ 21  Jọ̀wọ́, kí n má ṣe ojúsàájú ènìyàn;+Èmi kì yóò sì fi orúkọ oyè jíǹkí ará ayé;+ 22  Nítorí ó dájú pé èmi kò mọ bí a ti ń fi orúkọ oyè jíǹkí ẹni;Tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn ni Olùṣẹ̀dá+ mi yóò gbé mi kúrò.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé