Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 31:1-40

31  “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú.+ Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?+   Ìpín wo ni ó sì wà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lókè,+ Tàbí ogún láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè láti ibi gíga lókè?   Àjálù kò ha wà fún oníwà àìtọ́,+ Àti àgbákò ibi fún àwọn aṣenilọ́ṣẹ́?   Òun fúnra rẹ̀ kò ha rí àwọn ọ̀nà mi+ Tí ó sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi pàápàá?   Bí ó bá ṣe pé mo bá àwọn ènìyàn tí kì í sọ òtítọ́ rìn,+ Tí ẹsẹ̀ mi sì ṣe kánkán sí ẹ̀tàn,+   Òun yóò wọ̀n mí lórí òṣùwọ̀n pípéye,+ Ọlọ́run yóò sì wá mọ ìwà títọ́ mi.+   Bí ìṣísẹ̀ mi bá yapa kúrò lójú ọ̀nà,+ Tàbí tí ọkàn-àyà mi tọ kìkì ojú mi lẹ́yìn,+ Tàbí tí àbùkù èyíkéyìí ti lẹ̀ mọ́ mi ní àtẹ́lẹwọ́,+   Kí n fún irúgbìn, kí ẹlòmíràn sì jẹ ẹ́,+ Kí a sì fa àwọn ọmọ ìran mi tu.   Bí ọkàn-àyà mi bá ti di rírélọ sọ́dọ̀ obìnrin kan,+ Tí mo sì ń lúgọ+ àní ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé alábàákẹ́gbẹ́ mi, 10  Kí aya mi fi ọlọ lọ nǹkan fún ọkunrin mìíràn, Kí àwọn ọkùnrin mìíràn sì kúnlẹ̀ lórí rẹ̀.+ 11  Nítorí ìyẹn yóò jẹ́ ìwà àìníjàánu, Ìyẹn yóò sì jẹ́ ìṣìnà fún àfiyèsí àwọn adájọ́.+ 12  Nítorí ìyẹn jẹ́ iná tí yóò jó títí lọ dé ìparun,+ Yóò sì ta gbòǹgbò láàárín gbogbo èso mi. 13  Bí ó bá ṣe pé mo ti máa ń kọ ìdájọ́ ẹrúkùnrin mi, Tàbí ti ẹrúbìnrin mi nínú ẹjọ́ wọn lábẹ́ òfin pẹ̀lú mi, 14  Nígbà náà, kí ni mo lè ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì béèrè fún ìjíhìn, kí ni mo lè fi dá a lóhùn?+ 15  Kì í ha ṣe Ẹni tí ó ṣẹ̀dá mi nínú ikùn ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀,+ Kì í ha sì í ṣe Ẹnì kan ṣoṣo ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pèsè wa sílẹ̀ nínú ilé ọlẹ̀? 16  Bí ó bá ṣe pé mo ti máa ń dá ẹni rírẹlẹ̀ dúró kí wọ́n má ṣe ní inú dídùn,+ Tí mo sì mú kí ojú opó kọṣẹ́,+ 17  Tí mo sì máa ń dá nìkan jẹ òkèlè mi, Nígbà tí ọmọdékùnrin aláìníbaba kò jẹ nínú rẹ̀+ 18  (Nítorí tí ó dàgbà lọ́dọ̀ mi láti ìgbà èwe mi bí ẹni pé lọ́dọ̀ baba, Mo sì ń ṣamọ̀nà obìnrin náà láti inú ikùn ìyá mi wá); 19  Bí mo bá ń rí ẹnikẹ́ni tí n ṣègbé nítorí tí kò ní ẹ̀wù,+ Tàbí tí òtòṣì kò ní ìbora; 20  Bí abẹ́nú rẹ̀ kò bá súre fún mi,+ Tàbí tí kò fi irun tí a rẹ́+ lára àwọn ẹgbọrọ àgbò mi mú ara rẹ̀ móoru; 21  Bí mo bá fi ọwọ́ mi síwá-sẹ́yìn lòdì sí ọmọdékùnrin aláìníbaba,+ Nígbà tí mo bá rí i pé a nílò ìrànwọ́ mi ní ẹnubodè,+ 22  Kí ibi palaba èjìká mi já bọ́ kúrò ní èjìká, Kí apá mi sì ṣẹ́ kúrò ní egungun apá òkè. 23  Nítorí àjálù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ìbẹ̀rùbojo fún mi, Èmi kò sì lè dúrò lòdì sí iyì rẹ̀.+ 24  Bí mo bá fi wúrà ṣe ìgbọ́kànlé mi, Tàbí tí mo sọ fún wúrà pé, ‘Ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi!’+ 25  Bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé dúkìá mi pọ̀,+ Àti nítorí pé ọwọ́ mi ti rí àwọn nǹkan púpọ̀;+ 26  Bí mo bá ń rí ìmọ́lẹ̀ nígbà tí ó bá kọ mànà, Tàbí òṣùpá ọ̀wọ́n tí ń rìn lọ,+ 27  Tí ọkàn-àyà mi sì bẹ̀rẹ̀ sí di rírélọ ní ìkọ̀kọ̀+ Tí ọwọ́ mi sì bẹ̀rẹ̀ sí ko ẹnu mi, 28  Ìyẹn pẹ̀lú yóò jẹ́ ìṣìnà fún àfiyèsí àwọn adájọ́, Nítorí èmi ì bá ti sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wà lókè. 29  Bí mo bá yọ̀ sí àkúrun ẹni tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan,+ Tàbí tí mo ní ìmọ̀lára ìrusókè nítorí pé ibi ti dé bá a— 30  Èmi kò sì jẹ́ kí òkè ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀ Nípa bíbéèrè fún ìbúra lòdì sí ọkàn rẹ̀.+ 31  Bí àwọn ènìyàn tí ó wà nínú àgọ́ mi kò bá sọ pé, ‘Ta ní lè mú ẹnikẹ́ni tí a kò fi oúnjẹ́ rẹ̀ tẹ́ lọ́rùn jáde?’+ 32  Kò sí àtìpó tí yóò sùn mọ́jú ní òde;+ Ilẹ̀kùn mi ni mo ṣí síhà ipa ọ̀nà. 33  Bí mo bá bo àwọn ìrélànàkọjá mi mọ́lẹ̀ bí ará ayé+ Nípa fífi ìṣìnà mi pa mọ́ sínú àpò ṣẹ́ẹ̀tì mi— 34  Nítorí pé èmi yóò gbọ̀n rìrì nínú ogunlọ́gọ̀ ńlá, Tàbí ìfojú tín-ín-rín àwọn ìdílé yóò kó ìpayà bá mi, Èmi yóò sì dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi kì yóò jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà. 35  Ì bá ṣe pé mo ní ẹnì kan tí yóò fetí sí mi,+ Pé Olódùmarè tìkára rẹ̀ yóò dá mi lóhùn+ ní ìbámu pẹ̀lú àmì ìfọwọ́síwèé mi! Tàbí pé ẹni náà tí ó wà nínú ẹjọ́ pẹ̀lú mi lábẹ́ òfin ti kọ àkọsílẹ̀ kan! 36  Dájúdájú, èmi yóò gbé e lé èjìká mi; Èmi yóò dè é mọ́ra bí adé títóbi lọ́lá. 37  Èmi yóò sọ iye àwọn ìṣísẹ̀ mi fún un;+ Bí aṣáájú, èmi yóò tọ̀ ọ́ lọ. 38  Bí ilẹ̀ mi bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ lòdì sí mi, Tí àwọn aporo rẹ̀ sì jọ sunkún; 39  Bí mo bá jẹ èso rẹ̀ láìsan owó,+ Tí mo sì mú kí ọkàn ẹni tí ó ni ín mí hẹlẹ,+ 40  Dípò àlìkámà, kí èpò ẹlẹ́gùn-ún hù jáde,+ Àti èpò tí ń ṣíyàn-án dípò ọkà bálì.” Ọ̀rọ̀ Jóòbù ti wá sí òpin.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé