Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jóòbù 30:1-31

30  “Nísinsìnyí, wọ́n ń fi mí rẹ́rìn-ín,+ Àwọn tí kò tó mi ní ọjọ́ orí,+ Àwọn tí ó jẹ́ pé èmi ì bá kọ̀ Láti fi baba wọn pẹ̀lú agbo ajá mi.   Àní agbára ọwọ́ wọn—kí ni ìwúlò rẹ̀ fún mi? Okun inú ti ṣègbé nínú wọn.+   Nítórí àìní àti ebi, wọ́n di aláìlè-méso-jáde, Wọ́n ń ginrin jẹ ní ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi,+ Níbi tí ìjì àti ìsọdahoro wà lánàá.   Wọ́n ń já ewéko iyọ̀ lẹ́bàá àwọn igi kékeré, Gbòǹgbò igi wíwẹ́ sì ni oúnjẹ wọn.   A óò lé wọn kúrò ní àdúgbò;+ Àwọn ènìyàn yóò kígbe mọ́ wọn bí ẹní kígbe mọ́ olè.   Wọn yóò máa gbé ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, Nínú àwọn ihò inú ilẹ̀ àti nínú àpáta.   Àárín àwọn igi kékeré ni wọn yóò ti ké jáde; Abẹ́ èsìsì ni wọn yóò kó ara wọn jọpọ̀ sí.   Àwọn ọmọ òpònú+ àti àwọn ọmọ ẹni tí kò lórúkọ pẹ̀lú, A ti nà wọ́n lọ́rẹ́ kúrò ní ilẹ̀ náà.   Nísinsìnyí, mo ti di ẹṣin ọ̀rọ̀ orin wọn,+ Ẹni tí a fi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ+ sì ni mo jẹ́ fún wọn. 10  Wọ́n ṣe họ́ọ̀ sí mi, wọ́n jìnnà réré sí mi;+ Wọn kò sì ṣíwọ́ láti máa tutọ́ sí mi lójú.+ 11  Nítorí ó tú okùn ọrun mi, ó sì tẹ̀ síwájú láti rẹ̀ mí sílẹ̀, Wọ́n sì tú ìjánu sílẹ̀ ní tìtorí mi. 12  Wọ́n dìde ní ọwọ́ ọ̀tún mi bí ọ̀wọ́ àwọn ọmọkọ́mọ; Wọ́n jẹ́ kí ẹsẹ̀ mi lọ, Ṣùgbọ́n wọ́n tẹ̀ síwájú láti mọ àwọn ohun ìdínà wọn tí ń mú àjálù wá sókè lòdì sí mi.+ 13  Wọ́n ti ya àwọn òpópónà mi lulẹ̀; Wọ́n ṣàǹfààní fún mi, kìkì sí àgbákò,+ Láìjẹ́ pé wọ́n ní olùrànlọ́wọ́ èyíkéyìí. 14  Wọ́n ń bọ̀ bí ẹní gba inú àlàfo gbígbòòrò wá; Wọ́n ń yí gbirigbiri bọ̀ lábẹ́ ìjì. 15  Ìpayà òjijì ni a ti yí lé mi lórí; Ìdúró mi gẹ́gẹ́ bí ọmọlúwàbí ni a lé bí ẹ̀fúùfù, Ìgbàlà mi sì kọjá lọ bí àwọsánmà. 16  Nísinsìnyí, a ti tú ọkàn mi jáde kúrò nínú mi;+ Àwọn ọjọ́ ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́+ gbá mi mú. 17  Ní òru, àní egungun mi+ ni a dá lu, ó sì já bọ́ kúrò lára mi, Ìrora tí ń já mi jẹ kò sì dúró rárá.+ 18  Nípa ọ̀pọ̀ yanturu agbára, ẹ̀wù mi yí padà; Ó yí mi ká bí ọrùn ẹ̀wù mi gígùn. 19  Ó rẹ̀ mí sílẹ̀ sínú amọ̀, Tí mo fi fi ara mi hàn bí ekuru àti eérú. 20  Mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn;+ Mo dúró, kí o bàa lè fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí mi. 21  Ìwọ yí ara rẹ padà láti ṣe mí níkà;+ Ìwọ fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá ọwọ́ rẹ ṣe kèéta sí mi. 22  O gbé mi sókè sí ẹ̀fúùfù, o mú kí n gùn ún; Lẹ́yìn náà, o fi ìfọ́yángá tú mi ká. 23  Nítorí mo mọ̀ dáadáa pé ìwọ yóò mú kí n padà lọ sínú ikú,+ Àti sí ilé ìpàdé fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè. 24  Kìkì pé kò sí ẹni tí ń na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí òkìtì àwókù lásán-làsàn,+ Bẹ́ẹ̀ ni kò sí igbe fún ìrànlọ́wọ́ nípa nǹkan wọnnì nígbà tí ènìyàn bá ń jẹrà. 25  Dájúdájú, mo ti sunkún fún ẹni tí ọjọ́ nira fún;+ Ọkàn mi ti kẹ́dùn fún òtòṣì.+ 26  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo dúró de ohun rere, síbẹ̀ ohun búburú ni ó dé;+ Mo sì ń dúró dé ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ìṣúdùdù ni ó dé. 27  A ti mú kí ìfun mi hó, kò sì dákẹ́ jẹ́ẹ́; Àwọn ọjọ́ ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́ kò mí lójú. 28  Mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́+ nígbà tí kò sí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; Mo dìde nínú ìjọ, mo ń kígbe ṣáá fún ìrànlọ́wọ́. 29  Mo di arákùnrin àwọn akátá, Àti alábàákẹ́gbẹ́ àwọn abo ọmọ ògòǹgò.+ 30  Àní awọ ara mi di dúdú,+ ó sì ṣí kúrò lára mi, Àní egungun mi sì gbóná nítorí pé ó gbẹ. 31  Háàpù mi sì wá jẹ́ fún ọ̀fọ̀ lásán-làsàn, Àti fèrè ape mi fún ohùn àwọn tí ń sunkún.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé